YouVersion Logo
Search Icon

A. Oni 4

4
Debora ati Baraki
1AWỌN ọmọ Israeli si tun ṣe eyiti o buru li oju OLUWA, nigbati Ehudu kú tán.
2OLUWA si tà wọn si ọwọ́ Jabini ọba Kenaani, ẹniti o jọba ni Hasori; olori ogun ẹniti iṣe Sisera, ẹniti ngbé Haroṣeti ti awọn orilẹ-ède.
3Awọn ọmọ Israeli si kigbepè OLUWA: nitoriti o ní ẹdẹgbẹrun kẹkẹ́ irin; ogun ọdún li o si fi pọ́n awọn ọmọ Israeli loju gidigidi.
4Ati Debora, wolĩ-obinrin, aya Lappidotu, o ṣe idajọ Israeli li akokò na.
5On si ngbé abẹ igi-ọpẹ Debora li agbedemeji Rama ati Beti-eli ni ilẹ òke Efraimu: awọn ọmọ Israeli a si ma wá sọdọ rẹ̀ fun idajọ.
6On si ranṣẹ pè Baraki ọmọ Abinoamu lati Kedeṣi-naftali jade wá, o si wi fun u pe, OLUWA, Ọlọrun Israeli kò ha ti paṣẹ pe, Lọ sunmọ òke Tabori, ki o si mú ẹgba marun ọkunrin ninu awọn ọmọ Naftali, ati ninu awọn ọmọ Sebuluni pẹlu rẹ.
7Emi o si fà Sisera, olori ogun Jabini, pẹlu kẹkẹ́ rẹ̀ ati ogun rẹ̀, sọdọ rẹ si odò Kiṣoni; emi o si fi i lé ọ lọwọ.
8Baraki si wi fun u pe, Bi iwọ o ba bá mi lọ, njẹ emi o lọ: ṣugbọn bi iwọ ki yio ba bá mi lọ, emi ki yio lọ.
9On si wipe, Ni lilọ emi o bá ọ lọ: ṣugbọn ọlá ọ̀na ti iwọ nlọ nì ki yio jẹ́ tirẹ; nitoriti OLUWA yio tà Sisera si ọwọ́ obinrin. Debora si dide, o si bá Baraki lọ si Kedeṣi.
10Baraki si pè Sebuluni ati Naftali si Kedeṣi; on si lọ pẹlu ẹgba marun ọkunrin lẹhin rẹ̀: Debora si gòke lọ pẹlu rẹ̀.
11Njẹ Heberi ọmọ Keni, ti yà ara rẹ̀ kuro lọdọ awọn ọmọ Keni, ani awọn ọmọ Hobabu, ana Mose, o si pa agọ́ rẹ̀ titi dé igi-oaku Saanannimu, ti o wà li àgbegbe Kedeṣi.
12Nwọn si sọ fun Sisera pe, Baraki ọmọ Abinoamu ti lọ si òke Tabori.
13Sisera si kó gbogbo kẹkẹ́ rẹ̀ jọ, ẹdẹgbẹrun kẹkẹ́ irin, ati gbogbo awọn enia ti o wà pẹlu rẹ̀, lati Haroṣeti awọn orilẹ-ède wá si odò Kiṣoni.
14Debora si wi fun Baraki pe, Dide; nitoripe oni li ọjọ́ ti OLUWA fi Sisera lé ọ lọwọ: OLUWA kò ha ti ṣaju rẹ lọ bi? Bẹ̃ni Baraki sọkalẹ lati òke Tabori lọ, ẹgba marun ọkunrin si tẹle e lẹhin.
15OLUWA si fi oju idà ṣẹgun Sisera, ati gbogbo kẹkẹ́ rẹ̀, ati gbogbo ogun rẹ̀, niwaju Baraki; Sisera si sọkalẹ kuro li ori kẹkẹ́ rẹ̀, o si fi ẹsẹ̀ rẹ̀ sálọ.
16Ṣugbọn Baraki lepa awọn kẹkẹ́, ati ogun na, titi dé Haroṣeti awọn orilẹ-ède: gbogbo ogun Sisera si ti oju idà ṣubu; ọkunrin kanṣoṣo kò si kù.
17Ṣugbọn Sisera ti fi ẹsẹ̀ rẹ̀ sálọ si agọ́ Jaeli aya Heberi ọmọ Keni: nitoriti alafia wà lãrin Jabini ọba Hasori ati ile Heberi ọmọ Keni.
18Jaeli si jade lọ ipade Sisera, o si wi fun u pe, Yà wá, oluwa mi, yà sọdọ mi; má bẹ̀ru. On si yà sọdọ rẹ̀ sinu agọ́, o si fi kubusu bò o.
19On si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, fun mi li omi diẹ mu; nitoriti ongbẹ ngbẹ mi. O si ṣí igo warà kan, o si fi fun u mu, o si bò o lara.
20On si wi fun u pe, Duro li ẹnu-ọ̀na agọ́, yio si ṣe, bi ẹnikan ba wá, ti o si bi ọ lère pe, ọkunrin kan wà nihin bi? ki iwọ wipe, Kò sí.
21Nigbana ni Jaeli aya Heberi mú iṣo-agọ́ kan, o si mú õlù li ọwọ́ rẹ̀, o si yọ́ tọ̀ ọ, o si kàn iṣo na mọ́ ẹbati rẹ̀, o si wọ̀ ilẹ ṣinṣin; nitoriti o sùn fọnfọn; bẹ̃ni o daku, o si kú.
22Si kiyesi i, bi Baraki ti nlepa Sisera, Jaeli wá pade, rẹ̀, o si wi fun u pe, Wá, emi o si fi ọkunrin ti iwọ nwá hàn ọ. O si wá sọdọ rẹ̀; si kiyesi i, Sisera dubulẹ li okú, iṣo-agọ́ na si wà li ẹbati rẹ̀.
23Bẹ̃li Ọlọrun si tẹ̀ ori Jabini ọba Kenaani ba li ọjọ́ na niwaju awọn ọmọ Israeli.
24Ọwọ́ awọn ọmọ Israeli si le siwaju ati siwaju si Jabini ọba Kenaani, titi nwọn fi run Jabini ọba Kenaani.

Currently Selected:

A. Oni 4: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in