YouVersion Logo
Search Icon

A. Oni 5

5
Orin Debora ati Baraki
1NIGBANA ni Debora on Baraki ọmọ Abinoamu kọrin li ọjọ́ na, wipe,
2Nitori bi awọn olori ti ṣaju ni Israeli, nitori bi awọn enia ti fi tinutinu wá, ẹ fi ibukún fun OLUWA.
3Ẹ gbọ́, ẹnyin ọba; ẹ feti nyin silẹ, ẹnyin ọmọ alade; emi, ani emi, o kọrin si OLUWA; emi o kọrin iyìn si OLUWA, Ọlọrun Israeli.
4OLUWA, nigbati iwọ jade kuro ni Seiri, nigbati iwọ nyan jade lati pápa Edomu wá, ilẹ mìtiti, awọn ọrun si kánsilẹ, ani awọsanma pẹlu kán omi silẹ.
5Awọn òke nla yọ́ niwaju OLUWA, ani Sinai yọ́ niwaju OLUWA; Ọlọrun Israeli.
6Li ọjọ́ Ṣamgari ọmọ Anati, li ọjọ́ Jaeli, awọn ọ̀na opópo da, awọn èro si nrìn li ọ̀na ìkọ̀kọ̀.
7Awọn olori tán ni Israeli, nwọn tán, titi emi Debora fi dide, ti emi dide bi iya ni Israeli.
8Nwọn ti yàn ọlọrun titun; nigbana li ogun wà ni ibode: a ha ri asà tabi ọ̀kọ kan lãrin ẹgba ogún ni Israeli bi?
9Àiya mi fà si awọn alaṣẹ Israeli, awọn ti nwọn fi tinutinu wá ninu awọn enia: ẹ fi ibukún fun OLUWA.
10Ẹ sọ ọ, ẹnyin ti ngùn kẹtẹkẹtẹ funfun, ẹnyin ti njoko lori ẹni daradara, ati ẹnyin ti nrìn li ọ̀na.
11Li ọ̀na jijìn si ariwo awọn tafàtafa nibiti a gbé nfà omi, nibẹ̀ ni nwọn o gbé sọ iṣẹ ododo OLUWA, ani iṣẹ ododo ijọba rẹ̀ ni Israeli. Nigbana ni awọn enia OLUWA sọkalẹ lọ si ibode.
12Jí, jí, Debora; Jí, jí, kọ orin: dide, Baraki, ki o si ma kó awọn igbekun rẹ ni igbekun, iwọ ọmọ Abinoamu.
13Nigbana ni iyokù ninu awọn ọlọ̀tọ ati awọn enia sọkalẹ; OLUWA sọkalẹ sori awọn alagbara fun mi.
14Lati Efraimu ni nwọn ti wá awọn ti gbongbo wọn wà ni Amaleki; lẹhin rẹ, Benjamini, lãrin awọn enia rẹ; lati Makiri ni awọn alaṣẹ ti sọkalẹ wá, ati lati Sebuluni li awọn ẹniti nmú ọ̀pá-oyè lọwọ.
15Awọn ọmọ-alade Issakari wà pẹlu Debora; bi Issakari ti ri, bẹ̃ni Baraki; nwọn sure li ẹsẹ̀ lọ si afonifoji na. Ni ipadò Reubeni ni ìgbero pupọ̀ wà.
16Ẽṣe ti iwọ fi joko lãrin agbo-agutan lati ma gbọ́ fere oluṣọ-agutan? Ni ipadò Reubeni ni ìgbero pupọ̀ wà.
17Gileadi joko loke odò Jordani: ẽṣe ti Dani fi joko ninu ọkọ̀? Aṣeri joko leti okun, o si ngbé ebute rẹ̀.
18Sebuluni li awọn enia, ti o fi ẹmi wọn wewu ikú, ati Naftali, ni ibi giga pápa.
19Awọn ọba wá nwọn jà; nigbana li awọn ọba Kenaani jà ni Taanaki leti odò Megiddo: nwọn kò si gbà ère owo.
20Nwọn jà lati ọrun wá, awọn irawọ ni ipa wọn bá Sisera jà.
21Odò Kiṣoni gbá wọn lọ, odò igbani, odò Kiṣoni. Hã ọkàn mi, ma yan lọ ninu agbara.
22Nigbana ni patako ẹsẹ̀ ẹṣin kì ilẹ, nitori ire-sisá, iré-sisá awọn alagbara wọn.
23Ẹ fi Merosi bú, bẹ̃li angeli OLUWA wi, ẹ fi awọn ara inu rẹ̀ bú ibú kikorò; nitoriti nwọn kò wá si iranlọwọ OLUWA, si iranlọwọ OLUWA si awọn alagbara.
24Ibukún ni fun Jaeli aya Heberi ọmọ Keni jù awọn obinrin lọ, ibukún ni fun u jù awọn obinrin lọ ninu agọ́.
25O bère omi, o fun u ni warà; o mu ori-amọ tọ̀ ọ wá ninu awo iyebiye.
26O nà ọwọ́ rẹ̀ mú iṣo, ati ọwọ́ ọtún rẹ̀ mú òlu awọn ọlọnà; òlu na li o si fi lù Sisera, o gba mọ́ ọ li ori, o si gún o si kàn ẹbati rẹ̀ mọlẹ ṣinṣin.
27Li ẹsẹ̀ rẹ̀ o wolẹ, o ṣubu, o dubulẹ: li ẹsẹ̀ rẹ̀ o wolẹ, o ṣubu: ni ibi ti o gbè wolẹ, nibẹ̀ na li o ṣubu kú.
28Iya Sisera nwò oju-ferese, o si kigbe, o kigbe li oju-ferese ọlọnà pe; Ẽṣe ti kẹkẹ́ rẹ̀ fi pẹ bẹ̃ lati dé? Ẽṣe ti ẹsẹ̀ kẹkẹ̀ rẹ̀ fi duro lẹhin?
29Awọn obinrin rẹ̀ amoye da a lohùn, ani, on si ti da ara rẹ̀ lohùn pe,
30Nwọn kò ha ti ri, nwọn kò ha ti pín ikogun bi? fun olukuluku ọkunrin wundia kan tabi meji; fun Sisera ikogun-aṣọ alarabara, ikógun-aṣọ alarabara oniṣẹ-abẹ́rẹ, aṣọ alarabara oniṣẹ-abẹ́rẹ ni ìha mejeji, li ọrùn awọn ti a kó li ogun.
31Bẹ̃ni ki o jẹ ki gbogbo awọn ọtá rẹ ki o ṣegbé OLUWA: ṣugbọn jẹ ki awọn ẹniti o fẹ́ ẹ ki o dabi õrùn nigbati o ba yọ ninu agbara rẹ̀. Ilẹ na si simi li ogoji ọdún.

Currently Selected:

A. Oni 5: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in