A. Oni 6
6
Gideoni
1AWỌN ọmọ Israeli si ṣe buburu loju OLUWA: OLUWA si fi wọn lé Midiani lọwọ li ọdún meje.
2Ọwọ́ Midiani si le si Israeli: ati nitori Midiani awọn ọmọ Israeli wà ihò wọnni fun ara wọn, ti o wà ninu òke, ati ninu ọgbun, ati ni ibi-agbara wọnni.
3O si ṣe, bi Israeli ba gbìn irugbìn, awọn Midiani a si gòke wá, ati awọn Amaleki, ati awọn ọmọ ìha ìla-õrùn; nwọn a si gòke tọ̀ wọn wá;
4Nwọn a si dótì wọn, nwọn a si run eso ilẹ na, titi iwọ o fi dé Gasa, nwọn ki isi fi onjẹ silẹ ni Israeli, tabi agutan, tabi akọ-malu, tabi kẹtẹkẹtẹ.
5Nitoriti nwọn gòke wá ti awọn ti ohunọ̀sin wọn ati agọ́ wọn, nwọn si wá bi eṣú li ọ̀pọlọpọ; awọn ati awọn ibakasiẹ wọn jẹ́ ainiye: nwọn si wọ̀ inu ilẹ na lati jẹ ẹ run.
6Oju si pọ́n Israeli gidigidi nitori awọn Midiani; awọn ọmọ Israeli si kigbepè OLUWA.
7O si ṣe, nigbati awọn ọmọ Israeli kigbepè OLUWA nitori awọn Midiani,
8OLUWA si rán wolĩ kan si awọn ọmọ Israeli: ẹniti o wi fun wọn pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun Israeli wi, Emi mú nyin gòke ti Egipti wá, mo si mú nyin jade kuro li oko-ẹrú;
9Emi si gbà nyin li ọwọ́ awọn ara Egipti, ati li ọwọ́ gbogbo awọn ti npọ́n nyin loju, mo si lé wọn kuro niwaju nyin, mo si fi ilẹ wọn fun nyin;
10Mo si wi fun nyin pe, Emi li OLUWA Ọlọrun nyin; ẹ máṣe bẹ̀ru oriṣa awọn Amori, ilẹ ẹniti ẹnyin ngbé: ṣugbọn ẹnyin kò gbà ohùn mi gbọ́.
11Angeli OLUWA kan si wá, o si joko labẹ igi-oaku kan ti o wà ni Ofra, ti iṣe ti Joaṣi ọmọ Abieseri: Gideoni ọmọ rẹ̀ si npakà nibi ifọnti, lati fi i pamọ́ kuro loju awọn Midiani.
12Angeli OLUWA na si farahàn a, o si wi fun u pe, OLUWA wà pẹlu rẹ, iwọ ọkunrin alagbara.
13Gideoni si wi fun u pe, Yẽ oluwa mi, ibaṣepe OLUWA wà pẹlu wa, njẹ ẽṣe ti gbogbo eyi fi bá wa? nibo ni gbogbo iṣẹ-iyanu rẹ̀ ti awọn baba wa ti sọ fun wa gbé wà, wipe, OLUWA kò ha mú wa gòke lati Egipti wá? ṣugbọn nisisiyi OLUWA ti kọ̀ wa silẹ, o si ti fi wa lé Midiani lọwọ.
14OLUWA si wò o, o si wipe, Lọ ninu agbara rẹ yi, ki iwọ ki ó si gbà Israeli là kuro lọwọ Midiani: Emi kọ ha rán ọ bi?
15O si wi fun u pe, Yẽ oluwa mi, ọ̀na wo li emi o fi gbà Israeli là? kiyesi i, talakà ni idile mi ni Manasse, emi li o si jẹ́ ẹni ikẹhin ni ile baba mi.
16OLUWA si wi fun u pe, Nitõtọ emi o wà pẹlu rẹ, iwọ o si kọlù awọn Midiani bi ọkunrin kan.
17On si wi fun u pe, Bi o ba ṣepe mo ri ore-ọfẹ gbà li oju rẹ, njẹ fi àmi kan hàn mi pe iwọ bá mi sọ̀rọ.
18Máṣe lọ kuro nihin, emi bẹ̀ ọ, titi emi o fi tọ̀ ọ wá, ti emi o si fi mú ọrẹ mi fun ọ wá, ati ti emi o si fi gbé e kalẹ niwaju rẹ. On si wipe, Emi o duro titi iwọ o si fi pada wá.
19Gideoni si wọ̀ inu ilé lọ, o si pèse ọmọ ewurẹ kan, ati àkara alaiwu ti iyẹfun òṣuwọn efa kan: ẹran na li o fi sinu agbọ̀n, omi rẹ̀ li o si fi sinu ìkoko, o si gbé e jade tọ̀ ọ wá labẹ igi-oaku na, o si gbé e siwaju rẹ̀.
20Angeli Ọlọrun na si wi fun u pe, Mú ẹran na, ati àkara alaiwu na, ki o si fi wọn lé ori okuta yi, ki o si dà omi ẹran na silẹ. On si ṣe bẹ̃.
21Nigbana ni angeli OLUWA nà ọpá ti o wà li ọwọ rẹ̀, o si fi ori rẹ̀ kàn ẹran na ati àkara alaiwu na; iná si là lati inu okuta na jade, o si jó ẹran na, ati àkara alaiwu; angeli OLUWA na si lọ kuro niwaju rẹ̀.
22Gideoni si ri pe angeli OLUWA ni; Gideoni si wipe, Mo gbé, OLUWA Ọlọrun! nitoriti emi ri angeli OLUWA li ojukoju.
23OLUWA si wi fun u pe, Alafia fun ọ; má ṣe bẹ̀ru: iwọ́ ki yio kú.
24Nigbana ni Gideoni mọ pẹpẹ kan nibẹ̀ fun OLUWA, o si pè orukọ rẹ̀ ni Jehofa-ṣalomu: o wà ni Ofra ti awọn Abiesri sibẹ̀ titi di oni.
25O si ṣe li oru ọjọ́ kanna, li OLUWA wi fun u pe, Mú akọ-malu baba rẹ, ani akọ-malu keji ọlọdún meje, ki o si wó pẹpẹ Baali ti baba rẹ ní lulẹ ki o si bẹ́ igi-oriṣa ti o wà lẹba rẹ̀ lulẹ:
26Ki o si mọ pẹpẹ kan fun OLUWA Ọlọrun rẹ lori ibi agbara yi, bi o ti yẹ, ki o si mú akọ-malu keji, ki o si fi igi-oriṣa ti iwọ bẹ́ lulẹ ru ẹbọ sisun.
27Nigbana ni Gideoni mú ọkunrin mẹwa ninu awọn iranṣẹ rẹ̀, o si ṣe bi OLUWA ti sọ fun u: o si ṣe, nitoripe o bẹ̀ru ile baba rẹ̀ ati awọn ọkunrin ilu na, tobẹ̃ ti kò fi le ṣe e li ọsán, ti o si fi ṣe e li oru.
28Nigbati awọn ọkunrin ilu na si dide ni kùtukutu, si wò o, a ti wó pẹpẹ Baali lulẹ, a si bẹ́ igi-oriṣa lulẹ ti o wà lẹba rẹ̀, a si ti pa akọ-malu keji rubọ lori pẹpẹ ti a mọ.
29Nwọn si sọ fun ara wọn pe, Tali o ṣe nkan yi? Nigbati nwọn tọ̀sẹ̀, ti nwọn si bère, nwọn si wipe, Gideoni ọmọ Joaṣi li o ṣe nkan yi.
30Nigbana li awọn ọkunrin ilu na wi fun Joaṣi pe, Mú ọmọ rẹ jade wá ki o le kú: nitoripe o wó pẹpẹ Baali lulẹ, ati nitoriti o bẹ́ igi-oriṣa ti o wà lẹba rẹ̀ lulẹ.
31Joaṣi si wi fun gbogbo awọn ti o duro tì i pe, Ẹnyin o gbèja Baali bi? tabi ẹnyin o gbà a là bi? ẹniti o ba ngbèja rẹ̀, ẹ jẹ ki a lù oluwarẹ̀ pa ni kùtukutu owurọ yi: bi on ba ṣe ọlọrun, ẹ jẹ ki o gbèja ara rẹ̀, nitoriti ẹnikan wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ.
32Nitorina li ọjọ́ na, o pè orukọ rẹ̀ ni Jerubbaali, wipe, Jẹ ki Baali ki o bá a jà, nitoriti o wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ.
33Nigbana ni gbogbo awọn Midiani ati awọn Amaleki, ati awọn ọmọ ìha ìla-õrùn kó ara wọn jọ pọ̀; nwọn rekọja, nwọn si dó li afonifoji Jesreeli.
34Ṣugbọn ẹmi OLUWA bà lé Gideoni, on si fun ipè; Abieseri si kójọ sẹhin rẹ̀.
35On si rán onṣẹ si gbogbo Manasse; awọn si kójọ sẹhin rẹ̀ pẹlu: o si rán onṣẹ si Aṣeri, ati si Sebuluni, ati si Naftali; nwọn si gòke wá lati pade wọn.
36Gideoni si wi fun Ọlọrun pe, Bi iwọ o ba ti ọwọ́ mi gbà Israeli là, bi iwọ ti wi,
37Kiyesi i, emi o fi irun agutan le ilẹ-pakà; bi o ba ṣepe ìri sẹ̀ sara kìki irun nikan, ti gbogbo ilẹ si gbẹ, nigbana li emi o mọ̀ pe iwọ o ti ọwọ́ mi gbà Israeli là, gẹgẹ bi iwọ ti wi.
38Bẹ̃li o si ri: nitoriti on dide ni kùtukutu ijọ́ keji, o si fọ́n irun agutan na, o si fọ́n ìri na kuro lara rẹ̀, ọpọ́n kan si kún fun omi.
39Gideoni si wi fun Ọlọrun pe, Má ṣe jẹ ki ibinu rẹ ki o rú si mi, emi o sọ̀rọ lẹ̃kanṣoṣo yi: emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ki o fi irun na ṣe idanwò lẹ̃kan yi; jẹ ki irun agutan nikan ki o gbẹ, ṣugbọn ki ìri ki o wà lori gbogbo ilẹ.
40Ọlọrun si ṣe bẹ̃ li oru na: nitoriti irun agutan na gbẹ, ìri si wà lori gbogbo ilẹ na.
Currently Selected:
A. Oni 6: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: