YouVersion Logo
Search Icon

Job 25

25
1NIGBANA ni Bildadi, ara Ṣua, dahùn wipe,
2Ijọba ati ẹ̀ru mbẹ lọdọ rẹ̀, on ni iṣe ilaja ni ibi gigagiga rẹ̀.
3Awọn ọmọ-ogun rẹ̀ ha ni iye bi, tabi ara tani imọlẹ rẹ̀ kò mọ́ si?
4Eha ti ṣe ti a o fi da enia lare lọdọ Ọlọrun, tabi ẹniti a bi lati inu obinrin wá yio ha ṣe mọ́?
5Kiyesi i, òṣupa kò si le itan imọlẹ, ani awọn ìrawọ kò mọlẹ li oju rẹ̀.
6Ambọtori enia ti iṣe idin, ati ọmọ enia, ti iṣe kòkoro!

Currently Selected:

Job 25: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in