Job 38
38
OLUWA dá Jobu Lóhùn
1NIGBANA ni OLUWA da Jobu lohùn lati inu ìji ajayika wá o si wipe,
2Tani eyi ti nfi ọ̀rọ aini igbiro ṣú ìmọ li òkunkun.
3Di ẹgbẹ ara rẹ li amure bi ọkunrin nisisiyi, nitoripe emi o bère lọwọ rẹ ki o si da mi lohùn.
4Nibo ni iwọ wà nigbati mo fi ipilẹ aiye sọlẹ? wi bi iwọ ba moye!
5Tali o fi ìwọn rẹ̀ lelẹ, bi iwọ ba mọ̀, tabi tani o ta okun wiwọn sori rẹ̀.
6Lori ibo ni a gbe kan ipilẹ rẹ̀ mọ́, tabi tali o fi okuta igun rẹ̀ le ilẹ?
7Nigbati awọn irawọ owurọ jumọ kọrin pọ̀, ti gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun nhó iho ayọ̀?
8Tabi tali o fi ilẹkun sé omi okun mọ́, nigbati o ya jade bi ẹnipe o ti inu tu jade wá?
9Nigbati mo fi awọsanma ṣe aṣọ rẹ̀, ati òkunkun ṣiṣu ṣe ọ̀ja igbanu rẹ̀?
10Ti mo ti paṣẹ ipinnu mi fun u, ti mo si ṣe bèbe ati ilẹkun.
11Ti mo si wipe, Nihinyi ni iwọ o dé, ki o má si rekọja, nihinyi si ni igberaga riru omi rẹ yio gbe duro mọ.
12Iwọ paṣẹ fun owurọ lati igba ọjọ rẹ̀ wá, iwọ si mu ila-õrun mọ̀ ipo rẹ̀?
13Ki o le idi opin ilẹ aiye mu, ki a le gbọ̀n awọn enia buburu kuro ninu rẹ̀.
14Ki o yipada bi amọ fun edidi amọ, ki gbogbo rẹ̀ ki o si fi ara rẹ̀ hàn bi ẹnipe ninu aṣọ igunwa.
15A si fa imọlẹ wọn sẹhin kuro lọdọ enia buburu, apa giga li o si ṣẹ́.
16Iwọ ha wọ inu isun okun lọ ri bi? iwọ si rin lori isalẹ ibú nla?
17A ha ṣilẹkun ikú silẹ fun ọ ri bi, iwọ si ri ilẹkun ojiji ikú?
18Iwọ̀ moye ibú aiye bi? sọ bi iwọ ba mọ̀ gbogbo rẹ̀?
19Ọ̀na wo ni imọlẹ igbé, bi o ṣe ti òkunkun, nibo ni ipò rẹ̀?
20Ti iwọ o fi mu u lọ si ibi àla rẹ̀, ti iwọ o si le imọ̀ ipa-ọ̀na lọ sinu ile rẹ̀?
21Iwọ mọ̀ eyi, nitoriti ni igbana ni a bi ọ? ati iye ọjọ rẹ si pọ!
22Iwọ ha wọ inu iṣura ojò-dídì lọ ri bí, iwọ si ri ile iṣura yinyin ri?
23Ti mo ti fi pamọ de igba iyọnu, de ọjọ ogun ati ijà.
24Ọ̀na wo ni imọlẹ fi nyà, ti afẹfẹ ila-orun tàn kakiri lori ilẹ aiye?
25Tali o la ipado fun ẹkún iṣan omi, ati ọ̀na fun manamana ãrá?
26Lati mu u rọ̀jo sori aiye, nibiti enia kò si, ni aginju nibiti enia kò si.
27Lati mu ilẹ tutù, ijù ati alairo, ati lati mu irudi ọmudún eweko ru jade?
28Ojo ha ni baba bi, tabi tali o bi ikán ìsẹ-iri?
29Lati inu tani ìdi omi ti jade wá, ati ìri didi ọrun tali o bi i?
30Omi bò o mọlẹ bi ẹnipe labẹ okuta, oju ibú nla si dìlupọ̀.
31Iwọ le ifi ọja de awọn irawọ meje [Pleyade] tabi iwọ le itudi irawọ Orionu?
32Iwọ le imu awọn ami mejejila irawọ [Masaroti] jade wá ni igba akoko wọn? tabi iwọ le iṣe àmọna Arketuru pẹlu awọn ọmọ rẹ̀?
33Iwọ mọ̀ ilana-ilana ọrun, iwọ le ifi ijọba rẹ̀ lelẹ li aiye?
34Iwọ le igbé ohùn rẹ soke de awọsanma, ki ọ̀pọlọpọ omi ki o le bò ọ?
35Iwọ le iran mànamána ki nwọn ki o le ilọ, ki nwọn ki o si wi fun ọ pe, Awa nĩ!
36Tali o fi ọgbọ́n si odo-inu, tabi tali o fi oye sinu aiya?
37Tali o fi ọgbọ́n ka iye awọsanma, tali o si mu igo ọrun dàjade.
38Nigbati erupẹ di lile, ati ogulutu dipọ̀?
39Iwọ o ha dẹ ọdẹ fun abo kiniun bi, iwọ o si tẹ́ ebi ẹgbọrọ kiniun lọrun?
40Nigbati nwọn ba mọlẹ ninu iho wọn, ti nwọn si ba ni ibuba de ohun ọdẹ.
41Tani npese ohun jijẹ fun ìwo? nigbati awọn ọmọ rẹ̀ nkepe Ọlọrun, nwọn a ma fò kiri nitori aili ohun jijẹ.
Currently Selected:
Job 38: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.