YouVersion Logo
Search Icon

Job 8

8
1NIGBANA ni Bildadi, ara Ṣua, dahùn wipe,
2Iwọ o ti ma sọ nkan wọnyi pẹ to? ti ọ̀rọ ẹnu rẹ yio si ma dabi ẹfufu nla?
3Ọlọrun a ha ma yi idajọ po bi, tabi Olodumare a ma fi otitọ ṣẹ̀ bi?
4Nigbati awọn ọmọ rẹ ṣẹ̀ si i, o si gbá wọn kuro nitori irekọja wọn.
5Bi iwọ ba si kepe Ọlọrun ni igba akokò, ti iwọ bá si gbadura ẹ̀bẹ si Olodumare.
6Iwọ iba mọ́, ki o si duro ṣinṣin: njẹ nitõtọ nisisiyi on o tají fun ọ, on a si sọ ibujoko ododo rẹ di pipọ.
7Ipilẹṣẹ rẹ iba tilẹ kere ri, bẹ̃ni igbẹhin rẹ iba pọ̀ si i gidigidi.
8Emi bẹ̀ ọ njẹ, bere lọwọ awọn ara igbãni, ki o si kiyesi iwádi awọn baba wọn.
9Nitoripe ọmọ-àná li awa, a kò si mọ̀ nkan, nitoripe òjiji li ọjọ wa li aiye.
10Awọn kì yio ha kọ́ ọ, nwọn kì yio si sọ fun ọ, nwọn kì yio si sọ̀rọ lati inu ọkàn wọn jade wá?
11Koriko odò ha le dàgba laini ẹrẹ̀, tabi ẽsú ha le dàgba lailomi?
12Nigbati o wà ni tutù, ti a kò ke e lulẹ̀, o rọ danu sin eweko miran gbogbo.
13Bẹ̃ni ipa ọ̀na gbogbo awọn ti o gbagbe Ọlọrun, abá awọn àgabàgebe yio di ofo.
14Abá ẹniti a o ke kuro, ati igbẹkẹle ẹniti o dàbi ile alantakùn.
15Yio fi ara tì ile rẹ̀, ṣugbọn kì yio le iduro, yio fi di ara rẹ̀ mu ṣinṣin ṣugbọn kì yio le iduro pẹ.
16O tutù niwaju õrùn, ẹka rẹ̀ si yọ jade ninu ọgbà rẹ̀.
17Gbòngbo rẹ̀ ta yi ebè ka, o si wò ibi okuta wọnni.
18Bi o ba si pa a run kuro ni ipò rẹ̀, nigbana ni ipò na yio sẹ ẹ pe: emi kò ri ọ ri!
19Kiyesi eyi ni ayọ̀ ọ̀na rẹ̀ ati lati inu ilẹ li omiran yio ti hù jade wá.
20Kiyesi i, Ọlọrun kì yio ta ẹni-otitọ nù, bẹ̃ni kì yio ràn oniwa-buburu lọwọ.
21Titi yio fi fi ẹ̀rin kún ọ li ẹnu, ati ète rẹ pẹlu iho ayọ̀.
22Itiju li a o fi bò awọn ti o korira rẹ, ati ibujoko enia buburu kì yio si mọ.

Currently Selected:

Job 8: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in