Luk 22
22
Àwọn Juu Dìtẹ̀ láti Pa Jesu
(Mat 26:1-5,14-16; Mak 14:1-2,10-11; Joh 11:45-53)
1AJỌ ọdun aiwukara ti a npè ni Irekọja si kù fẹfẹ.
2Ati awọn olori alufa, ati awọn akọwe nwá ọ̀na bi nwọn iba ti ṣe pa a; nitoriti nwọn mbẹ̀ru awọn enia.
3Satani si wọ̀ inu Judasi, ti a npè ni Iskariotu, ọkan ninu awọn mejila.
4O si mu ọ̀na rẹ̀ pọ̀n, o lọ lati ba awọn olori alufa ati awọn olori ẹṣọ́ mọ̀ ọ pọ̀, bi on iba ti fi i le wọn lọwọ.
5Nwọn si yọ̀, nwọn si ba a da majẹmu ati fun u li owo.
6O si gbà: o si nwá akoko ti o wọ̀, lati fi i le wọn lọwọ laìsi ariwo.
Ìpalẹ̀mọ́ fún Àsè Ìrékọjá
(Mat 26:17-25; Mak 14:12-21; Joh 13:21-30)
7Ọjọ aiwukara pé, nigbati nwọn kò le ṣe aiṣẹbọ irekọja.
8O si rán Peteru on Johanu, wipe, Ẹ lọ ipèse irekọja fun wa, ki awa ki o jẹ.
9Nwọn si wi fun u pe, Nibo ni iwọ nfẹ ki a pèse sile?
10O si wi fun wọn pe, Kiyesi i, nigbati ẹnyin ba nwọ̀ ilu lọ, ọkunrin kan ti o rù iṣa omi yio pade nyin; ẹ ba a lọ si ile ti o ba wọ̀.
11 Ki ẹ si wi fun bãle ile na pe, Olukọni wi fun ọ pe, Nibo ni gbọ̀ngan apejẹ na gbé wà, nibiti emi o gbé jẹ irekọja pẹlu awọn ọmọ-ẹhin mi?
12 On o si fi gbọ̀ngan nla kan loke hàn nyin, ti a ṣe lọṣọ: nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o pèse silẹ.
13Nwọn si lọ nwọn si bá a gẹgẹ bi o ti sọ fun wọn: nwọn si pèse irekọja silẹ.
Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa
(Mat 26:26-30; Mak 14:22-26; I. Kor 11:23-25)
14Nigbati akokò si to, o joko ati awọn aposteli pẹlu rẹ̀.
15O si wi fun wọn pe, Tinu-tinu li emi fẹ fi ba nyin jẹ irekọja yi, ki emi ki o to jìya:
16 Nitori mo wi fun nyin, Emi kì yio jẹ ninu rẹ̀ mọ́, titi a o fi mú u ṣẹ ni ijọba Ọlọrun.
17O si gbà ago, nigbati o si ti dupẹ, o wipe, Gbà eyi, ki ẹ si pín i larin ara nyin.
18 Nitori mo wi fun nyin, Emi kì yio mu ninu eso ajara mọ́, titi ijọba Ọlọrun yio fi de.
19O si mú akara, nigbati o si ti dupẹ o bu u, o si fifun wọn, o wipe, Eyi li ara mi ti a fifun nyin: ẹ mã ṣe eyi ni iranti mi.
20Bẹ̃ gẹgẹ lẹhin onjẹ alẹ, o si mu ago, o wipe, Ago yi ni majẹmu titun li ẹ̀jẹ mi, ti a ta silẹ fun nyin.
21 Ṣugbọn ẹ kiyesi i, ọwọ́ ẹniti o fi mi hàn wà pẹlu mi lori tabili.
22 Ọmọ-enia nlọ nitõtọ bi a ti pinnu rẹ̀: ṣugbọn egbé ni fun ọkunrin na nipasẹ ẹniti a gbé ti fi i hàn!
23Nwọn si bẹ̀rẹ si ibère larin ara wọn, tani ninu wọn ti yio ṣe nkan yi.
24Ijà kan si mbẹ larin wọn, niti ẹniti a kà si olori ninu wọn.
25O si wi fun wọn pe, Awọn ọba Keferi a ma fẹla lori wọn: a si ma pè awọn alaṣẹ wọn ni olõre.
26 Ṣugbọn ẹnyin kì yio ri bẹ̃: ṣugbọn ẹniti o ba pọ̀ju ninu nyin ki o jẹ bi aburo; ẹniti o si ṣe olori, bi ẹniti nṣe iranṣẹ.
27 Nitori tali o pọ̀ju, ẹniti o joko tì onjẹ, tabi ẹniti o nṣe iranṣẹ? ẹniti o joko tì onjẹ ha kọ́? ṣugbọn emi mbẹ larin nyin bi ẹniti nṣe iranṣẹ.
28 Ẹnyin li awọn ti o ti duro tì mi ninu idanwo mi.
29 Mo si yàn ijọba fun nyin, gẹgẹ bi Baba mi ti yàn fun mi;
30 Ki ẹnyin ki o le mã jẹ, ki ẹnyin ki o si le mã mu lori tabili mi ni ijọba mi, ki ẹnyin ki o le joko lori itẹ́, ati ki ẹnyin ki o le mã ṣe idajọ fun awọn ẹ̀ya Israeli mejila.
Jesu Sọtẹ́lẹ̀ pé Peteru Yóo Sẹ́ Òun
(Mat 26:31-35; Mak 14:27-31; Joh 13:36-38)
31Oluwa si wipe, Simoni, Simoni, sawõ, Satani fẹ lati ni ọ, ki o le kù ọ bi alikama:
32 Ṣugbọn mo ti gbadura fun ọ, ki igbagbọ́ rẹ ki o má yẹ̀; ati iwọ nigbati iwọ ba si yipada, mu awọn arakunrin rẹ li ọkàn le.
33O si wi fun u pe, Oluwa, mo mura tan lati bá ọ lọ sinu tubu, ati si ikú.
34O si wipe, Mo wi fun ọ, Peteru, akukọ ki yio kọ loni ti iwọ o fi sẹ́ mi li ẹrinmẹta pe, iwọ kò mọ̀ mi.
Idà Meji
35O si wi fun wọn pe, Nigbati mo rán nyin lọ laini asuwọn, ati àpo, ati bàta, ọdá ohun kan da nyin bi? Nwọn si wipe, Rara o.
36Nigbana li o wi fun wọn pe, Ṣugbọn nisisiyi, ẹniti o ba li asuwọn, ki o mu u, ati àpo pẹlu: ẹniti kò ba si ni idà, ki o tà aṣọ rẹ̀, ki o si fi rà kan.
37 Nitori mo wi fun nyin pe, Eyi ti a ti kọwe rẹ̀ kò le ṣe ki o má ṣẹ lara mi, A si kà a mọ awọn arufin. Nitori ohun wọnni nipa ti emi o li opin.
38Nwọn si wipe, Oluwa, sawõ, idà meji mbẹ nihinyi. O si wi fun wọn pe, O to.
Adura Lórí Òkè Olifi
(Mat 26:36-46; Mak 14:32-42)
39Ó si jade, o si lọ bi iṣe rẹ̀ si òke Olifi; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tọ̀ ọ lẹhin.
40Nigbati o wà nibẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹ mã gbadura, ki ẹnyin ki o máṣe bọ sinu idẹwò.
41O si fi wọn silẹ niwọn isọko kan, o si kunlẹ o si ngbadura,
42Wipe, Baba, bi iwọ ba fẹ, gbà ago yi lọwọ mi: ṣugbọn ifẹ ti emi kọ́, bikoṣe tirẹ ni ki a ṣe.
43Angẹli kan si yọ si i lati ọrun wá, o ngbà a ni iyanju.
44Bi o si ti wà ni iwaya-ija o ngbadura si i kikankikan: õgùn rẹ̀ si dabi iro ẹ̀jẹ nla, o nkán silẹ.
45Nigbati o si dide kuro ni ibi adura, ti o si tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, o ba wọn, nwọn nsùn fun ibanujẹ,
46O si wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nsùn si? ẹ dide, ẹ mã gbadura, ki ẹnyin ki o máṣe bọ́ sinu idẹwò.
Judasi Fi Jesu fún Àwọn Ọ̀tá
(Mat 26:47-56; Mak 14:43-50; Joh 18:3-11)
47Bi o si ti nsọ lọwọ, kiyesi i, ọ̀pọ enia, ati ẹniti a npè ni Judasi, ọkan ninu awọn mejila, o ṣaju wọn o sunmọ Jesu lati fi ẹnu kò o li ẹnu.
48Jesu si wi fun u pe, Judasi, iwọ fi ifẹnukonu fi Ọmọ-enia hàn?
49Nigbati awọn ti o wà lọdọ rẹ̀ ri bi yio ti jasi, nwọn bi i pe, Oluwa, ki awa ki o fi idà ṣá wọn?
50Ọkan ninu wọn si fi idà ṣá ọmọ-ọdọ olori alufa, o si ke etí ọtún rẹ̀ sọnù.
51Ṣugbọn Jesu dahùn o wipe, Ẹ jọwọ rẹ̀ bayi na. O si fi ọwọ́ tọ́ ọ li etí, o si wò o sàn.
52Jesu si wi fun awọn olori alufa, ati awọn olori ẹṣọ́ tẹmpili, ati awọn agbagba, ti nwọn jade tọ̀ ọ wá, pe, Ẹnyin ha jade wá ti ẹnyin ti idà ati ọgọ bi ẹni tọ ọlọṣa wá?
53 Nigbati emi wà pẹlu nyin lojojumọ ni tẹmpili, ẹnyin ko nà ọwọ́ mu mi: ṣugbọn akokò ti nyin li eyi, ati agbara òkunkun.
Judasi Fi Jesu fún Àwọn Ọ̀tá
(Mat 26:47-56; Mak 14:43-50; Joh 18:3-11)
54Nwọn si gbá a mu, nwọn si fà a lọ, nwọn si mu u wá si ile olori alufa. Ṣugbọn Peteru tọ̀ ọ lẹhin li òkere.
55Nigbati nwọn si ti dana larin gbọ̀ngan, ti nwọn si joko pọ̀, Peteru joko larin wọn.
56Ọmọbinrin kan si ri i bi o ti joko nibi imọlẹ iná na, o si tẹjumọ́ ọ, o ni, Eleyi na wà pẹlu rẹ̀.
57O si sẹ́, o wipe, Obinrin yi, emi ko mọ̀ ọ.
58Kò pẹ lẹhin na ẹlomiran si ri i, o ni, Iwọ pẹlu wà ninu wọn. Ṣugbọn Peteru wipe, ọkunrin yi, Emi kọ.
59O si to iwọn wakati kan ẹlomiran gidigidi tẹnumọ́ ọ, nwipe, Nitõtọ eleyi na wà pẹlu rẹ̀: nitori ara Galili ni iṣe.
60Ṣugbọn Peteru wipe, ọkunrin yi, emi kò mọ̀ ohun ti iwọ nwi. Lojukanna, bi o ti nwi li ẹnu, akukọ kọ.
61Oluwa si yipada, o wò Peteru. Peteru si ranti ọ̀rọ Oluwa, bi o ti wi fun u pe, Ki akukọ ki o to kọ, iwọ o sẹ́ mi li ẹrinmẹta.
62Peteru si bọ si ode, o sọkun kikorò.
Wọ́n Fi Jesu Ṣẹ̀sín
(Mat 26:67-68; Mak 14:65)
63Awọn ọkunrin ti nwọn mu Jesu, si fi i ṣe ẹlẹyà, nwọn lù u.
64Nigbati nwọn si dì i loju, nwọn lù u niwaju, nwọn mbi i pe, Sọtẹlẹ, tani lù ọ nì?
65Ati nkan pipọ miran ni nwọn nfi ọ̀rọ-òdi sọ si i.
Wọ́n Mú Jesu Lọ Siwaju Ìgbìmọ̀
(Mat 26:59-66; Mak 14:55-64; Joh 18:19-24)
66Nigbati ilẹ si mọ́, awọn àgba awọn enia, ati awọn olori alufa, ati awọn akọwe pejọ, nwọn si fà a wá si ajọ wọn, nwọn nwipe,
67Bi iwọ ba iṣe Kristi nã, sọ fun wa. O si wi fun wọn pe, Bi mo ba wi fun nyin, ẹnyin ki yio gbagbọ́:
68 Bi mo ba si bi nyin lẽre pẹlu, ẹnyin kì yio da mi lohùn, bẹ̃li ẹnyin kì yio jọwọ mi lọwọ lọ.
69 Ṣugbọn lati isisiyi lọ li Ọmọ-enia yio joko li ọwọ́ ọtún agbara Ọlọrun.
70Gbogbo wọn si wipe, Iwọ ha ṣe Ọmọ Ọlọrun bi? O si wi fun wọn pe, Ẹnyin wipe, emi ni.
71Nwọn si wipe, Kili awa nfẹ ẹlẹri mọ́ si? Awa tikarawa sá ti gbọ́ li ẹnu ara rẹ̀.
Currently Selected:
Luk 22: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.