YouVersion Logo
Search Icon

Luk 3

3
Iwaasu Johanu Onítẹ̀bọmi
(Mat 3:1-12; Mak 1:1-8; Joh 1:19-28)
1LI ọdún kẹdogun ijọba Tiberiu Kesari, nigbati Pontiu Pilatu jẹ Bãlẹ, Judea, ti Herodu si jẹ tetrarki Galili, Filippi arakunrin rẹ̀ si jẹ tetrarki Iturea ati ti Trakoniti, Lisania si jẹ tetrarki Abilene,
2Ti Anna on Kaiafa nṣe olori awọn alufa, nigbana li ọ̀rọ Ọlọrun tọ̀ Johanu ọmọ Sakariah wá ni ijù.
3O si wá si gbogbo ilẹ ìha Jordani, o nwasu baptismu ironupiwada fun imukuro ẹ̀ṣẹ;
4Bi a ti kọ ọ ninu iwe ọ̀rọ woli Isaiah pe, Ohùn ẹni ti nkigbe ni ijù, Ẹ tún ọ̀na Oluwa ṣe, ẹ mu ipa-ọna rẹ̀ tọ́.
5Gbogbo ọgbún li a o kún, gbogbo òke nla ati òke kekere li a o tẹ-bẹrẹ; wíwọ li a o ṣe ni títọ, ati ọ̀na palapala li a o sọ di kikuna;
6Gbogbo enia ni yio si ri igbala Ọlọrun.
7Nigbana li o wi fun ọ̀pọ awọn enia ti o wá lati baptisi lọdọ rẹ̀ pe, Ẹnyin iran paramọlẹ, tali o kìlọ fun nyin lati sá kuro ninu ibinu ti mbọ̀?
8Nitorina ki ẹnyin ki o so eso ti o yẹ fun ironupiwada, ki ẹ má si ṣe bẹ̀rẹ si iwi ninu ara nyin pe, awa ni Abrahamu ni baba: ki emi ki o wi fun nyin, Ọlọrun le gbe ọmọ dide fun Abrahamu ninu okuta wọnyi.
9Ati nisisiyi pẹlu, a fi ãke le gbòngbo igi na: gbogbo igi ti kò ba so eso rere, a ke e lulẹ, a si wọ́ ọ jù sinu iná.
10Awọn enia si mbi i pe, Kini ki awa ki o ha ṣe?
11O dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹniti o ba li ẹ̀wu meji, ki o fi ọkan fun ẹniti kò ni; ẹniti o ba si li onjẹ, ki o ṣe bẹ̃ pẹlu.
12Awọn agbowode si tọ̀ ọ wá lati baptisi lọdọ rẹ̀, nwọn si bi i pe, Olukọni, kili awa o ha ṣe?
13O si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe fi agbara gbà jù bi a ti rán nyin lọ mọ́.
14Awọn ọmọ-ogun si bère lọdọ rẹ̀, pe, Ati awa, kili awa o ṣe? O si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe huwa ipá si ẹnikẹni, ki ẹ má si ṣe rẹ ẹnikẹni jẹ; ki owo onjẹ nyin to nyin.
15Bi awọn enia si ti nreti, ti gbogbo wọn si nrò ninu ara wọn nitori Johanu, bi on ni Kristi bi on kọ́;
16Johanu dahùn o si wi fun gbogbo wọn pe, Lõtọ li emi nfi omi baptisi nyin; ṣugbọn ẹniti o lagbarà ju mi lọ mbọ̀, okùn bàta ẹsẹ ẹniti emi ko to itú: on ni yio fi Ẹmí Mimọ́ ati iná baptisi nyin:
17Ẹniti atẹ rẹ̀ mbẹ li ọwọ́ rẹ̀, lati gbá ilẹ ipaka rẹ̀ mọ́ toto, ki o si kó alikama rẹ̀ sinu aká; ṣugbọn ìyangbo ni yio fi iná ajõku sun.
18Ohun pipọ pẹlu li o si wasu fun awọn enia ni ọrọ iyanju rẹ̀.
19Ṣugbọn Herodu tetrarki, ti o bawi nitori Herodia aya Filippi arakunrin rẹ̀, ati nitori ohun buburu gbogbo ti Herodu ti ṣe,
20O fi eyi pari gbogbo rẹ̀ niti o fi Johanu sinu tubu.
Johanu Ṣe Ìrìbọmi fún Jesu
(Mat 3:13-17; Mak 1:9-11)
21Nigbati a si baptisi awọn enia gbogbo tan, o si ṣe, a baptisi Jesu pẹlu, bi o ti ngbadura, ọrun ṣí silẹ̀,
22Ẹmí Mimọ́ si sọkalẹ si ori rẹ̀ li àwọ àdaba, ohùn kan si ti ọrun wá, ti o wipe, Iwọ ni ayanfẹ ọmọ mi; ẹniti inu mi dùn si gidigidi.
Ìrandíran Jesu
(Mat 1:1-17)
23Jesu tikararẹ̀ nto bi ẹni ìwọn ọgbọ̀n ọdún, o jẹ (bi a ti fi pè) ọmọ Josefu, ti iṣe ọmọ Eli,
24Ti iṣe ọmọ Mattati, ti iṣe ọmọ Lefi, ti iṣe ọmọ Melki, ti iṣe ọmọ Janna, ti iṣe ọmọ Josefu,
25Ti iṣe ọmọ Mattatai, ti iṣe ọmọ Amosi, ti iṣe ọmọ Naumu, ti iṣe ọmọ Esli, ti iṣe ọmọ Naggai,
26Ti iṣe ọmọ Maati, ti iṣe ọmọ Mattatia, ti iṣe ọmọ Simei, ti iṣe ọmọ Josefu, ti iṣe ọmọ Juda,
27Ti iṣe ọmọ Joanna, ti iṣe ọmọ Resa, ti iṣe ọmọ Sorobabeli, ti iṣe ọmọ Salatieli, ti iṣe ọmọ Neri,
28Ti iṣe ọmọ Melki, ti iṣe ọmọ Addi, ti iṣe ọmọ Kosamu, ti iṣe ọmọ Elmodamu, ti iṣe ọmọ Eri,
29Ti iṣe ọmọ Jose, ti iṣe ọmọ Elieseri, ti iṣe ọmọ Jorimu, ti iṣe ọmọ Mattati, ti iṣe ọmọ Lefi,
30Ti iṣe ọmọ Simeoni, ti iṣe ọmọ Juda, ti iṣe ọmọ Josefu, ti iṣe ọmọ Jonani, ti iṣe ọmọ Eliakimu,
31Ti iṣe ọmọ Melea, ti iṣe ọmọ Menani, ti iṣe ọmọ Mattata, ti iṣe ọmọ Natani, ti iṣe ọmọ Dafidi,
32Ti iṣe ọmọ Jesse, ti iṣe ọmọ Obedi, ti iṣe ọmọ Boasi, ti iṣe ọmọ Salmoni, ti iṣe ọmọ Naassoni,
33Ti iṣe ọmọ Aminadabu, ti iṣe ọmọ Aramu, ti iṣe ọmọ Esromu, ti iṣe ọmọ Faresi, ti iṣe ọmọ Juda,
34Ti iṣe ọmọ Jakọbu, ti iṣe ọmọ Isaaki, ti iṣe ọmọ Abrahamu, ti iṣe ọmọ Tera, ti iṣe ọmọ Nakoru,
35Ti iṣe ọmọ Saruku, ti iṣe ọmọ Ragau, ti iṣe ọmọ Faleki, ti iṣe ọmọ Eberi, ti iṣe ọmọ Sala,
36Ti iṣe ọmọ Kainani, ti iṣe ọmọ Arfaksadi, ti iṣe ọmọ Semu, ti iṣe ọmọ Noa, ti iṣe ọmọ Lameki,
37Ti iṣe ọmọ Metusala, ti iṣe ọmọ Enoku, ti iṣe ọmọ Jaredi, ti iṣe ọmọ Maleleeli, ti iṣe ọmọ Kainani,
38Ti iṣe ọmọ Enosi, ti iṣe ọmọ Seti, ti iṣe ọmọ Adamu, ti iṣe ọmọ Ọlọrun.

Currently Selected:

Luk 3: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in