Mat 28
28
Ajinde Jesu
(Mak 16:1-10; Luk 24:1-12; Joh 20:1-10)
1LI opin ọjọ isimi, bi ilẹ ọjọ kini ọ̀sẹ ti bèrẹ si imọ́, Maria Magdalene ati Maria keji wá lati wò ibojì na.
2Si wò o, ìṣẹlẹ nla ṣẹ̀: nitori angẹli Oluwa ti ọrun sọkalẹ wá, o si yi okuta na kuro, o si joko lé e.
3Oju rẹ̀ dabi manamana, aṣọ rẹ̀ si fún bi ẹ̀gbọn owu:
4Nitori ẹ̀ru rẹ̀ awọn oluṣọ warìri, nwọn si dabi okú.
5Angẹli na si dahùn, o si wi fun awọn obinrin na pe, Ẹ má bẹ̀ru: nitori emi mọ̀ pe ẹnyin nwá Jesu, ti a ti kàn mọ agbelebu.
6Kò si nihinyi: nitori o ti jinde gẹgẹ bi o ti wi. Wá, ẹ wò ibiti Oluwa ti dubulẹ si.
7Ẹ si yara lọ isọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, o ti jinde kuro ninu okú; wo o, ó ṣãju nyin lọ si Galili; nibẹ̀ li ẹnyin o gbé ri i: wo o, mo ti sọ fun nyin.
8Nwọn si fi ibẹru pẹlu ayọ̀ nla yara lọ kuro ni ibojì; nwọn si saré lọ iròhin fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.
9Bi nwọn si ti nlọ isọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, wo o, Jesu pade wọn, o wipe, Alafia. Nwọn si wá, nwọn si gbá a li ẹsẹ mu, nwọn si tẹriba fun u.
10Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Ẹ má bẹ̀ru: ẹ lọ isọ fun awọn arakunrin mi pe, ki nwọn ki o lọ si Galili, nibẹ̀ ni nwọn o gbé ri mi.
Ìròyìn Àwọn tí Ń Ṣọ́ Ibojì
11Njẹ bi nwọn ti nlọ, wo o, ninu awọn olusọ wá si ilu, nwọn rohin gbogbo nkan wọnyi ti o ṣe fun awọn olori alufa.
12Nigbati awọn pẹlu awọn agbàgba pejọ, ti nwọn si gbìmọ, nwọn fi ọ̀pọ owo fun awọn ọmọ-ogun na,
13Nwọn wi fun wọn pe, Ẹ wipe, Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá li oru, nwọn si ji i gbé lọ nigbati awa sùn.
14Bi eyi ba de etí Bãlẹ, awa o yi i li ọkàn pada, a o si gbà nyin silẹ.
15Bẹ̃ni nwọn gbà owo na, nwọn si ṣe gẹgẹ bi a ti kọ́ wọn: ọ̀rọ yi si di rirò kiri lọdọ awọn Ju titi di oni.
Jesu Rán Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ Níṣẹ́
(Mak 16:14-18; Luk 24:36-49; Joh 20:19-23; Iṣe Apo 1:6-8)
16Nigbana li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mọkanla jade lọ si Galili, si ori òke ti Jesu ti sọ fun wọn.
17Nigbati nwọn si ri i, nwọn foribalẹ fun u: ṣugbọn awọn miran ṣiyemeji.
18Jesu si wá, o si sọ fun wọn, wipe, Gbogbo agbara li ọrun ati li aiye li a fifun mi.
19 Nitorina ẹ lọ, ẹ ma kọ́ orilẹ-ède gbogbo, ki ẹ si mã baptisi wọn ni orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti Ẹmí Mimọ́:
20 Ki ẹ mã kọ́ wọn lati mã kiyesi ohun gbogbo, ohunkohun ti mo ti pa li aṣẹ fun nyin: ẹ si kiyesi i, emi wà pẹlu nyin nigbagbogbo, titi o fi de opin aiye. Amin.
Currently Selected:
Mat 28: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.