Mak 14
14
Ọ̀tẹ̀ Láti Pa Jesu
(Mat 26:1-5; Luk 22:1-2; Joh 11:45-53)
1LẸHIN ọjọ meji ni ajọ irekọja, ati ti aiwukara: ati awọn olori alufa ati awọn akọwe nwá ọ̀na bi nwọn iba ti fi ẹ̀tan mu u, ki nwọn ki o pa a.
2Ṣugbọn nwọn wipe, Ki iṣe li ọjọ ajọ, ki ariwo ki o má ba wà ninu awọn enia.
Obinrin kan Fi Òróró Kun Jesu ní Bẹtani
(Mat 26:6-13; Joh 12:1-8)
3Nigbati o si wà ni Betani ni ile Simoni adẹtẹ̀, bi o ti joko tì onjẹ, obinrin kan ti o ni oruba alabasta ororo ikunra nardi iyebiye, o wá, o si fọ́ orúba na, o si ndà a si i lori.
4Awọn kan si wà ti inu wọn ru ninu ara wọn, nwọn si wipe, Nitori kili a ṣe nfi ororo ikunra yi ṣòfo?
5A ba sá tà ororo ikunra yi jù ìwọn ọ̃dunrun owo idẹ lọ a ba si fifun awọn talakà. Nwọn si nkùn si i.
6Ṣugbọn Jesu wipe, Ẹ jọwọ rẹ̀ si; ẽṣe ti ẹnyin fi mba a wi? Iṣẹ́ rere li o ṣe si mi lara.
7 Nigbagbogbo li ẹnyin sá ni talakà pẹlu nyin, ẹnyin le ma ṣore fun wọn nigbakugba ti ẹnyin fẹ; ṣugbọn emi li ẹnyin kó ni nigbagbogbo.
8 O ṣe eyi ti o le ṣe: o wá ṣiwaju lati fi oróro kùn ara mi fun sisinku mi.
9 Lõtọ ni mo wi fun nyin, Nibikibi ti a o gbé wasu ihinrere yi ni gbogbo aiye, nibẹ̀ pẹlu li a o si rò ihin eyi ti obinrin yi ṣe lati fi ṣe iranti rẹ̀.
Judasi Ṣe Ètò láti Fi Jesu fún Àwọn Ọ̀tá Rẹ̀
(Mat 26:14-16; Luk 22:3-6)
10Judasi Iskariotu, ọkan ninu awọn mejila, si tọ̀ awọn olori alufa lọ, lati fi i le wọn lọwọ.
11Nigbati nwọn si gbọ́, nwọn yọ̀, nwọn si ṣe ileri lati fun u li owo. O si nwá ọ̀na bi yio ti ṣe fi i le wọn lọwọ.
Àjọ̀dún Ìrékọjá
(Mat 26:17-25; Luk 22:7-14,21-23; Joh 13:21-30)
12Li ọjọ kini ajọ aiwukara, nigbati nwọn npa ẹran irekọja, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wi fun u pe, Nibo ni iwọ nfẹ ki a lọ ipèse silẹ, ki iwọ́ ki o le jẹ irekọja.
13O si rán awọn meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹ lọ si ilu, ọkunrin kan ti nrù ìṣa omi yio pade nyin: ẹ mã tọ̀ ọ lẹhin.
14 Ati ibikibi ti o ba gbé wọ̀, ki ẹnyin ki o wi fun bãle na pe, Olukọni wipe, Nibo ni gbọ̀ngan apejẹ na gbé wà, nibiti emi o gbé jẹ irekọja pẹlu awọn ọmọ-ẹhin mi?
15 On o si fi gbọ̀ngan nla kan loke hàn nyin, ti a ṣe lọṣọ, ti a si pèse tẹlẹ; nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o pèse silẹ dè wa.
16Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si jade lọ, nwọn wá si ilu, nwọn si ri i gẹgẹ bi o ti sọ fun wọn: nwọn si pèse irekọja silẹ.
17Nigbati alẹ lẹ, o wá pẹlu awọn mejila.
18Bi nwọn si ti joko ti nwọn njẹun, Jesu wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ọkan ninu nyin yio fi mi hàn, ani on na ti mba mi jẹun.
19Nwọn si bẹ̀rẹ si ikãnu gidigidi, ati si ibi i lẽre lọkọ̃kan wipe, Emi ni bi? Ekeji si wipe, Emi ni bi?
20O si dahùn o si wi fun wọn pe, Ọkan ninu awọn mejila ni, ti o ntọwọ bọ̀ inu awo pẹlu mi.
21 Nitõtọ Ọmọ-enia nlọ bi a ti kọwe nipa tirẹ̀: ṣugbọn egbé ni fun ọkunrin na, lọdọ ẹniti a gbé ti fi Ọmọ-enia hàn! iba san fun ọkunrin na, bi o ṣepe a kò bí i.
Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa
(Mat 26:26-30; Luk 22:15-20; I. Kor 11:23-25)
22Bi nwọn si ti njẹun, Jesu mu akara, o si sure, o si bu u, o si fifun wọn, o wipe, Gbà, jẹ: eyiyi li ara mi.
23O si gbe ago, nigbati o si sure tan, o fifun wọn: gbogbo nwọn si mu ninu rẹ̀.
24O si wi fun wọn pe, Eyi li ẹ̀jẹ mi ti majẹmu titun, ti a ta silẹ fun ọ̀pọ enia.
25 Lõtọ ni mo wi fun nyin, emi kì yio mu ninu eso ajara mọ́, titi yio fi di ọjọ na, nigbati emi o mu u ni titun ni ijọba Ọlọrun.
26Nigbati nwọn si kọ orin kan tan, nwọn jade lọ sori òke Olifi.
Jesu Sọtẹ́lẹ̀ pé Peteru Yóo Sẹ́ Òun
(Mat 26:31-35; Luk 22:31-34; Joh 13:36-38)
27Jesu si wi fun wọn pe, Gbogbo nyin ni yio kọsẹ̀ lara mi li oru oni: nitoriti a ti kọwe rẹ̀ pe, Emi o lù oluṣọ agutan, a o si tú agbo agutan ká kiri.
28 Ṣugbọn lẹhin igba ti mo ba jinde, emi o ṣaju nyin lọ si Galili.
29Ṣugbọn Peteru wi fun u pe, Bi gbogbo enia tilẹ kọsẹ̀, ṣugbọn emi kọ́.
30Jesu si wi fun u pe, Lõtọ ni mo wi fun ọ pe, loni yi, ani li alẹ yi, ki akukọ ki o to kọ nigba meji, iwọ o sẹ́ mi nigba mẹta.
31Ṣugbọn o tẹnumọ ọ gidigidi wipe, Bi o tilẹ di ati ba ọ kú, emi ko jẹ sẹ́ ọ bi o ti wù ki o ri. Gẹgẹ bẹ̃ni gbogbo wọn wi pẹlu.
Jesu Gbadura ní Gẹtisemani
(Mat 26:36-46; Luk 22:39-46)
32Nwọn si wá si ibi kan ti a npè ni Getsemane: o si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ joko nihinyi, nigbati mo ba lọ igbadura.
33O si mu Peteru ati Jakọbu ati Johanu pẹlu rẹ̀, ẹnu si bẹrẹ si yà a gidigidi, o si bẹré si rẹ̀wẹsi.
34O si wi fun wọn pẹ, Ọkàn mi nkãnu gidigidi titi de ikú: ẹ duro nihin, ki ẹ si mã ṣọna.
35O si lọ siwaju diẹ, o si dojubolẹ, o si gbadura pe, bi o ba le ṣe, ki wakati na le kọja kuro lori rẹ̀.
36O si wipe, Abba, Baba, ṣiṣe li ohun gbogbo fun ọ; mú ago yi kuro lori mi: ṣugbọn kì iṣe eyiti emi fẹ, bikoṣe eyiti iwọ fẹ,
37O si wá, o ba wọn, nwọn nsùn, o si wi fun Peteru pe, Simoni, iwọ nsùn? iwọ kò le ṣọna ni wakati kan?
38 Ẹ mã ṣọna, kì ẹ si mã gbadura, ki ẹ má ba bọ́ sinu idẹwò. Lõtọ li ẹmí nfẹ, ṣugbọn o ṣe ailera fun ara.
39O si tún pada lọ, o si gbadura, o nsọ ọ̀rọ kanna.
40Nigbati o si pada wá, o tún bá wọn, nwọn nsùn, nitoriti oju wọn kún fun orun, bẹ̃ni nwọn kò si mọ̀ èsi ti nwọn iba fifun u.
41O si wá li ẹrinkẹta, o si wi fun wọn pe, Ẹ mã sùn wayi, ki ẹ si mã simi: o to bẹ̃, wakati na de; wo o, a fi Ọmọ-enia le awọn ẹlẹṣẹ lọwọ.
42 Ẹ dide, ki a ma lọ; wo o, ẹniti o fi mi hàn sunmọ tosi.
Judasi Fi Jesu Fún Àwọn Ọ̀tá
(Mat 26:47-56; Luk 22:47-53; Joh 18:2-12)
43Lojukanna, bi o si ti nsọ lọwọ, Judasi de, ọkan ninu awọn mejila, ati ọ̀pọ enia pẹlu rẹ̀ ti awọn ti idà, pẹlu ọgọ, lati ọdọ olori alufa, ati awọn akọwe, ati awọn agbagba wá.
44Ẹniti o si fi i hàn ti fi àmi fun wọn, wipe, Ẹnikẹni ti mo ba fi ẹnu kò li ẹnu, on na ni; ẹ mu u, ki ẹ si ma fà a lọ li alafia.
45Nigbati o de, o tọ̀ ọ lọ gan, o wipe, Olukọni, olukọni! o si fi ẹnu kò o li ẹnu.
46Nwọn si gbé ọwọ́ wọn le e, nwọn si mu u.
47Ṣugbọn ọkan ninu awọn ti o duro nibẹ̀ fà idà yọ, o si sá ọmọ-ọdọ olori alufa, o si ke etí rẹ̀ kuro.
48Jesu si dahùn o si wi fun wọn pe, Emi li ẹnyin jade tọ̀ wá bi olè, ti ẹnyin ti idà ati ọgọ lati mu?
49 Li ojojumọ li emi wà pẹlu nyin ni tẹmpili, ti emi nkọ́ nyin, ẹnyin kò si mu mi: ṣugbọn iwe-mimọ kò le ṣe alaiṣẹ.
50Gbogbo wọn si fi i silẹ, nwọn si sá lọ.
51Ọmọkunrin kan si ntọ̀ ọ lẹhin, ti o fi aṣọ ọgbọ bò ìhoho rẹ̀; awọn ọmọ-ogun si gbá a mu:
52O si jọwọ aṣọ ọgbọ na lọwọ, o si sá kuro lọdọ wọn nihoho.
Wọ́n Mú Jesu Lọ Siwaju Ìgbìmọ̀
(Mat 26:57-68; Luk 22:54-55,63-71; Joh 18:13-14,19-24)
53Nwọn si mu Jesu lọ ṣọdọ olori alufa: gbogbo awọn olori alufa, ati awọn agbagba, ati awọn akọwe si pejọ pẹlu rẹ̀.
54Peteru si tọ̀ ọ lẹhin li òkere wọ̀ inu ile, titi fi de agbala olori alufa; o si bá awọn ọmọ-ọdọ joko, o si nyána.
55Awọn olori alufa ati gbogbo ajọ ìgbimọ nwá ẹlẹri si Jesu lati pa a; nwọn kò si ri ohun kan.
56Nitoripe ọ̀pọlọpọ li o jẹri eke si i, ṣugbọn ohùn awọn ẹlẹri na kò ṣọkan.
57Awọn kan si dide, nwọn njẹri eke si i, wipe,
58Awa gbọ́ o wipe, Emi ó wó tẹmpili yi ti a fi ọwọ́ ṣe, niwọn ijọ́ mẹta emi o si kọ́ omiran ti a kò fi ọwọ́ ṣe.
59Ati ninu eyi na pẹlu, ohùn wọn kò ṣọkan.
60Olori alufa si dide duro larin, o si bi Jesu lẽre, wipe, Iwọ kò dahùn kan? kili eyi ti awọn wọnyi njẹri si ọ?
61Ṣugbọn Jesu dakẹ, ko si dahùn ohun kan. Olori alufa si tun bi i lẽre, o wi fun u pe, Iwọ ni Kristi na, Ọmọ Olubukun nì?
62Jesu si wipe, Emi ni: ẹnyin o si ri Ọmọ-enia joko li ọwọ́ ọtún agbara, yio si ma ti inu awọsanma ọrun wá.
63Nigbana li olori alufa fà aṣọ rẹ̀ ya, o wipe, Ẹlẹri kili a si nwá?
64Ẹnyin gbọ́ ọrọ-odi na: ẹnyin ti rò o si? Gbogbo wọn si da a lẹbi pe, o jẹbi ikú.
65Awọn miran si bẹ̀rẹ si itutọ́ si i lara, ati si ibò o loju, ati si ikàn a lẹṣẹ́, nwọn si wi fun u pe, Sọtẹlẹ: awọn onṣẹ si nfi atẹlẹ ọwọ́ wọn gbá a loju.
Peteru Sẹ́ Jesu
(Mat 26:69-75; Luk 22:56-62; Joh 18:15-18,25-27)
66Bi Peteru si ti wà ni isalẹ li ãfin, ọkan ninu awọn ọmọbinrin olori alufa wá:
67Nigbati o si ri ti Peteru nyána, o wò o, o si wipe, Iwọ pẹlu ti wà pẹlu Jesu ti Nasareti.
68Ṣugbọn o sẹ́, wipe, Emi ko mọ̀, oyé ohun ti iwọ nwi kò tilẹ yé mi. O si jade lọ si iloro; akukọ si kọ.
69Ọmọbinrin na si tún ri i, o si bẹ̀rẹ si iwi fun awọn ti o duro nibẹ̀ pe, Ọkan ninu wọn ni eyi.
70O si tún sẹ́. O si pẹ diẹ, awọn ti o duro nibẹ̀ tún wi fun Peteru pe, Lõtọ ni, ọkan ninu wọn ni iwọ iṣe: nitoripe ara Galili ni iwọ, ède rẹ si jọ bẹ̃.
71Ṣugbọn o bẹ̀rẹ si iré ati si ibura, wipe, Emi ko mọ̀ ọkunrin yi ẹniti ẹnyin nwi.
72Lojukanna akukọ si kọ lẹrinkeji. Peteru si ranti ọrọ ti Jesu wi fun u pe, Ki akukọ ki o to kọ lẹrinmeji, iwo o sẹ́ mi lẹrinmẹta. Nigbati o si rò o, o sọkun.
Currently Selected:
Mak 14: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.