Owe 14
14
1ỌLUKULUKU ọlọgbọ́n obinrin ni kọ́ ile rẹ̀: ṣugbọn aṣiwere a fi ọwọ ara rẹ̀ fà a lulẹ.
2Ẹniti o nrìn ni iduroṣiṣin rẹ̀ o bẹ̀ru Oluwa: ṣugbọn ẹniti o ṣe arekereke li ọ̀na rẹ̀, o gàn a.
3Li ẹnu aṣiwere ni paṣan igberaga; ṣugbọn ète awọn ọlọgbọ́n ni yio pa wọn mọ́.
4Nibiti malu kò si, ibujẹ a di ofo: ṣugbọn ibisi pupọ mbẹ nipa agbara malu.
5Ẹlẹri olõtọ kò jẹ ṣeke: ṣugbọn ẹ̀tan li ẹlẹri eke ima sọ jade.
6Ẹlẹgan nwá ọgbọ́n, kò si ri i: ṣugbọn ìmọ kò ṣoro fun ẹniti oye ye.
7Kuro niwaju aṣiwere, ati lọdọ ẹniti kò ni ète ìmọ.
8Ọgbọ́n amoye ni ati moye ọ̀na rẹ̀: ṣugbọn iwere awọn aṣiwere li ẹ̀tan.
9Aṣiwere nfi ẹbi-ẹ̀ṣẹ ṣẹsin: ṣugbọn ojurere wà larin awọn olododo.
10Aiya mọ̀ ikoro ara rẹ̀; alejo kò si ni iṣe pẹlu ayọ̀ rẹ̀.
11Ile enia buburu li a o run: ṣugbọn agọ ẹni diduroṣinṣin ni yio ma gbilẹ.
12Ọ̀na kan wà ti o dabi ẹnipe o dara li oju enia, ṣugbọn opin rẹ̀ li ọ̀na ikú.
13Ninu ẹrín pẹlu, aiya a ma kãnu; ati li opin, ayọ̀ a di ibinujẹ.
14Apadasẹhin li aiya ni itẹlọrun lati inu ọ̀na ara rẹ̀: ṣugbọn enia rere lati inu ohun ti iṣe tirẹ̀.
15Òpe enia gbà ọ̀rọ gbogbo gbọ́: ṣugbọn amoye enia wò ọ̀na ara rẹ̀ rere.
16Ọlọgbọ́n enia bẹ̀ru, o si kuro ninu ibi; ṣugbọn aṣiwère gberaga, o si da ara rẹ̀ loju.
17Ẹniti o ba tete binu, huwa wère; ẹni eletè buburu li a korira.
18Awọn òpe jogun iwère; ṣugbọn awọn amoye li a fi ìmọ de li ade.
19Awọn ẹni-buburu tẹriba niwaju awọn ẹnirere; ati awọn enia buburu li ẹnu-ọ̀na awọn olododo.
20A tilẹ korira talaka lati ọdọ aladugbo rẹ̀ wá: ṣugbọn ọlọrọ̀ ni ọrẹ́ pupọ.
21Ẹniti o kẹgàn ẹnikeji rẹ̀, o ṣẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba ṣãnu fun awọn talaka, ibukún ni fun u.
22Awọn ti ngbìmọ buburu kò ha ṣina bi? ṣugbọn ãnu ati otitọ ni fun awọn ti ngbìmọ ire.
23Ninu gbogbo lãla li ère pupọ wà: ṣugbọn ọ̀rọ-ẹnu, lasan ni.
24Adé awọn ọlọgbọ́n li ọrọ̀ wọn: ṣugbọn iwère awọn aṣiwère ni wère.
25Olõtọ ẹlẹri gbà ọkàn silẹ: ṣugbọn ẹlẹri ẹ̀tan sọ̀rọ eke.
26Ni ibẹ̀ru Oluwa ni igbẹkẹle ti o lagbara: yio si jẹ ibi àbo fun awọn ọmọ rẹ̀.
27Ibẹ̀ru Oluwa li orisun ìye, lati kuro ninu ikẹkùn ikú.
28Ninu ọ̀pọlọpọ enia li ọlá ọba: ṣugbọn ninu enia diẹ ni iparun ijoye.
29Ẹniti o ba lọra ati binu, o ni ìmọ pupọ; ṣugbọn ẹniti o ba yara binu o gbe wère leke.
30Ọkàn ti o yè kõro ni ìye ara; ṣugbọn ilara ni ibajẹ egungun.
31Ẹniti o ba nni talaka lara, o gàn Ẹlẹda rẹ̀; ṣugbọn ẹniti o ṣãnu fun talaka o bu ọlá fun u.
32A pa enia buburu run ninu ìwa-buburu rẹ̀; ṣugbọn olododo ni ireti ninu ikú rẹ̀.
33Ọgbọ́n fi idi kalẹ li aiya ẹniti o moye; ṣugbọn a fi i hàn laiya awọn aṣiwère.
34Ododo ni igbé orilẹ-ède leke; ṣugbọn ẹ̀ṣẹ li ẹ̀gan orilẹ-ède.
35Ojurere ọba mbẹ li ọdọ ọlọgbọ́n iranṣẹ; ṣugbọn ibinu rẹ̀ si iranṣẹ ti nhùwa itiju.
Currently Selected:
Owe 14: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.