Owe 19
19
1TALAKA ti nrìn ninu ìwa-titọ rẹ̀, o san jù ẹniti o nṣe arekereke li ète rẹ̀ lọ, ti o si nṣe wère.
2Pẹlupẹlu, ọkàn laini ìmọ, kò dara; ẹniti o ba si fi ẹsẹ rẹ̀ yara yio ṣubu.
3Wère enia yi ọ̀na rẹ̀ po: nigbana ni aiya rẹ̀ binu si Oluwa.
4Ọrọ̀ fà ọrẹ́ pupọ; ṣugbọn talaka di yiyà kuro lọdọ aladugbo rẹ̀.
5Ẹlẹri eke kì yio lọ laijiya, ati ẹniti o si nṣeke kì yio mu u jẹ.
6Ọpọlọpọ ni yio ma bẹ̀bẹ ojurere ọmọ-alade: olukuluku enia ni si iṣe ọrẹ́ ẹniti ntani li ọrẹ.
7Gbogbo awọn arakunrin talaka ni ikorira rẹ̀: melomelo ni awọn ọrẹ́ rẹ̀ yio ha jina si i? o ntẹle ọ̀rọ wọn, ṣugbọn nwọn kò si.
8Ẹniti o gbọ́n, o fẹ ọkàn ara rẹ̀: ẹniti o pa oye mọ́ yio ri rere.
9Ẹlẹri eke kì yio lọ laijiya, ẹniti o si nṣeke yio ṣegbe.
10Ohun rere kò yẹ fun aṣiwère; tabi melomelo fun iranṣẹ lati ṣe olori awọn ijoye.
11Imoye enia mu u lọra ati binu; ogo rẹ̀ si ni lati ré ẹ̀ṣẹ kọja.
12Ibinu ọba dabi igbe kiniun; ṣugbọn ọjurere rẹ̀ dabi ìri lara koriko.
13Aṣiwère ọmọ ni ibanujẹ baba rẹ̀: ìja aya dabi ọ̀ṣọrọ òjo.
14Ile ati ọrọ̀ li ogún awọn baba: ṣugbọn amoye aya, lati ọdọ Oluwa wá ni.
15Imẹlẹ mu ni sun orun fọnfọn; ọkàn ọlẹ li ebi yio si pa.
16Ẹniti o pa ofin mọ́, o pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́; ṣugbọn ẹniti o ba kẹgàn ọ̀na rẹ̀ yio kú.
17Ẹniti o ṣãnu fun talaka Oluwa li o win; ati iṣeun rẹ̀, yio san a pada fun u.
18Nà ọmọ rẹ nigbati ireti wà, má si ṣe gbe ọkàn rẹ le ati pa a.
19Onibinu nla ni yio jiya; nitoripe bi iwọ ba gbà a, sibẹ iwọ o tun ṣe e.
20Fetisi ìmọ ki o si gbà ẹkọ́, ki iwọ ki o le gbọ́n ni igbẹhin rẹ.
21Ete pupọ li o wà li aiya enia; ṣugbọn ìgbimọ Oluwa, eyini ni yio duro.
22Ẹwà enia ni iṣeun rẹ̀: talaka enia si san jù eleke lọ.
23Ibẹ̀ru Oluwa tẹ̀ si ìye: ẹniti o ni i yio joko ni itẹlọrun; a kì yio fi ibi bẹ̀ ẹ wọ́.
24Imẹlẹ enia kì ọwọ rẹ̀ sinu iṣasun, kò si le yọ ọ jade pada wá si ẹnu ara rẹ̀.
25Lu ẹlẹgàn, òpe yio si kiyesi ara: si ba ẹniti o moye wi, oye ìmọ yio si ye e.
26Ẹniti o ba nṣìka si baba rẹ̀, ti o si le iya rẹ̀ jade, on li ọmọ ti nṣe itiju, ti o si mu ẹ̀gan wá.
27Ọmọ mi, dẹkun ati fetisi ẹkọ́ ti imu ni ṣìna kuro ninu ọ̀rọ ìmọ.
28Ẹlẹri buburu fi idajọ ṣẹsin: ẹnu enia buburu si gbe aiṣedẽde mì.
29A pèse ọ̀rọ-idajọ fun awọn ẹlẹgàn, ati paṣan fun ẹ̀hin awọn aṣiwère.
Currently Selected:
Owe 19: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.