YouVersion Logo
Search Icon

O. Daf 19

19
Ògo Ọlọrun ninu àwọn ohun tí Ó dá
1AWỌN ọrun nsọ̀rọ ogo Ọlọrun; ati ofurufu nfi iṣẹ ọwọ rẹ̀ han.
2Ọjọ de ọjọ nfọhùn, ati oru de oru nfi ìmọ hàn.
3Kò si ohùn kan tabi ède kan, nibiti a kò gbọ́ iró wọn.
4Iró wọn la gbogbo aiye ja, ati ọ̀rọ wọn de opin aiye: ninu wọn li o gbe pagọ fun õrun.
5Ti o dabi ọkọ iyawo ti njade ti iyẹwu rẹ̀ wá, ti o si yọ̀ bi ọkunrin alagbara lati sure ije.
6Ijadelọ rẹ̀ ni lati opin ọrun wá, ati ayika rẹ̀ si de ipinlẹ rẹ̀: kò si si ohun ti o fi ara pamọ́ kuro ninu õru rẹ̀.
Òfin OLUWA
7Ofin Oluwa pé, o nyi ọkàn pada: ẹri Oluwa daniloju, o nsọ òpè di ọlọgbọ́n.
8Ilana Oluwa tọ́, o nmu ọkàn yọ̀: aṣẹ Oluwa ni mimọ́, o nṣe imọlẹ oju.
9Ẹ̀ru Oluwa mọ́, pipẹ ni titi lai; idajọ Oluwa li otitọ, ododo ni gbogbo wọn.
10Nwọn jù wura daradara pupọ; nwọn si dùn jù oyin lọ, ati riro afara oyin.
11Pẹlupẹlu nipa wọn li a ti ṣi iranṣẹ rẹ leti; ati ni pipamọ́ wọn ere pipọ̀ mbẹ.
12Tali o le mọ̀ iṣina rẹ̀? wẹ̀ mi mọ́ kuro ninu iṣiṣe ìkọkọ mi.
13Fà iranṣẹ rẹ sẹhin pẹlu kuro ninu ẹ̀ṣẹ ikugbu: máṣe jẹ ki nwọn ki o jọba lori mi: nigbana li emi o duro ṣinṣin, emi o si ṣe alaijẹbi kuro ninu ẹ̀ṣẹ nla nì.
14Jẹ ki ọ̀rọ ẹnu mi, ati iṣaro ọkàn mi, ki o ṣe itẹwọgba li oju rẹ, Oluwa, agbara mi, ati oludande mi.

Currently Selected:

O. Daf 19: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

Videos for O. Daf 19