YouVersion Logo
Search Icon

O. Daf 34

34
Ẹ yin Ọlọrun nítorí Oore Rẹ̀
Orin Dafidi, nigbati o yi ìwa rẹ̀ pada niwaju Abimeleki; ẹni ti o lé e, ti on si lọ.
1EMI o ma fi ibukún fun Oluwa nigbagbogbo: Iyìn rẹ̀ yio ma wà li ẹnu mi titi lai.
2Ọkàn mi yio ma ṣogo rẹ̀ niti Oluwa: awọn onirẹlẹ yio gbọ́, inu wọn yio si ma dùn.
3Gbé Oluwa ga pẹlu mi, ki a si jumọ gbé orukọ rẹ̀ leke.
4Emi ṣe afẹri Oluwa, o si gbohùn mi; o si gbà mi kuro ninu gbogbo ìbẹru mi.
5Nwọn wò o, imọlẹ si mọ́ wọn: oju kò si tì wọn.
6Ọkunrin olupọnju yi kigbe pè, Oluwa si gbohùn rẹ̀, o si gbà a ninu gbogbo ipọnju rẹ̀:
7Angeli Oluwa yi awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀ ká, o si gbà wọn.
8Tọ́ ọ wò, ki o si ri pe, rere ni Oluwa: alabukún fun li ọkunrin na ti o gbẹkẹle e.
9Ẹ bẹ̀ru Oluwa, ẹnyin enia rẹ̀ mimọ́: nitoriti kò si aini fun awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀,
10Awọn ọmọ kiniun a ma ṣe alaini, ebi a si ma pa wọn: ṣugbọn awọn ti nwá Oluwa, kì yio ṣe alaini ohun ti o dara.
11Wá, ẹnyin ọmọ, fi eti si mi: emi o kọ́ nyin li ẹ̀ru Oluwa.
12Ọkunrin wo li o nfẹ ìye, ti o si nfẹ ọjọ pipọ, ki o le ma ri rere?
13Pa ahọn rẹ mọ́ kuro ninu ibi, ati ète rẹ kuro li ẹ̀tan sisọ.
14Lọ kuro ninu ibi, ki o si ma ṣe rere; ma wá alafia, ki o si lepa rẹ̀.
15Oju Oluwa mbẹ lara awọn olododo, eti rẹ̀ si ṣi si igbe wọn.
16Oju Oluwa kan si awọn ti nṣe buburu, lati ke iranti wọn kuro lori ilẹ.
17Awọn olododo nke, Oluwa si gbọ́, o si yọ wọn jade ninu iṣẹ́ wọn gbogbo.
18Oluwa mbẹ leti ọdọ awọn ti iṣe onirobinujẹ ọkàn; o si gbà iru awọn ti iṣe onirora ọkàn là.
19Ọ̀pọlọpọ ni ipọnju olododo; ṣugbọn Oluwa gbà a ninu wọn gbogbo.
20O pa gbogbo egungun rẹ̀ mọ́; kò si ọkan ti o ṣẹ́ ninu wọn.
21Ibi ni yio pa enia buburu; ati awọn ti o korira olododo yio jẹbi.
22Oluwa rà ọkàn awọn iranṣẹ rẹ̀; ọkan ninu awọn ti o gbẹkẹle e kì yio jẹbi.

Currently Selected:

O. Daf 34: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in