O. Daf 88
88
Adura nígbà ìpọ́njú
1OLUWA Ọlọrun igbala mi, emi nkigbe lọsan ati loru niwaju rẹ.
2Jẹ ki adura mi ki o wá si iwaju rẹ: dẹ eti rẹ silẹ si igbe mi.
3Nitori ti ọkàn mi kún fun ipọnju, ẹmi mi si sunmọ isa-okú.
4A kà mi pẹlu kún awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò: emi dabi ọkunrin ti kò ni ipá.
5Ẹniti a kọ̀ silẹ lãrin awọn okú, bi awọn ẹni pipa ti o dubulẹ ni isa-okú, ẹniti iwọ kò ranti mọ́: a si ke wọn kuro nipa ọwọ rẹ.
6Iwọ ti fi mi le ibi isalẹ ti o jìn julọ, ninu okunkun, ninu ọgbun.
7Ibinu rẹ lẹ̀ mọ mi lara kikan, iwọ si ti fi riru omi rẹ gbogbo ba mi ja.
8Iwọ ti mu awọn ojulumọ mi jina si mi; iwọ si sọ mi di irira si wọn; a se mi mọ́, emi kò le jade.
9Oju mi nkãnu nitori ipọnju: Oluwa, emi ti npè ọ lojojumọ, emi si ti nawọ mi si ọ.
10Iwọ o fi iṣẹ iyanu rẹ hàn fun okú bi? awọn okú yio ha dide ki nwọn si ma yìn ọ bi?
11A o ha fi iṣeun ifẹ rẹ hàn ni isà-òkú bi? tabi otitọ rẹ ninu iparun?
12A ha le mọ̀ iṣẹ iyanu rẹ li okunkun bi? ati ododo rẹ ni ilẹ igbagbe?
13Ṣugbọn iwọ ni mo kigbe si, Oluwa; ati ni kutukutu owurọ li adura mi yio ṣaju rẹ.
14Oluwa, ẽṣe ti iwọ fi ṣa ọkàn mi tì? ẽṣe ti iwọ fi pa oju rẹ mọ́ kuro lọdọ mi?
15Iṣẹ́ nṣẹ mi, emi mura ati kú lati igba ewe mi wá: nigbati ẹ̀ru rẹ ba mbà mi, emi di gbéregbère.
16Ifẹju ibinu rẹ kọja lara mi; ìbẹru rẹ ti ke mi kuro.
17Nwọn wá yi mi ka li ọjọ gbogbo bi omi: nwọn yi mi kakiri tan.
18Olufẹ ati ọrẹ ni iwọ mu jina si mi, ati awọn ojulumọ mi ninu okunkun.
Currently Selected:
O. Daf 88: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.