YouVersion Logo
Search Icon

O. Daf 9

9
Ọpẹ́ fún Ọlọrun nítorí Ìdájọ́ Òdodo Rẹ̀
1EMI o fi gbogbo aiya mi yìn Oluwa: emi o fi gbogbo iṣẹ iyanu rẹ hàn.
2Emi o yọ̀, emi o si ṣe inu-didùn ninu rẹ, emi o si kọrin iyìn si orukọ rẹ, iwọ Ọga-ogo julọ.
3Nigbati awọn ọta mi ba pẹhinda, nwọn o ṣubu, nwọn o si ṣegbe ni iwaju rẹ.
4Nitori iwọ li o ti mu idajọ mi ati idi ọ̀ran mi duro; iwọ li o joko lori itẹ́, ti o nṣe idajọ ododo.
5Iwọ ba awọn orilẹ-ède wi, iwọ pa awọn enia buburu run, iwọ pa orukọ wọn rẹ́ lai ati lailai.
6Niti ọta, iparun wọn pari tan lailai: iwọ li o si ti run ilu wọnni; iranti wọn si ti ṣegbe pẹlu wọn.
7Ṣugbọn Oluwa yio wà titi lailai: o ti tẹ́ itẹ́ rẹ̀ silẹ fun idajọ.
8On o si ṣe idajọ aiye li ododo, yio ṣe idajọ fun awọn enia li otitọ ìwa.
9Oluwa ni yio ṣe àbo awọn ẹni-inilara, àbo ni igba ipọnju.
10Awọn ti o si mọ̀ orukọ rẹ o gbẹkẹ le ọ: nitori iwọ, Oluwa, kò ti ikọ̀ awọn ti nṣe afẹri rẹ silẹ.
11Ẹ kọrin iyìn si Oluwa, ti o joko ni Sioni: ẹ fi iṣẹ rẹ̀ hàn ninu awọn enia.
12Nigbati o wadi ẹjọ-ẹ̀jẹ, o ranti wọn: on kò si gbagbe ẹkún awọn olupọnju.
13Ṣãnu fun mi, Oluwa; rò iṣẹ́ ti emi nṣẹ́ lọwọ awọn ti o korira mi, iwọ ti o gbé ori mi soke kuro li ẹnu-ọ̀na ikú.
14Ki emi ki o le ma fi gbogbo iyìn rẹ hàn li ẹnu-ọ̀na ọmọbinrin Sioni, emi o ma yọ̀ ni igbala rẹ.
15Awọn orilẹ-ède jìn sinu ọ̀fin ti nwọn wà: ninu àwọn ti nwọn dẹ silẹ li ẹsẹ ara wọn kọ́.
16A mọ̀ Oluwa, nipa idajọ ti o nṣe: nipa iṣẹ ọwọ enia buburu li a fi ndẹkùn mu u.
17Ori awọn enia buburu li a o dà si ọrun apadi, ati gbogbo orilẹ-ède ti o gbagbe Ọlọrun.
18Nitori pe a kì yio gbagbe awọn alaini lailai: abá awọn talaka kì yio ṣegbe lailai.
19Oluwa, dide; máṣe jẹ ki enia ki o bori: jẹ ki a ṣe idajọ awọn orilẹ-ède niwaju rẹ.
20Dẹru ba wọn, Oluwa: ki awọn orilẹ-ède ki o le mọ̀ ara wọn pe, enia ṣa ni nwọn.

Currently Selected:

O. Daf 9: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

Videos for O. Daf 9