1 Tẹsalonika 1
1
1 Paulu, Sila àti Timotiu.
A kọ ọ́ sí ìjọ tí ó wà ní ìlú Tẹsalonika, àwọn ẹni tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run Baba àti ti Olúwa Jesu Kristi.
Kí ìbùkún àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Jesu Kristi kí ó jẹ́ tiyín.
Ọpẹ́ fún ìgbàgbọ́ àwọn ará Tẹsalonika
2 Gbogbo ìgbà ni a máa ń fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run nítorí yín, a sì ń gbàdúrà fún un yín nígbà gbogbo pẹ̀lú. 3 A ń rántí yin ni àìsimi nígbà gbogbo níwájú Ọlọ́run àti Baba nípa iṣẹ́ ìgbàgbọ́ yín, iṣẹ́ ìfẹ́ yín àti ìdúró ṣinṣin ìrètí yín nínú Jesu Kristi Olúwa wa.
4 Àwa mọ̀ dájúdájú, ẹ̀yin olùfẹ́ wa, wí pé Ọlọ́run ti yàn yín fẹ́ fún ara rẹ̀. 5 Nítorí pé, nígbà tí a mú ìhìnrere tọ̀ yín wà, kò rí bí ọ̀rọ̀ lásán tí kò ní ìtumọ̀ sí i yín, bí kò ṣe pẹ̀lú agbára, pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́, pẹ̀lú ìdánilójú tó jinlẹ̀. Bí ẹ̀yin ti mọ irú ènìyàn tí àwa jẹ́ láàrín yín nítorí yín. 6 Tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin pàápàá di aláwòkọ́ṣe wa àti ti Olúwa, ìdí ni pé, ẹ gba ẹ̀rí náà láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé, ó mú wàhálà àti ìbànújẹ́ wá fún yín. 7 Tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin pàápàá fi di àpẹẹrẹ fún gbogbo àwọn onígbàgbọ́ tó wà ní agbègbè Makedonia àti Akaia. 8 Ọ̀rọ̀ Olúwa ti gbilẹ̀ níbi gbogbo láti ọ̀dọ̀ yín láti agbègbè Makedonia àti Akaia lọ, ìgbàgbọ́ yín nínú Ọlọ́run tàn káàkiri. Nítorí náà, a kò ni láti ṣẹ̀ṣẹ̀ ń sọ fún wọn nípa rẹ̀. 9Ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí i ròyìn fún wa bí ẹ ti gbà wá lálejò. Wọ́n ròyìn fún wa pẹ̀lú pé, ẹ ti yípadà kúrò nínú ìbọ̀rìṣà àti wí pé Ọlọ́run alààyè àti òtítọ́ nìkan ṣoṣo ni ẹ ń sìn, 10 àti láti fi ojú ṣọ́nà fún ìpadàbọ̀ Ọmọ rẹ̀ láti ọ̀run wá, ẹni tí ó jí dìde kúrò nínú òkú, Jesu, ẹni tí ó gbà wá lọ́wọ́ ìbínú tí ń bọ̀.
Currently Selected:
1 Tẹsalonika 1: YCB
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.