YouVersion Logo
Search Icon

1 Timotiu 4:7-10

1 Timotiu 4:7-10 YCB

Ṣùgbọ́n kọ ọ̀rọ̀ asán àti ìtàn àwọn àgbà obìnrin, sì máa tọ́ ara rẹ sí ìwà-bí-Ọlọ́run. Nítorí ṣíṣe eré-ìdárayá ni èrè fún ohun díẹ̀, ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run ni èrè fún ohun gbogbo, ó ní ìlérí ti ìgbé ayé ìsinsin yìí àti ti èyí tí ń bọ̀. Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ fún ìtẹ́wọ́gbà gbogbo. Nítorí fún èyí ni àwa ń ṣe làálàá tí a sì ń jìjàkadì, nítorí àwa ní ìrètí nínú Ọlọ́run alààyè, ẹni tí í ṣe Olùgbàlà gbogbo ènìyàn, pẹ̀lúpẹ̀lú ti àwọn ti ó gbàgbọ́.