YouVersion Logo
Search Icon

Efesu Ìfáàrà

Ìfáàrà
Efesu jẹ́ ìlú tí ó wà ní erékùṣù ìhà ìwọ̀-oòrùn Asia kékeré. Nígbà ayé Paulu, ìlú yìí ni ó tóbi ṣe ẹ̀kẹrin ní ilẹ̀ Romu. Ó sì tún jẹ́ ìlú tì ẹ̀sìn òrìṣà Atẹmisi ti gbilẹ̀ púpọ̀.
Paulu jẹ́ kí àwọn ará Efesu mọ̀ pé ohun púpọ̀ ni a ń retí láti ọ̀dọ̀ àwọn tí a pè sí ìgbé ayé tuntun (4.17–5.20). Àwọn ènìyàn Olúwa jẹ́ ọmọ tó ṣe ọ̀wọ́n sí Ọlọ́run, wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe bí Ọlọ́run bá ṣe ṣe (5.1). Wọ́n ń gbé nínú òkùnkùn tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n báyìí wọ́n gbọdọ̀ gbé nínú ìmọ́lẹ̀, ìmọ́lẹ̀ wọn si gbọdọ̀ tàn fún aráyé (5.6-9). Paulu kọ́ àwọn ọkọ, àwọn aya, àwọn ọmọ, àwọn ẹrú àti àwọn ọ̀gá bí a ṣe lè gbé ìgbé ayé onígbàgbọ́ (5.21–6.9).
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìkíni 1.1,2.
ii. Kristi mú ìbùkún ẹ̀mí wá 1.3–3.21.
iii. Ìgbé ayé tuntun ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi 4.1–6.20.
iv. Ìkíni tí ó gbẹ̀yìn 6.21-24.

Currently Selected:

Efesu Ìfáàrà: YCB

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in