Esra 2
2
Àwọn ìgbèkùn tí o padà
1 Lákòókò náà, wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn agbègbè Juda tí ó gòkè wá láti ìgbèkùn láàrín àwọn tí a kó lọ, ẹni tí Nebukadnessari ọba Babeli ti fi agbára mú ní ìgbèkùn lọ sí Babeli (wọ́n padà sí Jerusalẹmu àti Juda, olúkúlùkù sí ìlú rẹ̀. 2Àwọn wọ̀nyí bá Serubbabeli, Jeṣua, Nehemiah, Seraiah, Reelaiah, Mordekai, Bilṣani, Mispari, Bigfai, Rehumu àti Baanah wá):
Iye àwọn ọkùnrin àwọn ènìyàn Israẹli:
3Àwọn ọmọ
Paroṣi jẹ́ ẹgbàá ó-lé-méjìléláàádọ́sàn-án (2,172)
4Ṣefatia jẹ́ òjì-dín-nírínwó ó-lé-méjìlá (372)
5Arah jẹ́ ẹgbẹ̀rin ó-dínmẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (775)
6Pahati-Moabu (láti ipasẹ̀ àwọn ọmọ Jeṣua àti Joabu) jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì àti ẹgbẹ̀rìn-lé-méjìlá (2,812)
7Elamu jẹ́ àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀fà ó-lé-mẹ́rin (1,254)
8Sattu jẹ́ ọ̀tà-dínlẹ́gbẹ̀rún ó-lé-márùn-ún (945)
9Sakkai jẹ́ òjì-dínlẹ́gbẹ̀rin (760)
10Bani jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó-lé-méjì (642)
11Bebai jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó-lé-mẹ́tàlélógún (623)
12Asgadi jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó-lé-méjìlélógún (1,222)
13Adonikami jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó-lé-mẹ́fà (666)
14Bigfai jẹ́ ẹgbàá ó-lé-mẹ́rìn-dínlọ́gọ́ta (2,056)
15Adini jẹ́ aádọ́ta-lé-ní-irínwó ó-lé-mẹ́rin (454)
16Ateri (nípasẹ̀ Hesekiah) jẹ́ méjì-dínlọ́gọ́rin (78)
17Besai jẹ́ ọrùn-dínnírínwó ó-lé-mẹ́ta (323)
18Jora jẹ́ méjìléláàdọ́fà (112)
19Haṣumu jẹ́ igba ó-lé-mẹ́tàlélógún (223)
20Gibbari jẹ́ márùn-dínlọ́gọ́rùn (95)
21Àwọn ọmọ
Bẹtilẹhẹmu jẹ́ mẹ́tàlélọ́gọ́fà (123)
22Netofa jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́tà (56)
23Anatoti jẹ́ méjì-dínláàdóje (128)
24Asmafeti jẹ́ méjìlélógójì (42)
25Kiriati-Jearimu, Kefira àti Beeroti jẹ́ ọ̀tà-dínlẹ́gbẹ̀rin ó-lé-mẹ́ta (743)
26Rama àti Geba jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó-lé-mọ́kànlélógún (621)
27Mikmasi jẹ́ méjìlélọ́gọ́fà (122)
28Beteli àti Ai jẹ́ igba ó-lé-mẹ́tàlélógún (223)
29Nebo jẹ́ méjìléláàdọ́ta (52)
30Magbiṣi jẹ́ mẹ́rìn-dínlọ́gọ́jọ (156)
31Elamu mìíràn jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó-lé-mẹ́rìnléláàdọ́ta (1,254)
32Harimu jẹ́ ọ̀rìn-dínnírínwó (320)
33Lodi, Hadidi àti Ono jẹ́ ọ̀rìn-dínlẹ́gbẹ̀rin ó-lé-márùn-ún (725)
34Jeriko jẹ́ ọ̀tà-dínnírínwó ó-lé-márùn-ún (345)
35Senaa jẹ́ egbèjì-dínlógún ó-lé-ọgbọ̀n (3,630)
36Àwọn àlùfáà:
Àwọn ọmọ
Jedaiah (láti ipasẹ̀ ìdílé Jeṣua) jẹ́ ogún-dínlẹ́gbẹ̀rin ó-dínméje (973)
37Immeri jẹ́ àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀rún ó-lé-méjì (1,052)
38Paṣuri jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó-lé-mẹ́tà-dínláàdọ́ta (1,247)
39Harimu jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó-lé-mẹ́tà-dínlógún (1,017)
40Àwọn ọmọ Lefi:
Àwọn ọmọ
Jeṣua àti Kadmieli (ti ìdílé Hodafiah) jẹ́ mẹ́rìnléláàdọ́rin (74)
41Àwọn akọrin:
Àwọn ọmọ
Asafu jẹ́ méjì-dínláádóje (128)
42Àwọn aṣọ́bodè:
Àwọn ará
Ṣallumu, Ateri, Talmoni,
Akkubu, Hatita àti Ṣobai jẹ́ mọ́kàn-dínlógóje (139)
43Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili:
Àwọn ọmọ
Ṣiha, Hasufa, Tabboati,
44Kerosi, Ṣiaha, Padoni,
45Lebana, Hagaba, Akkubu,
46Hagabu, Ṣalmai, Hanani,
47Giddeli, Gahari, Reaiah,
48Resini, Nekoda, Gassamu,
49Ussa, Pasea, Besai,
50Asna, Mehuni, Nefisimu,
51Bakbu, Hakufa, Harhuri.
52Basluti, Mehida, Harṣa,
53Barkosi, Sisera, Tema,
54Nesia àti Hatifa.
55Àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni:
Àwọn ọmọ
Sotai, Sofereti, Peruda,
56Jaala, Darkoni, Giddeli,
57Ṣefatia, àwọn ọmọ Hattili,
Pokereti ti Haṣebaimu àti àwọn ọmọ Ami.
58Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni jẹ́ irínwó-ó-dínmẹ́jọ (392)
59Àwọn wọ̀nyí gòkè wá láti àwọn ìlú ti Teli-Mela, Teli-Harṣa, Kerubu, Addoni àti Immeri, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìdílé àwọn wá láti ara ìran ẹ̀yà Israẹli:
60Àwọn ọmọ
Delaiah, Tobiah àti Nekoda jẹ́ àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀ta ó-lé-méjì (652)
61Àti nínú àwọn ọmọ àwọn àlùfáà:
Àwọn ọmọ:
Hobaiah, Hakosi àti Barsillai (ọkùnrin tí ó fẹ́ ọmọbìnrin Barsillai ará Gileadi a sì ń fi orúkọ náà pè é).
62Àwọn wọ̀nyí wá ìwé ìrántí ìdílé wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni a kò kà wọ́n kún ara àlùfáà nítorí, a kà wọ́n sí aláìmọ́. 63Baálẹ̀ pa á láṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ nínú oúnjẹ mímọ́ jùlọ títí tí àlùfáà kan yóò fi ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú Urimu àti Tumimu.
64Gbogbo ìjọ ènìyàn náà jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlélógún ó-lé-òjìdínnírínwó (42,360). 65Yàtọ̀ sí ẹgbẹ̀rìn-dínlẹ́gbàárin-ó-dín mẹ́tàlélọ́gọ́ta (7,337) ìránṣẹ́ ọkùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin; wọ́n ní igba (200) akọrin ọkùnrin àti obìnrin. 66Wọ́n ní ọ̀tà-dínlẹ́gbẹ̀rin ó-dínmẹ́rin ẹṣin (736); ìbáaka òjìlélúgba ó-lé-márùn-ún (245) 67Ràkunmí jẹ́ irínwó ó-lé-márùn-dínlógójì; (435) àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbẹ̀rìnlélọ́gbọ̀n ó-dínọgọ́rin (6,720).
68Ní ìgbà tí wọ́n dé ilé Olúwa ní Jerusalẹmu, díẹ̀ nínú àwọn olórí àwọn ìdílé fi ọrẹ àtinúwá sílẹ̀ fún ṣíṣe àtúnkọ́ ilé Ọlọ́run ní ààyè rẹ̀. 69Gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, wọ́n fún ilé ìṣúra fún iṣẹ́ yìí ní ọ̀kẹ́ mẹ́ta (61,000) ìwọ̀n dariki wúrà, ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n fàdákà (5,000) àti ọgọ́rùn-ún (100) ẹ̀wù àlùfáà.
70Àwọn àlùfáà, àwọn ará Lefi, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́bodè àti àwọn ìránṣẹ́ ilé Olúwa ṣe àtìpó sínú àwọn ìlú wọn, pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn, àti ìyókù àwọn ọmọ Israẹli ṣe àtìpó sínú ìlú u wọn.
Currently Selected:
Esra 2: YCB
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.