Gẹnẹsisi 28
28
1Nítorí náà Isaaki pe Jakọbu, ó sì súre fún un, ó sì pàṣẹ fún un pé; “Ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ aya láàrín àwọn ọmọbìnrin Kenaani. 2Dípò bẹ́ẹ̀ lọ sí Padani-Aramu, sí ilé Betueli, baba ìyá rẹ, kí ìwọ kí ó sì fẹ́ aya fún ara rẹ nínú àwọn ọmọbìnrin Labani arákùnrin ìyá rẹ. 3Kí Ọlọ́run Olódùmarè (Eli-Ṣaddai) kí ó bùkún fún ọ, kí ó sì mú ọ bí sí i, kí ó sì mú ọ pọ̀ sí i ní iye títí tí ìwọ yóò di àgbájọ àwọn ènìyàn. 4 Kí Ọlọ́run kí ó fún ìwọ àti irú-ọmọ rẹ ní ìre tí ó sú fún Abrahamu, kí ìwọ kí ó le gba ilẹ̀ níbi tí a ti ń ṣe àtìpó yìí, ilẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi fún Abrahamu.” 5Bẹ́ẹ̀ ni Isaaki sì rán Jakọbu lọ. Ó sì lọ sí Padani-Aramu, lọ́dọ̀ Labani ọmọ Betueli, ará Aramu, tí í ṣe arákùnrin Rebeka ìyá Jakọbu àti Esau.
6Nígbà tí Esau gbọ́ pé, Isaaki ti súre fún Jakọbu, ó sì ti rán Jakọbu lọ sí Padani-Aramu láti fẹ́ aya níbẹ̀ àti pé nígbà tí ó súre fún un, ó kìlọ̀ fun un pé, kò gbọdọ̀ fẹ́ nínú àwọn ọmọbìnrin Kenaani 7àti pé, Jakọbu ti gbọ́rọ̀ sí ìyá àti baba rẹ̀ lẹ́nu, ó sì ti lọ sí Padani-Aramu. 8Nígbà náà ni Esau mọ bí Isaaki baba rẹ ti kórìíra àwọn ọmọbìnrin Kenaani tó. 9Nítorí náà Esau tọ Iṣmaeli lọ, ó sì fẹ́ Mahalati, arábìnrin Nebaioti, ọmọbìnrin Iṣmaeli tí í ṣe ọmọ Abrahamu. Ó fẹ́ ẹ, kún àwọn ìyàwó tí ó ti ní tẹ́lẹ̀.
Àlá Jakọbu ní Beteli
10Jakọbu kúrò ní Beerṣeba, ó sì kọrí sí ìlú Harani. 11Nígbà tí ó dé ibìkan, ó dúró ní òru náà nítorí tí ilẹ̀ ti ń ṣú, ó sì gbé òkúta kan ó fi ṣe ìrọ̀rí, ó sì sùn. 12 Ó sì lá àlá pé, a gbé àkàsọ̀ kan dúró ti ó fi ìdí lélẹ̀, orí rẹ̀ sì kan ọ̀run, àwọn angẹli Ọlọ́run sì ń gòkè, wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀. 13 Olúwa sì dúró lókè rẹ̀, ó sì wí pé, “Èmi ni Olúwa, Ọlọ́run baba rẹ Abrahamu àti Ọlọ́run Isaaki, ìwọ àti ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ tí ìwọ dùbúlẹ̀ sórí rẹ̀ yìí fún. 14 Ìran rẹ yóò pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, ìwọ yóò sì tànkálẹ̀ dé ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn, àti dé gúúsù àti àríwá. A ó sì bùkún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé nípasẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ. 15Èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì pa ọ mọ́ ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ, èmi yóò sì mú ọ padà wá sí ilẹ̀ yìí ní àlàáfíà. Èmi kì yóò fi ọ sílẹ̀ ní ìgbà kan, títí tí èmi yóò fi mú gbogbo ìlérí mi ṣẹ.”
16Nígbà tí Jakọbu jí lójú oorun rẹ̀, ó rò nínú ara rẹ̀ pé, “Dájúdájú Olúwa ń bẹ ní ìhín yìí, èmi kò sì mọ̀.” 17Ẹ̀rù sì bà á, ó sì wí pé, “Ìhín yìí ní ẹ̀rù gidigidi; ibí kì í ṣe ibòmíràn bí kò ṣe ilé Ọlọ́run, àní ẹnu ibodè ọ̀run nìyìí.”
18Jakọbu sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì gbé òkúta tí ó fi ṣe ìrọ̀rí lélẹ̀ bí ọ̀wọ́n, ó sì da òróró si lórí. 19Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Beteli (Ilé Ọlọ́run) bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú náà ń jẹ́ Lusi tẹ́lẹ̀ rí.
20Jakọbu sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ níbẹ̀ pé, “Bí Ọlọ́run yóò bá wà pẹ̀lú mi, tí yóò sì pa mí mọ́ ní ìrìnàjò mi tí mo ń lọ, tí yóò sì fún mi ní oúnjẹ láti jẹ àti aṣọ láti wọ̀, 21tí mo sì padà sílé baba mi ní àlàáfíà, nígbà náà Olúwa ni yóò jẹ́ Ọlọ́run mi, 22Òkúta yìí tí mo gbé kalẹ̀ bí ọ̀wọ́n yóò jẹ́ ilé Ọlọ́run, nínú gbogbo ohun tí ìwọ ó fi fún mi, èmi yóò sì fi ìdámẹ́wàá rẹ̀ fún ọ.”
Currently Selected:
Gẹnẹsisi 28: YCB
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.