Jobu 9
9
Jobu Fún Bilidadi lésì Nípa Ẹ̀kọ́ àti ẹ̀rí Ìdájọ́ Ọlọ́run
1Jobu sì dáhùn ó sì wí pé:
2“Èmi mọ̀ pe bẹ́ẹ̀ ni ní òtítọ́.
Báwo ní ènìyàn yóò ha ti ṣe jẹ́ aláre níwájú Ọlọ́run?
3Bí ó bá ṣe pé yóò bá a jà,
òun kì yóò lè dalóhùn kan nínú ẹgbẹ̀rún ọ̀rọ̀.
4Ọlọ́gbọ́n nínú àwọn alágbára ní ipa ní Òun;
ta ni ó ṣe agídí sí i tí ó sì gbé fún rí?
5Ẹni tí ó sí òkè nídìí tí wọn kò sì mọ́:
tí ó taari wọn ṣubú ní ìbínú rẹ̀.
6Tí ó mi ilẹ̀ ayé tìtì kúrò ní ipò rẹ̀,
ọwọ́n rẹ̀ sì mì tìtì.
7Ó pàṣẹ fún oòrùn kò sì le è ràn,
kí ó sì dí ìmọ́lẹ̀ ìràwọ̀ mọ́.
8Òun nìkan ṣoṣo ni ó ta ojú ọ̀run,
ti ó sì ń rìn lórí ìgbì Òkun.
9Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Beari, Orioni
àti Pleiadesi àti ìràwọ̀ púpọ̀ ti gúúsù.
10Ẹni tí ń ṣe ohun tí ó tóbi jù àwárí lọ,
àní ohun ìyanu láìní iye.
11Kíyèsi i, ó ń kọjá lọ ní ẹ̀bá ọ̀dọ̀ mi, èmi kò sì rí i,
ó sì kọjá síwájú, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò rí ojú rẹ̀.
12Kíyèsi i, ó já a gbà lọ, ta ni ó lè fà á padà?
Ta ni yóò bi í pé kí ni ìwọ ń ṣe nì?
13Ọlọ́run kò ní fa ìbínú rẹ̀ sẹ́yìn,
àwọn onírànlọ́wọ́ ti Rahabu a sì tẹríba lábẹ́ rẹ̀.
14“Kí ní ṣe tí èmi ti n o fi ba ṣàròyé?
Tí èmi yóò fi ma ṣe àwáwí?
15Bí ó tilẹ̀ ṣe pé mo ṣe aláìlẹ́bi, èmi kò gbọdọ̀ dá a lóhùn;
ṣùgbọ́n èmi ó gbàdúrà fún àánú.
16Bí èmi bá sì ké pè é, tí Òun sì dá mi lóhùn,
èmi kì yóò sì gbàgbọ́ pé, Òun ti fetí sí ohùn mi.
17Nítorí pé òun yóò lọ̀ mí lúúlúú pẹ̀lú ìjì ńlá,
ó sọ ọgbẹ́ mi di púpọ̀ láìnídìí.
18Òun kì yóò jẹ́ kí èmi kí ó rí ẹ̀mí mi,
ṣùgbọ́n ó mú ohun kíkorò kún un fún mi.
19Bí mo bá sọ ti agbára, wò ó!
Alágbára ni, tàbí ní ti ìdájọ́, ta ni yóò dá àkókò fún mi láti rò?
20Bí mo tilẹ̀ dá ara mi láre, ẹnu ara mi yóò dá mi lẹ́bi;
bí mo wí pé olódodo ni èmi yóò sì fi mí hàn ní ẹni ẹ̀bi.
21“Olóòótọ́ ni mo ṣe,
síbẹ̀ èmi kò kíyèsi ara mi,
ayé mi ní èmi ìbá máa gàn.
22Ohùn kan náà ni, nítorí náà ni èmi ṣe sọ:
‘Òun a pa ẹni òtítọ́ àti ènìyàn búburú pẹ̀lú.’
23Bí ìjàǹbá bá pa ni lójijì,
yóò rẹ́rìn-ín nínú ìdààmú aláìṣẹ̀.
24Nígbà tí a bá fi ayé lé ọwọ́ ènìyàn búburú;
ó sì bo àwọn onídàájọ́ rẹ̀ lójú;
bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ ǹjẹ́ ta ni?
25“Ǹjẹ́ nísinsin yìí ọjọ́ mi yára ju oníṣẹ́ lọ,
wọ́n fò lọ, wọn kò rí ayọ̀.
26Wọ́n kọjá lọ bí ọkọ̀ eèsún papirusi tí ń sáré lọ;
bí idì tí ń yára si ohùn ọdẹ.
27Bí èmi bá wí pé, ‘Èmi ó gbàgbé arò ìbìnújẹ́ mi,
èmi ó fi ọkàn lélẹ̀, èmi ó sì rẹ ara mi lẹ́kún.’
28Ẹ̀rù ìbànújẹ́ mi gbogbo bà mí,
èmi mọ̀ pé ìwọ kì yóò mú mi bí aláìṣẹ̀.
29Bí ó bá ṣe pé ènìyàn búburú ni èmi,
ǹjẹ́ kí ni èmi ń ṣe làálàá lásán sí?
30Bí mo tilẹ̀ fi ọṣẹ dídì wẹ ara mi,
tí mo fi omi aró wẹ ọwọ́ mi mọ́,
31síbẹ̀ ìwọ ó gbé mi wọ inú ihò
ọ̀gọ̀dọ̀ aṣọ ara mi yóò sọ mi di ìríra.
32“Nítorí Òun kì í ṣe ènìyàn bí èmi,
tí èmi ó fi dá a lóhùn tí àwa o fi pàdé ní ìdájọ́.
33Bẹ́ẹ̀ ni kò sí alátúnṣe kan ní agbede-méjì wa
tí ìbá fi ọwọ́ rẹ̀ lé àwa méjèèjì lára.
34Kí ẹnìkan sá à mú ọ̀pá Ọlọ́run kúrò lára mi,
kí ìbẹ̀rù rẹ̀ kí ó má sì ṣe dáyà fò mí
35Nígbà náà ni èmi ìbá sọ̀rọ̀, èmi kì bá sì bẹ̀rù rẹ̀;
ṣùgbọ́n bí ó tí dúró tì mí, kò ri bẹ́ẹ̀ fún mi.
Currently Selected:
Jobu 9: YCB
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.