YouVersion Logo
Search Icon

Luku Ìfáàrà

Ìfáàrà
Luku jẹ́ oníṣègùn àti alábáṣiṣẹ́pọ̀ aposteli Paulu nínú ìrìnàjò rẹ̀ fún iṣẹ́ ìhìnrere. Ó kọ ìhìnrere rẹ̀ fún ọ̀làjú Giriki kan ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tiofilu (1.3) láti fi ìtàn Jesu hàn bí onínúrere ènìyàn. Nítorí ìdí èyí, Luku fi ara balẹ̀ wo àwọn ẹ̀rí fínní fínní láti fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ní ọjọ́ bí wọ́n ṣe wáyé. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àkọsílẹ̀ ọjọ́ ìbí Jesu, tí ó kún tí a kò sì lè rí àkọsílẹ̀ tí ó kún ju bẹ́ẹ̀ lọ ní ibòmíràn. Ó ṣàpèjúwe iṣẹ́ ìhìnrere Jesu ní Galili àti ìrìnàjò rẹ̀ sí Jerusalẹmu. Lẹ́yìn ikú àti àjíǹde Jesu, a fi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sílẹ̀ nínú ayọ̀ pẹ̀lú ìrètí agbára ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run láti ọ̀run wá tí yóò kún inú ọkàn wọn.
Nígbà tí Matiu fi Jesu hàn bí olùgbàlà Júù, tí Marku sì fi Jesu hàn bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run, Luku ṣàpèjúwe Jesu bí ènìyàn Ọlọ́run tí a lè sọ nípa ìran rẹ̀ títí kan Adamu (3.23-38). Luku fi Jesu hàn bí ọkùnrin tí ó tóbi jùlọ nínú ìtàn ayé. Ó jẹ́ ẹni ńlá nítorí ẹ̀kọ́ rẹ̀ àti àwọn ohun tí ó ń ṣe, ikú tí ó kú àti nítorí àjíǹde rẹ̀. Nítorí àwọn ìdí yìí ó yẹ kí a gbà á bí Olúwa wa.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìbí Jesu àti ìgbà èwe rẹ̀ 1.1–2.52.
ii. Ìtẹ̀bọmi Jesu àti ìdánwò rẹ̀ 3.1–4.13.
iii. ìhìnrere Jesu ní Galili 4.14–9.50.
iv. Ìrìnàjò Jesu sí Jerusalẹmu 9.51–19.27.
v. ìhìnrere Jesu ní Jerusalẹmu 19.28–20.47.
vi. Àsọtẹ́lẹ̀ Jesu nípa àwọn nǹkan tí ń bọ̀ 21.1-38.
vii. Ikú àti àjíǹde Jesu 22.1–24.53.

Currently Selected:

Luku Ìfáàrà: YCB

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in