YouVersion Logo
Search Icon

Filipi Ìfáàrà

Ìfáàrà
Paulu kọ lẹ́tà yìí láti inú ẹ̀wọ̀n ní Romu sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n ní ìlú Filipi, fún ẹ̀bùn owó tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí i láti fi gbọ́ ohun tó ń jẹ ẹ́ ní yà. Ó bẹ̀rẹ̀ nípa ṣíṣe àlàyé bí òun ṣe gba ẹ̀rí wọn jẹ́, lẹ́yìn náà ni ó wá ṣàpèjúwe àwọn ìṣòro tó dojúkọ ní Romu. Kò mọ̀ bóyá òun yóò kú tàbí òun kò ní kú, ṣùgbọ́n bí ikú bá dé, yóò láyọ̀ ní iwájú Kristi. Bí òun bá sì wà láààyè, òun yóò fi gbogbo agbára ṣiṣẹ́ fún Ọlọ́run. Ó fi Kristi ṣe àpẹẹrẹ ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tí ó yẹ ní àwòkọ́ṣe fún àwọn ará Filipi, ìkọ́ni ẹ̀tàn gbọdọ̀ di ìkọ̀sílẹ̀. Gbogbo àwọn onígbàgbọ́ ni a bá wí láti ní èrò gíga fún ara wọn nítorí pé Ọlọ́run yóò pèsè gbogbo ohun tí ènìyàn ń fẹ́ ní ayé.
Nínú lẹ́tà tí Paulu kọ sí àwọn ènìyàn rẹ̀ yìí ni a ti rí ọ̀rọ̀ inú dídùn láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. Bí ènìyàn bá wà láààyè yóò ní inú dídùn nítorí Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ̀, Kristi kú fún un, àti pé ohun gbogbo ni Ọlọ́run fi tẹ́ ẹ lọ́rùn nínú ayé. Bí ènìyàn bá sì kú, yóò ní inú dídùn pé òun yóò wà ní iwájú ìtẹ́ Ọlọ́run títí ayérayé. Èyí kò sọ pé onígbàgbọ́ kò ní ní ìṣòro. Ní ìwọ̀n ìgbà tí Jesu ti lè fi ara rẹ̀ da ìyà orí àgbélébùú, ó yẹ kí a lè tẹ̀lé ìlànà yìí, kí a fi ara wa fún Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n ọmọ ìjọba Ọlọ́run ni a jẹ́, ó sì yẹ kí èrò yìí wà ní iwájú wa ni ìgbà gbogbo.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìkíni 1.1-2.
ii. Ìdúpẹ́ àti àdúrà fún àwọn ará Filipi 1.3-11.
iii. Paulu àti àwọn ìṣòro rẹ̀ ní Romu 1.2-26.
iv. Ọ̀rọ̀ ìyànjú 1.27–2.18.
v. Àwọn alábáṣiṣẹ́ Paulu nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ 2.19-20.
vi. Ìkìlọ̀ nípa àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ òdì 3.1–4.1.
vii. Ìdúpẹ́ àti ìdágbére 4.2-23.

Currently Selected:

Filipi Ìfáàrà: YCB

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in