YouVersion Logo
Search Icon

Saamu 14

14
Saamu 14
FĂșn adarĂ­ orin. Ti Dafidi.
1 AáčŁiwĂšrĂš wĂ­ nĂ­nĂș ọkĂ n ráșč̀ pĂ©,
“Ko sĂ­ Ọlọ́run.”
Wọ́n dĂ­bĂ jáșč́, iáčŁáșč́ wọn sĂŹ burĂș;
kĂČ sĂ­ áșčnĂŹkan tĂ­ yĂłĂČ áčŁe rere.
2 OlĂșwa sĂŹ bojĂș woláșč̀ lĂĄti ọ̀run wĂĄ
lĂłrĂ­ Ă wọn ọmọ ĂšnĂŹyĂ n
bĂłyĂĄ Ăł le rĂ­ áșčni tĂ­ ĂČye yĂ©,
áșčnikáșč́ni tĂł Ƅ wĂĄ Ọlọ́run.
3Gbogbo wọn sĂŹ ti yĂ­padĂ , gbogbo wọn sĂŹ ti dĂ­bĂ jáșč́;
kĂČ sĂŹ áčŁĂ­ áșčni tĂ­ Ăł Ƅ áčŁe rere,
kĂČ sĂ­ áșčnĂŹkan.
4Çžjáșč́ olĂčáčŁe bĂșburĂș kĂČ ha nĂ­ ĂŹmọ̀?
Àwọn tĂ­ Ăł Ƅ pa ĂšnĂŹyĂ n mi jáșč bĂ­ áșčnĂ­ jáșčun;
wọn kĂČ sĂŹ kĂ© pe OlĂșwa?
5Wọ́n wĂ  nĂ­báșč̀, tĂ­ a bĂČ mọ́láșč̀ páșč̀lĂș áșč̀rĂč,
nĂ­torĂ­ Ọlọ́run wĂ  nĂ­ Ă wĂčjọ Ă wọn olĂłdodo.
6áșžÌ€yin olĂčáčŁe bĂșburĂș da ĂšrĂČ Ă wọn tĂĄlĂĄkĂ  rĂș,
áčŁĂčgbọ́n OlĂșwa ni Ă Ă bĂČ wọn.
7ÌgbĂ lĂ  Ă wọn Israáșčli yĂłĂČ ti Sioni wĂĄ!
NĂ­gbĂ  tĂ­ OlĂșwa bĂĄ mĂș ĂŹkĂłlọ Ă wọn ĂšnĂŹyĂ n ráșč̀ padĂ ,
jáșč́ kĂ­ Jakọbu kĂ­ Ăł yọ̀, kĂ­ inĂș Israáșčli kĂ­ Ăł dĂčn!

Currently Selected:

Saamu 14: YCB

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

Videos for Saamu 14