JOHANU 3
3
Jesu ati Nikodemu
1Ọkunrin kan wà ninu àwọn Farisi tí ń jẹ́ Nikodemu. Ó jẹ́ ọ̀kan ninu ìgbìmọ̀ àwọn Juu. 2Ọkunrin yìí fi òru bojú lọ sọ́dọ̀ Jesu. Ó wí fún un pé, “Rabi, a mọ̀ pé olùkọ́ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá ni ọ́, nítorí kò sí ẹni tí ó lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ò ń ṣe wọnyi àfi ẹni tí Ọlọrun bá wà pẹlu rẹ̀.”
3Jesu bá gba ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu, ó ní, “Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, ẹnikẹ́ni tí a kò bá tún bí láti ọ̀run kò lè rí ìjọba Ọlọrun.”
4Nikodemu bi í pé, “Báwo ni a ti ṣe lè tún ẹni tí ó ti di àgbàlagbà bí? Kò sá tún lè pada wọ inú ìyá rẹ̀ lẹẹkeji kí á wá tún un bí!”
5Jesu dáhùn pé, “Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, ẹnikẹ́ni tí a kò bá fi omi ati Ẹ̀mí bí, kò lè wọ ìjọba Ọlọrun. 6Ẹni tí a bá bí ní bíbí ti ẹran-ara, ẹran-ara ni. Ẹni tí a bá bí ní bíbí ti Ẹ̀mí, ẹ̀mí ni. 7Má ṣe jẹ́ kí ẹnu yà ọ́ nítorí mo wí fún ọ pé: dandan ni kí á tún yín bí. 8Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ sí ibikíbi tí ó bá wù ú; ò ń gbọ́ ìró rẹ̀, ṣugbọn o kò mọ ibi tí ó ti ń bọ̀, tabi ibi tí ó ń lọ. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí pẹlu gbogbo ẹni tí a bí ní bíbí ti Ẹ̀mí.”
9Nikodemu wá bi í pé, “Báwo ni nǹkan wọnyi ti ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?”
10Jesu ní, “Mo ṣebí olùkọ́ni olókìkí ní Israẹli ni ọ́, sibẹ o kò mọ nǹkan wọnyi? 11Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, à ń sọ ohun tí a mọ̀, a sì ń jẹ́rìí ohun tí a rí, ṣugbọn ẹ̀yin kò gba ẹ̀rí wa. 12Bí mo bá sọ nǹkan ti ayé fun yín tí ẹ kò gbàgbọ́, ẹ óo ti ṣe gbàgbọ́ bí mo bá sọ nǹkan ti ọ̀run fun yín?#Ọgb 9:16-17 13Kò sí ẹni tí ó tíì gòkè lọ sí ọ̀run rí àfi ẹni tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, èyí ni Ọmọ-Eniyan.”#Bar 3:39
14Bí Mose ti gbé ejò sókè ní aṣálẹ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni a óo gbé Ọmọ-Eniyan sókè,#Nọm 21:9; Ọgb 16:5-7 15kí gbogbo ẹni tí ó bá gbà á gbọ́ lè ní ìyè ainipẹkun. 16Nítorí Ọlọrun fẹ́ aráyé tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kanṣoṣo fúnni, pé kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ má baà ṣègbé, ṣugbọn kí ó lè ní ìyè ainipẹkun. 17Nítorí Ọlọrun kò rán Ọmọ rẹ̀ wá sí ayé láti dá aráyé lẹ́bi bíkòṣe pé kí aráyé lè ti ipasẹ̀ rẹ̀ ní ìgbàlà.
18A kò ní dá ẹni tí ó bá gbà á gbọ́ lẹ́bi. Ṣugbọn a ti dá ẹni tí kò bá gbà á gbọ́ lẹ́bi ná, nítorí kò gba orúkọ Ọmọ bíbí Ọlọrun kanṣoṣo gbọ́. 19Ìdálẹ́bi náà ni pé ìmọ́lẹ̀ ti dé sinu ayé, ṣugbọn aráyé fẹ́ràn òkùnkùn ju ìmọ́lẹ̀ lọ, nítorí iṣẹ́ wọn burú. 20Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe burúkú a máa kórìíra ìmọ́lẹ̀; kò jẹ́ wá sí ibi tí ìmọ́lẹ̀ bá wà, kí eniyan má baà bá a wí nítorí iṣẹ́ rẹ̀. 21Ṣugbọn ẹni tí ó bá ń hùwà òtítọ́ á máa wá sí ibi ìmọ́lẹ̀, kí iṣẹ́ rẹ̀ lè hàn pé agbára Ọlọrun ni ó fi ń ṣe wọ́n.
Johanu Tún Sọ̀rọ̀ nípa Jesu
22Lẹ́yìn èyí, Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Judia, wọ́n ń gbé ibẹ̀, ó bá ń ṣe ìrìbọmi fún àwọn eniyan. 23Johanu náà ń ṣe ìrìbọmi fún àwọn eniyan ní Anoni lẹ́bàá Salẹmu, nítorí omi pọ̀ níbẹ̀. Àwọn eniyan ń wọ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì ń ṣe ìrìbọmi fún wọn.#Mat 14:3 Mak 6:17; Luk 3:19-20 24(Wọn kò ì tíì ju Johanu sẹ́wọ̀n ní àkókò yìí.)
25Ọ̀rọ̀ nípa ìwẹ̀mọ́ di àríyànjiyàn láàrin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ati ọkunrin Juu kan.#3:25 Àwọn Bibeli àtijọ́ mìíràn sọ pé ati àwọn Juu dípò ati ọkunrin Juu kan. 26Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà bá lọ sọ́dọ̀ Johanu, wọ́n wí fún un pé, “Olùkọ́ni, ọkunrin tí ó wà pẹlu rẹ ní òdìkejì odò Jọdani, tí o jẹ́rìí nípa rẹ̀, ń ṣe ìrìbọmi, gbogbo eniyan sì ń tọ̀ ọ́ lọ.”
27Johanu fèsì pé, “Kò sí ẹni tí ó lè rí ohunkohun gbà àfi ohun tí Ọlọrun bá fún un. 28Ẹ̀yin fúnra yín jẹ́rìí mi pé mo sọ pé, ‘Èmi kì í ṣe Kristi náà, ṣugbọn èmi ni a rán ṣiwaju rẹ̀.’#Joh 1:20 29Ọkọ iyawo ni ó ni iyawo, ṣugbọn ẹni tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ ọkọ iyawo, tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀, tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, á máa láyọ̀ láti gbọ́ ohùn ọkọ iyawo. Nítorí náà ayọ̀ mi yìí di ayọ̀ kíkún. 30Dandan ni pé kí òun túbọ̀ jẹ́ pataki sí i, ṣugbọn kí jíjẹ́ pataki tèmi máa dínkù.”
Ipò Ẹni Tí Ó Wá láti Ọ̀run
31Ẹni tí ó wá láti òkè ju gbogbo eniyan lọ. Ẹni tí ó jẹ́ ti ayé, ti ayé ni, ọ̀rọ̀ ti ayé ni ó sì ń sọ. Ẹni tí ó wá láti ọ̀run ju gbogbo eniyan lọ. 32Ohun tí ó rí, tí ó sì gbọ́ ni ó ń jẹ́rìí sí, ṣugbọn ẹ̀yin kò gba ẹ̀rí rẹ̀. 33Ẹni tí ó bá gba ẹ̀rí rẹ̀ gbà dájúdájú pé olóòótọ́ ni Ọlọrun. 34Nítorí pé ẹni tí Ọlọrun rán wá ń sọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Nítorí pé Ọlọrun fún un ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ẹ̀mí rẹ̀. 35Baba fẹ́ràn Ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo sí ìkáwọ́ rẹ̀.#Mat 11:27; Luk 10:22 36Ẹni tí ó bá gba Ọmọ gbọ́ ní ìyè ainipẹkun. Ṣugbọn ẹni tí ó bá ṣàìgbọràn sí Ọmọ kò ní rí ìyè, ṣugbọn ibinu Ọlọrun wà lórí rẹ̀.
Bible Society of Nigeria © 1900/2010