1
JẸNẸSISI 3:6
Yoruba Bible
Nígbà tí obinrin yìí ṣe akiyesi pé èso igi náà dára fún jíjẹ ati pé ó dùn ún wò, ó sì wòye bí yóo ti dára tó láti jẹ́ ọlọ́gbọ́n, ó mú ninu èso igi náà, ó jẹ ẹ́. Lẹ́yìn náà, ó fún ọkọ rẹ̀, ọkọ rẹ̀ náà sì jẹ ẹ́.
Kokisana
Luka JẸNẸSISI 3:6
2
JẸNẸSISI 3:1
Ejò jẹ́ alárèékérekè ju gbogbo ẹranko tí OLUWA Ọlọrun dá lọ. Ejò bi obinrin náà pé, “Ngbọ́! Ṣé nítòótọ́ ni Ọlọrun sọ pé ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ninu èso àwọn igi ọgbà yìí?”
Luka JẸNẸSISI 3:1
3
JẸNẸSISI 3:15
N óo dá ọ̀tá sí ààrin ìwọ ati obinrin náà, ati sí ààrin atọmọdọmọ rẹ ati atọmọdọmọ rẹ̀. Wọn óo máa fọ́ ọ lórí, ìwọ náà óo sì máa bù wọ́n ní gìgísẹ̀ jẹ.”
Luka JẸNẸSISI 3:15
4
JẸNẸSISI 3:16
Lẹ́yìn náà Ọlọrun wí fún obinrin náà pé, “N óo fi kún ìnira rẹ nígbà tí o bá lóyún, ninu ìrora ni o óo máa bímọ. Sibẹsibẹ, lọ́dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yóo máa fà sí, òun ni yóo sì máa ṣe olórí rẹ.”
Luka JẸNẸSISI 3:16
5
JẸNẸSISI 3:19
Iṣẹ́ àṣelàágùn ni o óo máa ṣe, kí o tó rí oúnjẹ jẹ, títí tí o óo fi pada sí ilẹ̀, nítorí inú rẹ̀ ni a ti mú ọ wá. Erùpẹ̀ ni ọ́, o óo sì pada di erùpẹ̀.”
Luka JẸNẸSISI 3:19
6
JẸNẸSISI 3:17
Ó sọ fún Adamu, pé, “Nítorí pé o gba ohun tí aya rẹ wí fún ọ, o sì jẹ ninu èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé o kò gbọdọ̀ jẹ, mo fi ilẹ̀ gégùn-ún títí lae nítorí rẹ. Pẹlu ìnira ni o óo máa mú oúnjẹ jáde láti inú ilẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.
Luka JẸNẸSISI 3:17
7
JẸNẸSISI 3:11
Ọlọrun bi í pé, “Ta ló sọ fún ọ pé ìhòòhò ni o wà? Àbí o ti jẹ ninu èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé o kò gbọdọ̀ jẹ?”
Luka JẸNẸSISI 3:11
8
JẸNẸSISI 3:24
Ó lé e jáde, ó sì fi Kerubu kan sí ìhà ìlà oòrùn ọgbà náà láti máa ṣọ́ ọ̀nà tí ó lọ sí ibi igi ìyè náà, pẹlu idà oníná tí ń jò bùlà bùlà, tí ó sì ń yí síhìn-ín sọ́hùn-ún.
Luka JẸNẸSISI 3:24
9
JẸNẸSISI 3:20
Adamu sọ iyawo rẹ̀ ní Efa, nítorí pé òun ni ìyá gbogbo eniyan.
Luka JẸNẸSISI 3:20
Ndako
Biblia
Bibongiseli
Bavideo