JẸNẸSISI 4

4
Kaini ati Abeli
1Nígbà tí ó yá, Adamu bá Efa, aya rẹ̀, lòpọ̀, ó lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. Ó ní, “Pẹlu ìrànlọ́wọ́ OLUWA, mo ní ọmọkunrin kan,” ó sọ ọmọ náà ní Kaini. 2Lẹ́yìn náà, ó bí ọmọkunrin mìíràn, ó sọ ọ́ ní Abeli. Iṣẹ́ darandaran ni Abeli ń ṣe, Kaini sì jẹ́ àgbẹ̀. 3Nígbà tí ó yá, Kaini mú ninu èso oko rẹ̀, ó fi rúbọ sí OLUWA. 4Abeli náà mú àkọ́bí ọ̀kan ninu àwọn aguntan rẹ̀, ó pa á, ó sì fi ibi tí ó lọ́ràá, tí ó dára jùlọ lára rẹ̀ rúbọ sí OLUWA. Inú OLUWA dùn sí Abeli, ó sì gba ẹbọ rẹ̀, 5ṣugbọn inú Ọlọrun kò dùn sí Kaini, kò sì gba ẹbọ rẹ̀. Inú bí Kaini, ó sì fa ojú ro. 6OLUWA bá bi Kaini, ó ní, “Kí ló dé tí ò ń bínú, tí o sì fa ojú ro? 7Bó bá jẹ́ pé o ṣe rere ni, ara rẹ ìbá yá gágá, ẹbọ rẹ yóo sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. Ṣugbọn nítorí pé ibi ni o ṣe, ẹ̀ṣẹ̀ ba dè ọ́ lẹ́nu ọ̀nà rẹ, ó fẹ́ jọba lé ọ lórí ṣugbọn tìrẹ ni láti ṣẹgun rẹ̀.”#Heb 11:4
8Nígbà tí ó yá, Kaini pe Abeli lọ sinu oko. Nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, Kaini dìde sí Abeli àbúrò rẹ̀, ó sì lù ú pa.#Ọgb 10:3; Mat 23:35; Luk 11:51; 1 Joh 3:12.
9OLUWA bá pe Kaini, ó bi í pé, “Níbo ni Abeli, àbúrò rẹ wà?” Ó dáhùn, ó ní, “N kò mọ̀. Ṣé èmi wá jẹ́ bí olùṣọ́ àbúrò mi ni?”
10OLUWA bá bi í pé “Kí ni o dánwò yìí? Láti inú ilẹ̀ ni ẹ̀jẹ̀ àbúrò rẹ ti ń kígbe pè mí.#Heb 12:24. 11Wò ó! mo fi ọ́ gégùn-ún lórí ilẹ̀ tí ó mu ẹ̀jẹ̀ arakunrin rẹ tí o pa. 12Láti òní lọ, nígbà tí o bá dá oko, ilẹ̀ kò ní fi gbogbo agbára rẹ̀ so èso fún ọ mọ́, ìsáǹsá ati alárìnká ni o óo sì jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé.”
13Kaini dá OLUWA lóhùn, ó ní, “Ìjìyà yìí ti pọ̀jù fún mi. 14O lé mi kúrò lórí ilẹ̀, ati kúrò níwájú rẹ, n óo sì di ìsáǹsá ati alárìnká lórí ilẹ̀ ayé, nígbà tí ó bá yá, ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi ni yóo pa mí.”
15Ṣugbọn OLUWA dáhùn, ó ní, “Rárá o! ẹnikẹ́ni tí ó bá pa Kaini, a óo gbẹ̀san lára rẹ̀ nígbà meje.” Nítorí náà OLUWA fi àmì sí ara Kaini kí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí i má baà pa á. 16Kaini bá kúrò níwájú OLUWA, ó lọ ń gbé ìlú tí ń jẹ́ Nodu.#4:16 Itumọ orúkọ ìlú yìí ni Ìrìn-kiri. Ó wà ní apá ìlà oòrùn ọgbà Edẹni.
Àwọn Ìran Kaini
17Kaini bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó lóyún, ó sì bí Enọku. Kaini lọ tẹ ìlú kan dó, ó sọ ìlú náà ní Enọku, tí í ṣe orúkọ ọmọ rẹ̀. 18Enọku bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Iradi. Iradi bí Mehujaeli, Mehujaeli bí Metuṣaeli, Metuṣaeli bí Lamẹki. 19Lamẹki fẹ́ iyawo meji, ọ̀kan ń jẹ́ Ada, ekeji ń jẹ́ Sila. 20Ada ni ó bí Jabali, tíí ṣe baba ńlá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé inú àgọ́, tí wọ́n sì ń sin ẹran ọ̀sìn. 21Orúkọ arakunrin rẹ̀ ni Jubali, òun ni baba ńlá gbogbo àwọn tí wọn ń lu hapu ati àwọn tí wọn ń fọn fèrè. 22Sila bí Tubali Kaini. Tubali Kaini yìí ni baba ńlá gbogbo àwọn alágbẹ̀dẹ tí ń rọ ohun èlò irin, ati idẹ. Arabinrin Tubali Kaini ni Naama.
23Nígbà tí ó yá Lamẹki pe àwọn aya rẹ̀, ó ní:
“Ada ati Sila, ẹ tẹ́tí sílẹ̀,
ẹ̀yin aya mi, ẹ gbọ́ mi ní àgbọ́yé:
Mo pa ọkunrin kan nítorí pé ó pa mí lára,
mo gba ẹ̀mí eniyan nítorí pé ó ṣá mi lọ́gbẹ́.
24Bí ẹ̀san ti Kaini bá jẹ́ ẹ̀mí eniyan meje,
ẹ̀san ti Lamẹki gbọdọ̀ jẹ́ aadọrin ẹ̀mí ó lé meje.”
Seti ati Enọṣi
25Adamu tún bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. Ó sọ ọ́ ní Seti, ó ní: “Ọlọrun tún fún mi ní ọmọ mìíràn dípò Abeli tí Kaini pa.” 26Seti bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Enọṣi. Nígbà náà ni àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí jọ́sìn ní orúkọ mímọ́ OLUWA.

Märk

Dela

Kopiera

None

Vill du ha dina höjdpunkter sparade på alla dina enheter? Registrera dig eller logga in