JẸNẸSISI 1
1
Ìtàn Bí A ṣe Dá Ayé
1Ní ìbẹ̀rẹ̀, nígbà tí Ọlọrun dá ọ̀run ati ayé, 2ayé rí júujùu, ó sì ṣófo. Ibú omi bo gbogbo ayé, gbogbo rẹ̀ ṣókùnkùn biribiri, ẹ̀mí Ọlọrun sì ń rábàbà lójú omi. 3Ọlọrun pàṣẹ pé kí ìmọ́lẹ̀ wà, ìmọ́lẹ̀ sì wà. #2 Makab 7:28; 2 Kọr 4:6 4Ọlọrun wò ó, ó rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì yà á kúrò lára òkùnkùn. 5Ó sọ ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán, ó sì sọ òkùnkùn ní òru. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kinni.
6Ọlọrun pàṣẹ pé kí awọsanma wà láàrin omi, kí ó pín omi sí ọ̀nà meji, kí ó sì jẹ́ ààlà láàrin omi tí ó wà lókè awọsanma náà ati èyí tí ó wà ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. 7Ọlọrun dá awọsanma, ó fi ya omi tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ kúrò lára èyí tí ó wà lókè rẹ̀, ó sì rí bẹ́ẹ̀. 8Ọlọrun sọ awọsanma náà ní ojú ọ̀run. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ keji. #2 Pet 3:5.
9Ọlọrun pàṣẹ pé kí omi tí ó wà lábẹ́ ọ̀run wọ́jọ pọ̀ sí ojú kan, kí ìyàngbẹ ilẹ̀ lè farahàn, ó sì rí bẹ́ẹ̀. 10Ó sọ ìyàngbẹ ilẹ̀ náà ní ilẹ̀, ó sì sọ omi tí ó wọ́jọ pọ̀ ní òkun. Ó wò ó, ó sì rí i pé ó dára. 11Ọlọrun pàṣẹ pé kí ilẹ̀ hu koríko jáde oríṣìíríṣìí ohun ọ̀gbìn ati ewéko tí ń so ati oríṣìíríṣìí igi eléso tí ń so èso tí ó ní irúgbìn ninu, ó sì rí bẹ́ẹ̀. 12Ilẹ̀ bá hu koríko jáde, oríṣìíríṣìí ohun ọ̀gbìn ati ewéko tí ń so ati oríṣìíríṣìí igi eléso tí ó ní irúgbìn ninu. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára. 13Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kẹta.
14Ọlọrun pàṣẹ pé kí àwọn ìmọ́lẹ̀ wà ní ojú ọ̀run, láti fi ààlà sí ààrin ọ̀sán ati òru, kí wọ́n wà láti jẹ́ àmì, ati láti máa fi àkókò àjọ̀dún, ọjọ́, ati ọdún hàn, 15kí wọ́n sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ní ojú ọ̀run láti máa tàn sórí ilẹ̀ ayé, ó sì rí bẹ́ẹ̀. 16Ọlọrun dá ìmọ́lẹ̀ ńlá meji: ó dá oòrùn láti máa jọba ọ̀sán, ati òṣùpá láti máa jọba òru, ó sì dá àwọn ìràwọ̀ pẹlu. 17Ọlọrun fi wọ́n sí ojú ọ̀run láti máa tan ìmọ́lẹ̀ sórí ilẹ̀ ayé, 18láti máa jọba lórí ọ̀sán ati òru, ati láti fi ààlà sí ààrin ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára. 19Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kẹrin.
20Ọlọrun pàṣẹ pé kí omi kún fún oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè, kí ojú ọ̀run sì kún fún àwọn ẹyẹ. 21Ó dá àwọn ẹranko ńláńlá inú omi ati oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi, ati oríṣìíríṣìí ẹyẹ. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára. 22Ọlọrun súre fún wọn, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, kí ẹ kún gbogbo inú omi òkun, kí àwọn ẹyẹ náà sì máa pọ̀ sí i lórí ilẹ̀.” 23Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ karun-un.
24Ọlọrun pàṣẹ pé kí ilẹ̀ mú oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè jáde: oríṣìíríṣìí ẹran ọ̀sìn, oríṣìíríṣìí ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀ ati oríṣìíríṣìí ẹranko ìgbẹ́, ó sì rí bẹ́ẹ̀. 25Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun dá gbogbo wọn, ó wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára.
26Lẹ́yìn náà Ọlọrun wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á dá eniyan ní àwòrán ara wa, kí ó rí bíi wa, kí wọ́n ní àṣẹ lórí àwọn ẹja inú òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run, àwọn ẹranko ati lórí gbogbo ayé ati àwọn ohun tí wọn ń fàyà fà lórí ilẹ̀.” #Ọgb 2:23; Sir 17:3-4; 1 Kọr 11:7. 27Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun dá eniyan ní àwòrán ara rẹ̀. Takọ-tabo ni ó dá wọn. #Mat 19:4; Mak 10:6. 28Ó súre fún wọn, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ kún gbogbo ayé. Kí ayé wà ní ìkáwọ́ yín, kí ẹ ní àṣẹ lórí àwọn ẹja inú omi, lórí ẹyẹ ojú ọ̀run, ati lórí gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé.” 29Ọlọrun tún wí pé, “Mo ti pèsè gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ń so èso ati igi tí ń so èso tí ó ní irúgbìn ninu fún yín láti jẹ. 30Bẹ́ẹ̀ ni mo sì ti pèsè àwọn ewéko fún oúnjẹ àwọn ẹranko, ati àwọn ẹyẹ, ati àwọn ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀, ati gbogbo ẹ̀dá alààyè.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 31Ọlọrun wo gbogbo ohun tí ó dá, ó sì rí i pé wọ́n dára. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kẹfa. #Jẹn 5:1-2.
Đang chọn:
JẸNẸSISI 1: YCE
Tô màu
Chia sẻ
Sao chép
Bạn muốn lưu những tô màu trên tất cả các thiết bị của mình? Đăng ký hoặc đăng nhập
Bible Society of Nigeria © 1900/2010