OLUWA, Olùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli, ní,
“Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ,
tí ń kọ́ ọ ní ohun tí yóo ṣe ọ́ ní anfaani,
tí ń darí rẹ, sí ọ̀nà tí ó yẹ kí o gbà.
“Ìbá jẹ́ pé o ti fetí sí òfin mi,
alaafia rẹ ìbá máa ṣàn bí odò,
òdodo rẹ ìbá lágbára bi ìgbì omi òkun.