AISAYA 48
48
Ọlọrun ni OLUWA Ọjọ́ Iwájú
1Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin ará ilé Jakọbu,
ẹ̀yin tí à ń fi orúkọ Israẹli pè,
ọmọ bíbí inú Juda,
ẹ̀yin tí ẹ̀ ń forúkọ OLUWA búra,
tí ẹ jẹ́wọ́ Ọlọrun Israẹli,
ṣugbọn tí kì í ṣe pẹlu òdodo tabi òtítọ́.
2Ẹ̀ ń pe ara yín ní ará ìlú mímọ́,
ẹ fẹ̀yìn ti Ọlọrun Israẹli,
tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun.
3OLUWA ní, “Láti ìgbà àtijọ́ ni mo ti kéde,
àwọn nǹkan tí yóo ṣẹlẹ̀,
èmi ni mo sọ wọ́n jáde,
tí mo sì fi wọ́n hàn.
Lójijì mo ṣe wọ́n,
nǹkan tí mo sọ sì ṣẹ.
4Nítorí mo mọ̀ pé alágídí ni yín,
olóríkunkun sì ni yín pẹlu.
5Mo ti sọ fun yín láti ọjọ́ pípẹ́:
kí wọn tó ṣẹlẹ̀, mo ti kéde wọn fun yín,
kí ẹ má baà sọ pé, ‘oriṣa wa ni ó ṣe wọ́n,
àwọn ère wa ni ó pàṣẹ pé kí wọn ṣẹlẹ̀.’
6“Ẹ ti fetí ara yín gbọ́,
nítorí náà, ẹ wo gbogbo èyí, ṣé ẹ kò ní kéde rẹ̀?
Láti àkókò yìí lọ, n óo mú kí ẹ máa gbọ́ nǹkan tuntun,
àwọn nǹkan tí ó farapamọ́ tí ẹ kò mọ̀.
7Kò tíì pẹ́ tí a dá wọn,
ẹ kò gbọ́ nípa wọn rí, àfi òní.
Kí ẹ má baà wí pé:
Wò ó, a mọ̀ wọ́n.
8Ẹ kò gbọ́ ọ rí,
bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀.
Ọjọ́ ti pẹ́ tí a ti di yín létí,
nítorí mo mọ̀ pé ẹ óo hùwà àgàbàgebè,
ọlọ̀tẹ̀ ni orúkọ tí mo mọ̀ yín mọ̀,
láti ìgbà tí ẹ ti jáde ninu oyún.
9“Mo dáwọ́ ibinu mi dúró ná, nítorí orúkọ mi,
nítorí ìyìn mi ni mo ṣe dá a dúró fun yín,
kí n má baà pa yín run.
10Mo ti fọ̀ ọ́ mọ́,
ṣugbọn kì í ṣe bí a tií fọ fadaka,
mo dán yín wò ninu iná ìpọ́njú.
11Nítorí tèmi, àní nítorí tèmi ni mo ṣe ṣe bẹ́ẹ̀.
Nítorí kí ni ìdí rẹ̀ tí orúkọ mi yóo ṣe díbàjẹ́,
n kò ní gbé ògo mi fún ẹlòmíràn.
Kirusi Alákòóso tí OLUWA Yàn
12“Tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi ìwọ Jakọbu,#Ais 44:6; Ifi 1:17; 22:13
ìwọ Israẹli, ẹni tí mo pè,
Èmi ni ẹni ìbẹ̀rẹ̀,
èmi sì ni ẹni òpin.
13Ọwọ́ mi ni mo fi fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,
ọwọ́ ọ̀tún mi ni mo fi ta awọsanma sójú ọ̀run.
Nígbà tí mo pè wọ́n, gbogbo wọn jọ yọ síta.
14“Gbogbo yín, ẹ péjọ, kí ẹ gbọ́,
èwo ninu wọn ni ó kéde nǹkan wọnyi?
OLUWA fẹ́ràn rẹ̀,
yóo mú ìfẹ́ inú rẹ̀ ṣẹ lórí Babiloni,
yóo sì gbógun ti àwọn ará Kalidea.
15Èmi, àní èmi pàápàá ni mo sọ̀rọ̀, tí mo pè é,
èmi ni mo mú un wá,
yóo sì ṣe àṣeyege ninu àdáwọ́lé rẹ̀.
16Ẹ súnmọ́ mi, kí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí,
láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, n kò sọ̀rọ̀ ní àṣírí,
láti ìgbà tí ọ̀rọ̀ náà ti ṣe ni mo ti wà níbẹ̀.”
Nisinsinyii, OLUWA, Ọlọrun, ati Ẹ̀mí rẹ̀ ti rán mi.
Ìlànà Ọlọrun fún Àwọn Eniyan Rẹ̀
17OLUWA, Olùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli, ní,
“Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ,
tí ń kọ́ ọ ní ohun tí yóo ṣe ọ́ ní anfaani,
tí ń darí rẹ, sí ọ̀nà tí ó yẹ kí o gbà.
18“Ìbá jẹ́ pé o ti fetí sí òfin mi,
alaafia rẹ ìbá máa ṣàn bí odò,
òdodo rẹ ìbá lágbára bi ìgbì omi òkun.
19Àwọn ọmọ rẹ ìbá pọ̀ bí iyanrìn,
arọmọdọmọ rẹ ìbá pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀ tí kò lóǹkà.
Orúkọ wọn kì bá tí parẹ́ títí ayé,
bẹ́ẹ̀ ni kì bá tí parun lae níwájú mi.”
20Ẹ jáde kúrò ní Babiloni,#Ifi 18:4
ẹ sá kúrò ní Kalidea,
ẹ sọ ọ́ pẹlu ayọ̀,
ẹ kéde rẹ̀,
ẹ máa ròyìn rẹ̀ lọ títí dè òpin ayé, pé
“OLUWA ti ra Jakọbu iranṣẹ rẹ̀ pada.”
21Òùngbẹ kò gbẹ wọ́n,
nígbà tí ó mú wọn la inú aṣálẹ̀ kọjá,
ó tú omi jáde fún wọn láti inú àpáta,
ó la àpáta, omi sì tú jáde.
22OLUWA sọ pé, “Kò sí alaafia fún àwọn eniyan burúkú.”#Ais 57:21
Currently Selected:
AISAYA 48: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010