ẸKISODU 14
14
Líla Òkun Pupa Kọjá
1OLUWA bá rán Mose, ó ní, 2“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n yipada, kí wọ́n sì pàgọ́ siwaju Pi Hahirotu, láàrin Migidoli ati Òkun Pupa, níwájú Baali Sefoni; ẹ pàgọ́ yín siwaju rẹ̀ lẹ́bàá òkun. 3Nítorí Farao yóo wí pé, ‘Ilẹ̀ ti ká àwọn eniyan Israẹli mọ́, aṣálẹ̀ sì ti sé wọn mọ́.’ 4N óo tún mú kí ọkàn Farao le, yóo lépa yín, n óo sì gba ògo lórí Farao ati ogun rẹ̀, àwọn ará Ijipti yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” Àwọn eniyan Israẹli sì ṣe bí OLUWA ti wí.
5Nígbà tí wọ́n sọ fún Farao, ọba Ijipti, pé àwọn ọmọ Israẹli ti sálọ, èrò òun ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ nípa àwọn eniyan náà yipada. Wọ́n wí láàrin ara wọn pé, “Irú kí ni a ṣe yìí, tí a jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi lọ mọ́ wa lọ́wọ́, tí a kò jẹ́ kí wọ́n ṣì máa sìn wá?” 6Nítorí náà Farao ní kí wọ́n tọ́jú kẹ̀kẹ́ ogun òun, ó sì kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ. 7Ó ṣa ẹgbẹta (600) kẹ̀kẹ́ ogun tí ó dára, ati àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ilẹ̀ Ijipti yòókù, ó sì yan àwọn olórí ogun tí yóo máa ṣe àkóso wọn. 8OLUWA mú ọkàn Farao, ọba Ijipti le, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa àwọn ọmọ Israẹli bí wọ́n ti ń lọ tìgboyà-tìgboyà. 9Àwọn ará Ijipti ń lé wọn lọ, pẹlu gbogbo ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun Farao, ati gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀, ati gbogbo àwọn jagunjagun rẹ̀, wọ́n bá wọn níbi tí wọ́n pàgọ́ sí lẹ́bàá òkun, lẹ́bàá Pi Hahirotu ni òdìkejì Baali Sefoni.
10Nígbà tí Farao súnmọ́ àwọn ọmọ Israẹli, tí àwọn ọmọ Israẹli gbé ojú sókè tí wọ́n rí àwọn ará Ijipti tí wọn ń bọ̀ lẹ́yìn wọn; ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi. Wọ́n kígbe sí OLUWA; 11wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí Mose pé, “Ṣé kò sí ibojì ní Ijipti ni o fi kó wa kúrò láti wá kú sí ààrin aṣálẹ̀? Irú kí ni o ṣe sí wa yìí, tí o kó wa kúrò ní Ijipti? 12Ṣebí a sọ fún ọ ní Ijipti pé kí o fi wá sílẹ̀ kí á máa sin àwọn ará Ijipti tí à ń sìn, nítorí pé kì bá sàn kí á máa sin àwọn ará Ijipti ju kí á wá kú sinu aṣálẹ̀ lọ.”
13Mose bá dá àwọn eniyan náà lóhùn, ó ní, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ dúró gbọningbọnin, kí ẹ wá máa wo ohun tí OLUWA yóo ṣe. Ẹ óo rí i bí yóo ṣe gbà yín là lónìí; nítorí pé àwọn ará Ijipti tí ẹ̀ ń wò yìí, ẹ kò tún ní rí wọn mọ́ laelae. 14OLUWA yóo jà fún yín, ẹ̀yin ẹ ṣá dúró jẹ́.”
15OLUWA wí fún Mose pé, “Kí ló dé tí o fi ń ké pè mí, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n tẹ̀síwájú. 16Gbé ọ̀pá rẹ sókè kí o na ọwọ́ sórí Òkun Pupa, kí ó sì pín in sí meji, kí àwọn eniyan Israẹli lè kọjá láàrin rẹ̀ lórí ìyàngbẹ ilẹ̀. 17N óo mú kí ọkàn àwọn ará Ijipti le, kí wọ́n sì tẹ̀lé àwọn ọmọ Israẹli wọ inú Òkun Pupa, n óo sì gba ògo lórí Farao ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀. 18Àwọn ará Ijipti yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA, nígbà tí mo bá gba ògo lórí Farao ati kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.”
19Angẹli Ọlọrun tí ó ti wà níwájú àwọn eniyan Israẹli bá bọ́ sẹ́yìn wọn, ọ̀wọ̀n ìkùukùu tí ó wà níwájú wọn náà bá pada sí ẹ̀yìn wọn. 20Ọ̀wọ̀n ìkùukùu náà sì wà láàrin àwọn ọmọ ogun Ijipti ati àwọn ọmọ ogun Israẹli, ìkùukùu náà ṣókùnkùn dudu títí tí gbogbo òru ọjọ́ náà fi kọjá, wọn kò sì súnmọ́ ara wọn.
21Mose na ọwọ́ rẹ̀ sórí Òkun Pupa; OLUWA bá mú kí afẹ́fẹ́ líle kan fẹ́ wá láti ìhà ìlà oòrùn ní gbogbo òru náà, afẹ́fẹ́ náà bi omi òkun sẹ́yìn, ó sì mú kí ààrin òkun náà di ìyàngbẹ ilẹ̀, omi rẹ̀ sì pín sí ọ̀nà meji. 22Àwọn ọmọ Israẹli bọ́ sí ààrin òkun náà lórí ìyàngbẹ ilẹ̀, omi òkun wá dàbí ògiri ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún ati ní ẹ̀gbẹ́ òsì wọn.#1 Kọr 10:1-12; Heb 11:29. 23Àwọn ará Ijipti lé wọn wọ inú òkun, tàwọn ti gbogbo ẹṣin Farao ati gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ati gbogbo ẹlẹ́ṣin rẹ̀. 24Nígbà tí ó di òwúrọ̀ kutukutu, OLUWA bojú wo ogun Ijipti láti òkè wá, ninu ọ̀wọ̀n iná, ati ọ̀wọ̀n ìkùukùu, ó sì dẹ́rùbà wọ́n. 25Ó mú kí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun wọ́n há, tí ó fi jẹ́ pé àwọn kẹ̀kẹ́ náà wúwo rinrin. Àwọn ọmọ ogun Ijipti bá wí láàrin ara wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á sá fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí pé, OLUWA Ọlọrun ń bá wa jà nítorí wọn.”
26Ọlọrun bá sọ fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ sórí òkun pupa kí omi lè bo àwọn ará Ijipti ati kẹ̀kẹ́ ogun wọn, ati àwọn ẹlẹ́ṣin wọn mọ́lẹ̀.” 27Mose bá na ọwọ́ sórí òkun, òkun bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣàn tẹ́lẹ̀ nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ keji yóo fi mọ́; àwọn ará Ijipti gbìyànjú láti jáde, ṣugbọn OLUWA pa wọ́n run sinu òkun náà. 28Omi òkun pada sí ipò rẹ̀, ó sì bo gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun, ati àwọn ẹlẹ́ṣin, ati àwọn ọmọ ogun Farao tí wọ́n lépa àwọn ọmọ Israẹli wọ inú Òkun Pupa, ẹyọ kan kò sì yè ninu wọn. 29Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli rìn kọjá lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ ninu Òkun Pupa, omi rẹ̀ sì dàbí ògiri ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún ati ní ẹ̀gbẹ́ òsì wọn.
30Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe gba Israẹli lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti ní ọjọ́ náà, àwọn ọmọ Israẹli sì rí i bí àwọn ará Ijipti ti kú sí etí bèbè òkun. 31Àwọn ọmọ Israẹli rí ohun ńlá tí OLUWA ṣe sí àwọn ará Ijipti, wọ́n bẹ̀rù OLUWA, wọ́n sì gba OLUWA gbọ́, ati Mose, iranṣẹ rẹ̀.
Currently Selected:
ẸKISODU 14: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010