ORIN DAFIDI 19
19
Ògo Ọlọrun ninu àwọn ohun tí Ó dá
1Ojú ọ̀run ń sọ̀rọ̀ ògo Ọlọrun,
òfuurufú sì ń kéde iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
2Ọjọ́ dé ọjọ́ ń sọ ọ́ ní àsọgbà
òru dé òru sì ń fi ìmọ̀ rẹ̀ hàn.
3Wọn kò fọ èdè kankan, wọn kò sì sọ ọ̀rọ̀;
bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́ ohùn wọn;
4sibẹ ìró wọn la gbogbo ayé já,
ọ̀rọ̀ wọn sì dé òpin ayé.
Ó pàgọ́ fún oòrùn lójú ọ̀run,
5tí ó ń yọ jáde bí ọkọ iyawo tí ń jáde láti inú yàrá rẹ̀,
ati bí akọni tí ara ń wá láti fi tayọ̀tayọ̀ sáré ìje.
6Láti apá kan ojú ọ̀run ni ó ti ń yọ wá,
a máa yípo gbogbo ojú ọ̀run dé apá keji;
kò sì sí ohun tí ó bọ́ lọ́wọ́ ooru rẹ̀.#Rom 10:18
Òfin OLUWA
7Òfin OLUWA pé, a máa sọ ọkàn jí;
àṣẹ OLUWA dájú, ó ń sọ òpè di ọlọ́gbọ́n.
8Ìlànà OLUWA tọ́, ó ń mú ọkàn yọ̀,
àṣẹ OLUWA péye, a máa lani lójú.
9Ìbẹ̀rù OLUWA pé, ó wà títí lae,
ìdájọ́ OLUWA tọ́, òdodo ni gbogbo wọn.
10Wọ́n wuni ju wúrà lọ,
àní ju ojúlówó wúrà lọ;
wọ́n sì dùn ju oyin,
àní, wọ́n dùn ju oyin tí ń kán láti inú afárá lọ.
11Pẹlupẹlu àwọn ni wọ́n ń ki èmi iranṣẹ rẹ, nílọ̀,
èrè pupọ sì ń bẹ ninu pípa wọ́n mọ́.
12Ṣugbọn ta ni lè mọ àṣìṣe ara rẹ̀?
Wẹ̀ mí mọ́ ninu àṣìṣe àìmọ̀ mi.
13Pa èmi iranṣẹ rẹ mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀-ọ́n-mọ̀-dá;
má jẹ́ kí wọ́n jọba lórí mi.
Nígbà náà ni ara mi yóo mọ́,
n kò sì ní jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.
14Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi, ati àṣàrò ọkàn mi
jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ,
OLUWA ibi ààbò mi ati olùràpadà mi.
Currently Selected:
ORIN DAFIDI 19: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010