ORIN DAFIDI 18
18
Orin Ìṣẹ́gun
1Mo fẹ́ràn rẹ, OLUWA, agbára mi.
2OLUWA ni àpáta mi, ibi ààbò mi, ati olùgbàlà mi;
Ọlọrun mi, àpáta mi, ninu ẹni tí ààbò mi wà.
Òun ni asà mi, ìwo ìgbàlà mi ati ibi ìsásí mi.
3Mo ké pe OLUWA, ẹni tí ìyìn yẹ,
ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.
4Ikú wé mọ́ mi bí okùn,
ìparun sì bò mí mọ́lẹ̀ bíi rírú omi.
5Isà òkú yí mi ká,
tàkúté ikú sì dojú kọ mí.
6Ninu ìpọ́njú mi mo ké pe OLUWA,
Ọlọrun mi ni mo ké pè.
Ó gbọ́ ohùn mi láti inú ilé mímọ́ rẹ̀,
ó sì tẹ́tí sí igbe mi.
7Ilẹ̀ ayé wárìrì, ó sì mì tìtì,
ìpìlẹ̀ àwọn òkè mì jìgìjìgì;
wọ́n wárìrì nítorí tí ó bínú.
8Èéfín ṣẹ́ jáde láti ihò imú rẹ̀,
iná ajónirun yọ jáde láti ẹnu rẹ̀;
ẹ̀yinná sì ń jò bùlà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá.
9Ó dẹ ojú ọ̀run sílẹ̀, ó sì sọ̀kalẹ̀ wá,
ìkùukùu tó ṣókùnkùn biribiri sì wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.
10Ó gun orí Kerubu, ó sì fò,
ó fò lọ sókè lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́.
11Ó fi òkùnkùn bora bí aṣọ,
ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn, tí ó sì kún fún omi
ni ó fi ṣe ìbòrí.
12Ninu ìmọ́lẹ̀ níwájú rẹ,
ẹ̀yinná ati yìnyín ń fọ́n jáde,
láti inú ìkùukùu.
13OLUWA sán ààrá láti ọ̀run,
Ọ̀gá Ògo fọhùn, òjò dídì ati ẹ̀yinná sì fọ́n jáde.
14Ó ta ọfà rẹ̀ jáde, ó sì fọ́n wọn ká,
ó jẹ́ kí mànàmáná kọ, ó sì tú wọn ká.
15Nígbà náà ni ìsàlẹ̀ òkun hàn ketekete,
ìpìlẹ̀ ayé sì fojú hàn gbangba nítorí ìbáwí rẹ, OLUWA,
ati nítorí agbára èémí ihò imú rẹ.
16Ó nawọ́ láti òkè wá, ó sì dì mí mú,
ó fà mí jáde láti inú ibú omi.
17Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi tí ó lágbára,
ati lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi;
nítorí wọ́n lágbára jù mí lọ.
18Wọ́n gbógun tì mí ní ọjọ́ ìpọ́njú mi,
ṣugbọn OLUWA ni aláfẹ̀yìntì mi.
19Ó mú mi jáde wá síbi tí ó láàyè,
ó yọ mí jáde nítorí tí inú rẹ̀ dùn sí mi.
20OLUWA ti san án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,
bí ọwọ́ mi ṣe mọ́ ni ó ṣe pín mi lérè.
21Nítorí tí mo ti pa ọ̀nà OLUWA mọ́,
n kò ṣe ibi nípa yíyà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun mi.
22Nítorí pé gbogbo òfin rẹ̀ ni mo tẹ̀lé,
n kò sì yà kúrò ninu ìlànà rẹ̀.
23Mo wà ní àìlẹ́bi níwájú rẹ̀,
mo sì ti yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀.
24Nítorí náà ni OLUWA ṣe san án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;
ati gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ mi ṣe mọ́ lójú rẹ̀.
25Ò máa dúró ti àwọn tí ó dúró tì ọ́,
ò sì máa ṣe àṣepé fún àwọn tí ó pé;
26mímọ́ ni ọ́ sí àwọn tí ọkàn wọn mọ́,
ṣugbọn àwọn alárèékérekè ni o fi ọgbọ́n tayọ.
27Nítorí tí o máa ń gba àwọn onírẹ̀lẹ̀ là,
ṣugbọn o máa ń rẹ àwọn onigbeeraga sílẹ̀.
28Nítorí ìwọ ni o mú kí àtùpà mi máa tàn,
OLUWA, Ọlọrun mi ni ó tan ìmọ́lẹ̀ sí òkùnkùn mi.
29Pẹlu ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, mo lè run ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun,
àní, pẹlu àtìlẹ́yìn Ọlọrun mi, mo lè fo odi ìlú.
30Ní ti Ọlọrun, ọ̀nà rẹ̀ pé,
pípé ni ọ̀rọ̀ OLUWA;
òun sì ni ààbò fún gbogbo àwọn tí ó sá di í.
31Ta tún ni Ọlọrun, bíkòṣe OLUWA?
Àbí, ta ni àpáta, àfi Ọlọrun wa?
32Ọlọrun tí ó gbé agbára wọ̀ mí,
tí ó sì mú ọ̀nà mi pé.
33Ó fi eré sí mi lẹ́sẹ̀ bíi ti àgbọ̀nrín,
ó sì fún mi ní ààbò ní ibi ìsásí.
34Ó kọ́ mi ní ogun jíjà
tóbẹ́ẹ̀ tí mo fi lè fa ọrun idẹ.#Hab 3:19
35O ti fún mi ní asà ìgbàlà rẹ,
ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ó gbé mi ró,
ìrànlọ́wọ́ rẹ sì ni ó sọ mí di ẹni ńlá.
36O la ọ̀nà tí ó gbòòrò fún mi,
n kò sì fi ẹsẹ̀ rọ́.
37Mo lé àwọn ọ̀tá mi, ọwọ́ mi sì tẹ̀ wọ́n,
n kò bojú wẹ̀yìn títí a fi pa wọ́n run.
38Mo ṣá wọn lọ́gbẹ́, wọn kò lè dìde,
wọ́n ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ mi.
39O gbé agbára ogun wọ̀ mí;
o sì mú àwọn tí ó dìde sí mi wólẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ mi.
40O mú kí àwọn ọ̀tá mi máa sá níwájú mi,
mo sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run.
41Wọ́n kígbe pé, “Ẹ gbà wá o!”
Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó gbà wọ́n,
wọ́n ké pe OLUWA, ṣugbọn kò dá wọn lóhùn.
42Mo lọ̀ wọ́n lúbúlúbú bí eruku tí afẹ́fẹ́ ń gbá lọ,
mo dà wọ́n nù bí ẹni da omi ẹrẹ̀ nù.
43O gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tẹ̀ àwọn eniyan,
o fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè;
àwọn orílẹ̀-èdè tí n kò mọ̀ rí sì ń sìn mí.
44Bí wọ́n bá ti gbúròó mi ni wọ́n ń gbọ́ràn sí mi lẹ́nu;
àwọn àjèjì ń fi ìbẹ̀rùbojo tẹríba, wọ́n ń wá ojurere mi.
45Àyà pá àwọn àlejò,
wọ́n sì fi ìbẹ̀rùbojo sá jáde kúrò ní ibi tí wọ́n sápamọ́ sí.
46OLUWA wà láàyè! Ẹni ìyìn ni àpáta mi!
Ẹni àgbéga ni Ọlọrun ìgbàlà mi!
47Ọlọrun tí ó ń gbẹ̀san fún mi,
tí ó sì ń tẹ orí àwọn eniyan ba fún mi;
48Ọlọrun tí ó gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi;
tí ó sì gbé mi ga ju àwọn abínú-ẹni lọ;
ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ àwọn ẹni ipá tí ó dìde sí mi.
49Nítorí náà ni èmi ó ṣe máa yìn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, OLUWA,
èmi ó sì máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ.#Rom 15:9
50Ó fi ìṣẹ́gun ńlá fún ọba rẹ̀,
ó sì fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ han ẹni àmì òróró rẹ̀,
àní Dafidi ati ìrandíran rẹ̀ títí lae.
Currently Selected:
ORIN DAFIDI 18: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010