ORIN DAFIDI 25
25
Adura fún ìtọ́sọ́nà ati Ààbò
1OLUWA, ìwọ ni mo gbé ojú ẹ̀bẹ̀ sókè sí.
2Ọlọrun mi, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé,
má jẹ́ kí ojú ó tì mí;
má jẹ́ kí ọ̀tá ó yọ̀ mí.
3OLUWA, má jẹ́ kí ojú ó ti ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọ;
àwọn ọ̀dàlẹ̀ eniyan ni kí ojú ó tì.
4Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, OLUWA,
kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ.
5Tọ́ mi sí ọ̀nà òtítọ́ rẹ, sì máa kọ́ mi,
nítorí ìwọ ni Ọlọrun olùgbàlà mi;
ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé ní ọjọ́ gbogbo.
6OLUWA, ranti àánú rẹ, ati ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,
nítorí wọ́n ti wà ọjọ́ ti pẹ́.
7Má ranti ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ti ṣẹ̀ ní ìgbà èwe mi,
tabi ibi tí mo ti kọjá ààyè mi;
ranti mi, OLUWA, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,
ati nítorí oore rẹ.
8Olóore ati olódodo ni OLÚWA,
nítorí náà ni ó ṣe ń fi ọ̀nà han àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
9A máa tọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ láti ṣe ohun tí ó tọ́,
a sì máa kọ́ wọn ní ìlànà rẹ̀.
10Gbogbo ọ̀nà OLUWA ni ó kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́,
fún àwọn tí ń pa majẹmu ati òfin rẹ̀ mọ́.
11Nítorí orúkọ rẹ, OLUWA, dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí,
nítorí mo jẹ̀bi lọpọlọpọ.
12Ẹni tí ó bá bẹ̀rù OLUWA
ni OLUWA yóo kọ́ ní ọ̀nà tí yóo yàn.
13Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóo ní ọpọlọpọ ọrọ̀,
àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóo sì jogún ilẹ̀ náà.
14Àwọn tí ó bá bẹ̀rù OLUWA ni OLUWA ń mú ní ọ̀rẹ́,
a sì máa fi majẹmu rẹ̀ hàn wọ́n.
15OLUWA ni mò ń wò lójú nígbà gbogbo,
nítorí òun ni yóo yọ ẹsẹ̀ mi kúrò ninu àwọ̀n.
16Kọjú sí mi kí o sì ṣàánú mi;
nítorí n kò lẹ́nìkan, ojú sì ń pọ́n mi.
17Mú ìdààmú ọkàn mi kúrò;
kí o sì yọ mí ninu gbogbo ìpọ́njú mi.
18Wo ìpọ́njú ati ìdààmú mi,
kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí.
19Wo iye ọ̀tá tí èmi nìkan ní,
ati irú ìkórìíra ìkà tí wọ́n kórìíra mi.
20Pa mí mọ́, kí o sì gbà mí;
má jẹ́ kí ojú kí ó tì mí,
nítorí ìwọ ni mo sá di.
21Nítorí pípé mi ati òdodo mi, pa mí mọ́,
nítorí pé ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé.
22Ọlọrun, ra Israẹli pada,
kúrò ninu gbogbo ìyọnu rẹ̀.
Currently Selected:
ORIN DAFIDI 25: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010