ORIN DAFIDI 37
37
Ìgbẹ̀yìn Àwọn Eniyan Burúkú
1Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná nítorí àwọn eniyan burúkú;
má sì jowú àwọn aṣebi;
2nítorí pé kíákíá ni wọn yóo gbẹ bí i koríko;
wọn óo sì rọ bí ewé.
3Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA; kí o sì máa ṣe rere.
Máa gbe ilẹ̀ náà; ewu kò sì ní wu ọ́.
4Jẹ́ kí inú rẹ máa dùn ninu OLUWA;
yóo sì fún ọ ní ohun tí ọkàn rẹ ń fẹ́.
5Fi ọ̀nà rẹ lé OLUWA lọ́wọ́;
gbẹ́kẹ̀lé e, yóo sì ṣe ohun tí ó yẹ.
6Yóo mú kí ìdáláre rẹ tàn bí ìmọ́lẹ̀;
ẹ̀tọ́ rẹ yóo sì hàn kedere bí ọ̀sán gangan.
7Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLUWA; fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé e.
Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná nítorí ẹni tí nǹkan ń dára fún;
tabi nítorí ẹni tí ń gbèrò ibi, tí ó sì ń ṣe é.
8Yẹra fún ibinu; sì yàgò fún ìrúnú.
Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná; ibi ni àyọrísí rẹ̀.
9Nítorí pé a óo pa àwọn eniyan burúkú run;
ṣugbọn àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA
ni yóo jogún ilẹ̀ náà.
10Ẹ fún eniyan burúkú ní ìgbà díẹ̀ sí i, yóo pòórá;
ẹ̀ báà wá a títí ní ààyè rẹ̀, kò ní sí níbẹ̀.
11Ṣugbọn àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóo jogún ilẹ̀ náà:
wọn óo máa gbádùn ara wọn;
wọn óo sì ní alaafia lọpọlọpọ.#Mat 5:5
12Eniyan burúkú dìtẹ̀ mọ́ olódodo;
ó sì ń wò ó bíi kíkú bíi yíyè.
13Ṣugbọn OLUWA ń fi eniyan burúkú rẹ́rìn-ín,
nítorí ó mọ̀ pé ọjọ́ ìparun rẹ̀ ń bọ̀.
14Àwọn eniyan burúkú fa idà yọ, wọ́n sì kẹ́ ọfà wọn
láti gba ẹ̀mí talaka ati aláìní,
láti pa àwọn tí ń rìn lọ́nà ẹ̀tọ́.
15Ṣugbọn idà wọn ni o óo fi pa wọ́n,
ọrun wọn yóo sì dá.
16Nǹkan díẹ̀ tí olódodo ní
dára ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ àwọn eniyan burúkú.
17Nítorí OLUWA yóo ṣẹ́ apá eniyan burúkú,
ṣugbọn yóo gbé olódodo ró.
18OLUWA a máa tọ́jú àwọn aláìlẹ́bi;
ilẹ̀ ìní wọn yóo jẹ́ tiwọn títí lae.
19Ojú kò ní tì wọ́n nígbà tí àjálù bá dé;
bí ìyàn tilẹ̀ mú, wọn óo jẹ, wọn óo yó.
20Ṣugbọn àwọn eniyan burúkú yóo ṣègbé;
àwọn ọ̀tá OLUWA yóo pòórá bí ẹwà ewéko
wọn óo parẹ́ bí èéfín tí í parẹ́.
21Bí eniyan burúkú bá yá owó, kò ní san;
ṣugbọn ẹni rere ní ojú àánú, ó sì lawọ́.
22Nítorí pé àwọn tí Ọlọrun bá bukun ni yóo jogún ilẹ̀ náà,
ṣugbọn àwọn tí ó bá fi gégùn-ún yóo parun.
23OLUWA níí darí ìgbésẹ̀ ẹni;
a sì máa fi ẹsẹ̀ ẹni tí inú rẹ̀ bá dùn sí múlẹ̀.
24Bí ó tilẹ̀ ṣubú, kò ní lulẹ̀ lógèdèǹgbé,
nítorí OLUWA yóo gbé e ró.
25Mo ti jẹ́ ọmọde rí; mo sì ti dàgbà:
n kò tíì ri kí á kọ olódodo sílẹ̀,
tabi kí ọmọ rẹ̀ máa tọrọ jẹ.
26Olódodo ní ojú àánú, a sì máa yáni ní nǹkan,
ayọ̀ ń bẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀.
27Ẹ yẹra fún ibi; ẹ sì máa ṣe rere;
kí ẹ lè wà ní ààyè yín títí lae.
28Nítorí OLUWA fẹ́ràn ẹ̀tọ́;
kò ní kọ àwọn olùfọkànsìn rẹ̀ sílẹ̀.
Yóo máa ṣọ́ wọn títí lae,
ṣugbọn a óo pa àwọn ọmọ eniyan burúkú run.
29Àwọn ẹni rere ni yóo jogún ilẹ̀ náà;
wọn óo sì máa gbé orí rẹ̀ títí lae.
30Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n níí máa jáde lẹ́nu ẹni rere,
a sì máa sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́.
31Òfin Ọlọrun rẹ̀ wà ní ọkàn rẹ̀;
ìrìn ẹsẹ̀ rẹ̀ kì í yà kúrò níbẹ̀.
32Eniyan burúkú ń ṣọ́ olódodo,
ó ń wá ọ̀nà ati pa á.
33OLUWA kò ní fi olódodo lé e lọ́wọ́,
tabi kí ó jẹ́ kí á dá olódodo lẹ́bi ní ilé ẹjọ́.
34Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, sì máa tọ ọ̀nà rẹ̀,
yóo gbé ọ ga, kí o lè jogún ilẹ̀ náà;
nígbà tí a bá pa àwọn eniyan burúkú run, o óo fojú rẹ rí i.
35Mo ti rí eniyan burúkú tí ń halẹ̀ mọ́ni,
tí ó ga bí igi kedari ti Lẹbanoni.
36Ṣugbọn nígbà tí mo tún gba ibẹ̀ kọjá,
mo wò ó, kò sí níbẹ̀ mọ́;
mo wá a, ṣugbọn n kò rí i.
37Ṣe akiyesi ẹni pípé;
sì wo olódodo dáradára,
nítorí pé ìgbẹ̀yìn ẹni tí ń wá alaafia yóo dára.
38Ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo parun patapata,
a óo sì run ọmọ àwọn eniyan burúkú.
39Ọ̀dọ̀ OLUWA ni ìgbàlà àwọn olódodo ti ń wá;
òun ni alátìlẹ́yìn wọn ní àkókò ìṣòro.
40OLUWA a máa ràn wọ́n lọ́wọ́, a sì máa gbà wọ́n;
a máa gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú,
a sì máa gbà wọ́n là,
nítorí pé òun ni wọ́n sá di.
Currently Selected:
ORIN DAFIDI 37: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010