ORIN DAFIDI 36
36
Ìwà ìkà
1Ẹ̀ṣẹ̀ ń gbin lọ́kàn eniyan burúkú,
kò sí ìbẹ̀rù Ọlọrun ninu èrò tirẹ̀.
2Nítorí pé lọ́kàn rẹ̀ a máa pọ́n ara rẹ̀,
pé kò sí ẹni tí ó lè rí ẹ̀ṣẹ̀ òun,
ká tó wá sọ pé yóo dá òun lẹ́bi.
3Ọ̀rọ̀ ìkà ati ẹ̀tàn ni ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀.
Ó ti dáwọ́ ire ṣíṣe dúró;
kò sì hu ìwà ọlọ́gbọ́n mọ́.
4A máa pète ìkà lórí ibùsùn rẹ̀;
a máa rin ọ̀nà tí kò tọ́;
kò sì kórìíra ibi.#Rom 3:18
Oore Ọlọrun
5OLUWA, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ga kan ọ̀run;
òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run.
6Òtítọ́ rẹ dàbí òkè ńlá;
ìdájọ́ rẹ sì jìn bí ibú omi.
OLUWA, àtènìyàn, àtẹranko ni ò ń gbàlà.
7Ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ níye lórí pupọ, Ọlọrun!
Àwọn ọmọ eniyan a máa sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ.
8Wọ́n ń rí oúnjẹ jẹ ní àjẹyó ní ilé rẹ;
nǹkan mímu tí ń ṣàn bí odò,
ni o sì ń fún wọn mu.
9Nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà;
ninu ìmọ́lẹ̀ rẹ ni a ti ń rí ìmọ́lẹ̀.
10Túbọ̀ máa fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀
han àwọn tí ó mọ̀ ọ́,
sì máa fi òdodo rẹ han àwọn ọlọ́kàn mímọ́.
11Má jẹ́ kí àwọn agbéraga borí mi,
má sì jẹ́ kí àwọn eniyan burúkú lé mi kúrò.
12Ẹ wo àwọn aṣebi níbi tí wọ́n ṣubú sí;
wọ́n dà wólẹ̀, wọn kò sì le dìde.
Currently Selected:
ORIN DAFIDI 36: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010