ORIN DAFIDI 79
79
Adura Ìdáǹdè Orílẹ̀-Èdè
1Ọlọrun, àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà ti wọ inú ilẹ̀ ìní rẹ;
wọ́n ti ba ilé mímọ́ rẹ jẹ́;
wọ́n sì ti sọ Jerusalẹmu di ahoro.#2A. Ọba 25:8-10; 2Kron 36:17-19; Jer 52:12-14
2Wọ́n ti fi òkú àwọn iranṣẹ rẹ
fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run jẹ;
wọ́n sì ti sọ òkú àwọn eniyan mímọ́ rẹ di ìjẹ
fún àwọn ẹranko ìgbẹ́.
3Wọ́n ti da ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ bí omi, káàkiri Jerusalẹmu;
kò sì sí ẹni tí yóo gbé wọn sin.
4A ti di ẹni ẹ̀gàn lójú àwọn aládùúgbò wa;
àwọn tí ó yí wa ká ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́;
wọ́n sì ń fi wá rẹ́rìn-ín.
5Yóo ti pẹ́ tó, OLUWA?
Ṣé títí ayé ni o óo máa bínú ni?
Àbí owú rẹ yóo máa jó bí iná?
6Tú ibinu rẹ sórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́,
ati orí àwọn ìjọba tí kò sìn ọ́.
7Nítorí pé wọ́n ti jẹ Jakọbu run;
wọ́n sì ti sọ ibùgbé rẹ di ahoro.
8Má gbẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wa lára wa;
yára, kí o ṣàánú wa,
nítorí pé a ti rẹ̀ wá sílẹ̀ patapata.
9Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọrun Olùgbàlà wa,
nítorí iyì orúkọ rẹ;
gbà wá, sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá,
nítorí orúkọ rẹ.
10Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè yóo fi máa sọ pé,
“Níbo ni Ọlọrun wọn wà?”
Níṣojú wa, gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn iranṣẹ rẹ tí a pa
lára àwọn orílẹ̀-èdè!
11Jẹ́ kí ìkérora àwọn ìgbèkùn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ;
gẹ́gẹ́ bí agbára ńlá rẹ,
dá àwọn tí a dájọ́ ikú fún sí.
12OLUWA, san ẹ̀san ẹ̀gàn tí àwọn aládùúgbò wa gàn ọ́,
san án fún wọn ní ìlọ́po meje,
13Nígbà náà, àwa eniyan rẹ,
àní, àwa agbo aguntan pápá rẹ,
yóo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ títí lae;
a óo sì máa sọ̀rọ̀ ìyìn rẹ láti ìran dé ìran.
Currently Selected:
ORIN DAFIDI 79: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010