YouVersion Logo
Search Icon

ORIN DAFIDI 96

96
Ọlọrun Ọba Àwọn Ọba
(1Kron 16:23-33)
1Ẹ kọ orin titun sí OLUWA;
gbogbo ayé, ẹ kọ orin sí OLUWA.
2Ẹ kọ orin sí OLUWA, ẹ yin orúkọ rẹ̀;
ẹ sọ nípa ìgbàlà rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́.
3Ẹ kéde ògo rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè;
ẹ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrin àwọn eniyan.
4Nítorí OLUWA tóbi, ó yẹ kí á máa yìn ín lọpọlọpọ;
ó sì yẹ kí á bẹ̀rù rẹ̀ ju gbogbo oriṣa lọ.
5Nítorí oriṣa lásán ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ń sìn,
ṣugbọn OLUWA ni ó dá ọ̀run.
6Iyì ati ọlá ńlá ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀;
agbára ati ẹwà kún inú ilé mímọ́ rẹ̀.
7Ẹ yin OLUWA, gbogbo ẹ̀yin aráyé;
ẹ kókìkí ògo ati agbára rẹ̀.
8Ẹ fún OLUWA ní iyì tí ó tọ́ sí orúkọ rẹ̀,
ẹ mú ọrẹ lọ́wọ́ wá sinu àgbàlá rẹ̀.
9Ẹ sin OLUWA ninu ẹwà ìwà mímọ́;
gbogbo ayé, ẹ wárìrì níwájú rẹ̀.#O. Daf 29:1-2
10Ẹ wí láàrin àwọn orílẹ̀-èdè pé, “OLUWA jọba!
A ti fi ìdí ayé múlẹ̀, kò sì ní yẹ̀ lae;
OLUWA yóo fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan.”
11Jẹ́ kí inú ọ̀run ó dùn, sì jẹ́ kí ayé ó yọ̀;
kí òkun ó hó, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀.
12Jẹ́ kí pápá oko ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ yọ̀.
Nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóo fi ayọ̀ kọrin,
13níwájú OLUWA, nítorí pé ó ń bọ̀;
ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé.
Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé;
yóo sì fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan.

Currently Selected:

ORIN DAFIDI 96: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in