YouVersion Logo
Search Icon

II. Tim 3

3
Ìwà tí Àwọn Eniyan Yóo Máa Hù ní Ọjọ́ Ìkẹyìn
1ṢUGBỌN eyi ni ki o mọ̀, pe ni ikẹhin ọjọ ìgbà ewu yio de.
2Nitori awọn enia yio jẹ olufẹ ti ara wọn, olufẹ owo, afunnú, agberaga, asọ̀rọbuburu, aṣaigbọran si obi, alailọpẹ, alaimọ́,
3Alainifẹ, alaile darijini, abanijẹ́, alaile-kó-ra-wọnnijanu, onroro, alainifẹ-ohun-rere,
4Onikupani, alagidi, ọlọkàn giga, olufẹ fãji jù olufẹ Ọlọrun lọ;
5Awọn ti nwọn ni afarawe iwa-bi-Ọlọrun, ṣugbọn ti nwọn sẹ́ agbara rẹ̀: yẹra kuro lọdọ awọn wọnyi pẹlu.
6Nitori ninu irú eyi li awọn ti nrakò wọ̀ inu ile, ti nwọn si ndì awọn obinrin alailọgbọn ti a dì ẹ̀ṣẹ rù ni igbekùn, ti a si nfi onirũru ifẹkufẹ fà kiri,
7Nwọn nfi igbagbogbo kẹ́kọ, nwọn kò si le de oju ìmọ otitọ.
8Njẹ gẹgẹ bi Janesi ati Jamberi ti kọ oju ija si Mose, bẹ̃li awọn wọnyi kọ oju ija si otitọ: awọn enia ti inu wọn dibajẹ, awọn ẹni ìtanù niti ọran igbagbọ́.
9Ṣugbọn nwọn kì yio lọ siwaju jù bẹ̃lọ: nitori wère wọn yio farahan fun gbogbo enia gẹgẹ bi tiwọn ti yọri si.
A Tún Kìlọ̀ fún Timotiu
10Ṣugbọn iwọ ti mọ̀ ẹkọ́ mi, igbesi aiye mi, ipinnu, igbagbọ́, ipamọra, ifẹ́ni, sũru,
11Inunibini, iyà; awọn ohun ti o dé bá mi ni Antioku, ni Ikonioni ati ni Listra; awọn inunibini ti mo faradà: Oluwa si gbà mi kuro ninu gbogbo wọn.
12Nitõtọ, gbogbo awọn ti o fẹ mã gbé igbé ìwa-bi-Ọlọrun ninu Kristi Jesu, yio farada inunibini.
13Ṣugbọn awọn enia buburu, ati awọn ẹlẹtàn yio mã gbilẹ siwaju si i, nwọn o mã tàn-ni-jẹ, a o si mã tàn wọn jẹ.
14Ṣugbọn iwọ duro ninu nkan wọnni ti iwọ ti kọ́, ti a si ti jẹ ki oju rẹ dá ṣáṣa si, ki iwọ ki o si mọ̀ ọdọ ẹniti iwọ gbé kọ́ wọn;
15Ati pe lati igba ọmọde ni iwọ ti mọ̀ iwe-mimọ́, ti o le sọ ọ di ọlọ́gbọn si igbala nipasẹ igbagbọ́ ninu Kristi Jesu.
16Gbogbo iwe-mimọ́ ni o ni imísi Ọlọrun ti o si ni ère fun ẹkọ́, fun ibaniwi, fun itọ́ni, fun ikọ́ni ti o wà ninu ododo:
17Ki enia Ọlọrun ki o le pé, ti a ti mura silẹ patapata fun iṣẹ rere gbogbo.

Currently Selected:

II. Tim 3: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in