II. Tim 4
4
1NITORINA mo paṣẹ fun ọ niwaju Ọlọrun, ati Kristi Jesu, ẹniti yio ṣe idajọ alãye ati okú, ati nitori ifarahàn rẹ̀ ati ijọba rẹ̀,
2Wasu ọ̀rọ na; ṣe aisimi li akokò ti o wọ̀, ati akokò ti kò wọ̀; baniwi, ṣe itọ́ni, gbà-ni-niyanju pẹlu ipamọra ati ẹ̀kọ́ gbogbo.
3Nitoripe ìgba yio de, ti nwọn kì yio le gba ẹkọ́ ti o yè kõro; ṣugbọn bi nwọn ti jẹ ẹniti eti nrìn nwọn ó lọ kó olukọ jọ fun ara wọn ninu ifẹkufẹ ara wọn.
4Nwọn ó si yi etí wọn pada kuro ninu otitọ, nwọn ó si yipada si ìtan asan.
5Ṣugbọn mã ṣe pẹlẹ ninu ohun gbogbo, mã farada ipọnju, ṣe iṣẹ efangelisti, ṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ laṣepe.
6Nitori a nfi mi rubọ nisisiyi, atilọ mi si sunmọ etile.
7Emi ti jà ìja rere, emi ti pari ire-ije mi, emi ti pa igbagbọ́ mọ́:
8Lati isisiyi lọ a fi ade ododo lelẹ fun mi, ti Oluwa, onidajọ ododo, yio fifun mi li ọjọ na, kì si iṣe kìki emi nikan, ṣugbọn pẹlu fun gbogbo awọn ti o ti fẹ ifarahàn rẹ̀.
Ọ̀rọ̀ Ìparí
9Sa ipa rẹ lati tete tọ̀ mi wá.
10Nitori Dema ti kọ̀ mi silẹ, nitori o nfẹ aiye isisiyi, o si lọ si Tessalonika; Kreskeni si Galatia, Titu si Dalmatia.
11Luku nikan li o wà pẹlu mi. Mu Marku wá pẹlu rẹ: nitori o wulo fun mi fun iṣẹ iranṣẹ.
12Mo rán Tikiku ni iṣẹ lọ si Efesu.
13Aṣọ otutu ti mo fi silẹ ni Troa lọdọ Karpu, nigbati iwọ ba mbọ̀ mu u wá, ati iwe wọnni, pẹlupẹlu iwe-awọ wọnni.
14Aleksanderu alagbẹdẹ bàba ṣe mi ni ibi pupọ̀: Oluwa yio san a fun u gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀:
15Lọdọ ẹniti ki iwọ ki o mã ṣọra pẹlu; nitoriti o kọ oju ija si iwasu wa pupọ̀.
16Li àtetekọ jẹ ẹjọ mi, kò si ẹniti o bá mi gba ẹjọ ro, ṣugbọn gbogbo enia li o kọ̀ mi silẹ: adura mi ni ki a máṣe kà a si wọn li ọrùn.
17Ṣugbọn Oluwa gbà ẹjọ mi ro, o si fun mi lagbara; pe nipasẹ mi ki a le wãsu na ni awàjálẹ̀, ati pe ki gbogbo awọn Keferi ki o le gbọ́: a si gbà mi kuro li ẹnu kiniun nì.
18Oluwa yio yọ mi kuro ninu iṣẹ buburu gbogbo, yio si gbé mi de inu ijọba rẹ̀ ọrun: ẹniti ogo wà fun lai ati lailai. Amin.
Ìdágbére
19Kí Priskilla ati Akuila, ati ile Onesiforu.
20Erastu wà ni Korinti: ṣugbọn mo fi Trofimu silẹ ni Miletu ninu aisan.
21Sa ipa rẹ lati tete wá ṣaju ìgba otutù. Eubulu kí ọ, ati Pudeni, ati Linu, ati Klaudia, ati gbogbo awọn arakunrin.
22Ki Oluwa ki o wà pẹlu ẹmí rẹ. Ki ore-ọfẹ ki o wà pẹlu nyin. Amin.
Currently Selected:
II. Tim 4: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.