Eks 10
10
1OLUWA si sọ fun Mose pe, Wọle tọ̀ Farao lọ: nitoriti mo mu àiya rẹ̀ le, ati àiya awọn iranṣẹ rẹ̀, ki emi ki o le fi iṣẹ-àmi mi wọnyi hàn niwaju rẹ̀:
2Ati ki iwọ ki o le wi li eti ọmọ rẹ, ati ti ọmọ ọmọ rẹ, ohun ti mo ṣe ni Egipti, ati iṣẹ-àmi mi ti mo ṣe ninu wọn; ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe emi li OLUWA.
3Mose ati Aaroni si wọle tọ̀ Farao lọ, nwọn si wi fun u pe, Bayi li OLUWA Ọlọrun Heberu wi, Iwọ o ti kọ̀ pẹ tó lati rẹ̀ ara rẹ silẹ niwaju mi? jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn mi.
4Ṣugbọn bi iwọ ba si kọ̀ lati jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, kiyesi i, li ọla li emi o mú eṣú wá si ẹkùn rẹ:
5Nwọn o si bò oju ilẹ ti ẹnikan ki yio fi le ri ilẹ: nwọn o si jẹ ajẹkù eyiti o bọ́, ti o kù fun nyin lọwọ yinyin, yio si jẹ igi nyin gbogbo ti o nruwe ninu oko.
6Nwọn o si kún ile rẹ, ati ile awọn iranṣẹ rẹ gbogbo, ati ile awọn ara Egipti gbogbo; ti awọn baba rẹ, ati awọn baba baba rẹ kò ri ri, lati ìgba ọjọ́ ti nwọn ti wà lori ilẹ titi o fi di oni-oloni. O si yipada, o jade kuro lọdọ Farao.
7Awọn iranṣẹ Farao si wi fun u pe, ọkunrin yi yio ti ṣe ikẹkùn si wa pẹ to? jẹ ki awọn ọkunrin na ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn OLUWA Ọlọrun wọn: iwọ kò ti imọ̀ pe Egipti run tán?
8A si tun mú Mose ati Aaroni wá sọdọ Farao: o si wi fun wọn pe, Ẹ lọ sìn OLUWA Ọlọrun nyin; ṣugbọn awọn tani yio ha lọ?
9Mose si wipe, Awa o lọ ati ewe ati àgba, ati awọn ọmọkunrin wa ati awọn ọmọbinrin wa, pẹlu awọn agbo, ati ọwọ́-ẹran wa li awa o lọ; nitori ajọ OLUWA ni fun wa:
10O si wi fun wọn pe, Ki OLUWA ki o pẹlu nyin bẹ̃, bi emi o ti jẹ ki ẹ lọ yi, ati awọn ewe nyin: ẹ wò o; nitori ibi mbẹ niwaju nyin.
11Bẹ̃kọ: ẹnyin ọkunrin ẹ lọ, ki ẹ si sìn OLUWA; eyinì li ẹnyin sá nfẹ́. Nwọn si lé wọn jade kuro niwaju Farao.
12OLUWA si wi fun Mose pe, Nà ọwọ́ rẹ sori ilẹ Egipti nitori eṣú, ki nwọn ki o le wá sori ilẹ Egipti, ki nwọn ki o si le jẹ gbogbo eweko ilẹ yi, gbogbo eyiti yinyin ti kù silẹ.
13Mose si nà ọpá rẹ̀ si ori ilẹ Egipti, OLUWA si mu afẹfẹ ìla-õrùn kan fẹ́ si ori ilẹ na, ni gbogbo ọsán na, ati gbogbo oru na; nigbati o di owurọ̀, afẹfẹ ila-õrùn mú awọn eṣú na wá.
14Awọn eṣú na si goke sori ilẹ Egipti gbogbo, nwọn si bà si ẹkùn Egipti gbogbo; nwọn papọ̀ju, kò si irú eṣú bẹ̃ ṣaju wọn, bẹ̃ni lẹhin wọn irú wọn ki yio si si.
15Nitoriti nwọn bò oju ilẹ gbogbo, tobẹ̃ ti ilẹ fi ṣú; nwọn si jẹ gbogbo eweko ilẹ na, ati gbogbo eso igi ti yinyin kù silẹ: kò si kù ohun tutù kan lara igi, tabi lara eweko igbẹ́, já gbogbo ilẹ Egipti.
16Nigbana ni Farao ranṣẹ pè Mose ati Aaroni kánkan; o si wipe, Emi ti ṣẹ̀ si OLUWA Ọlọrun nyin, ati si nyin.
17Njẹ nitorina emi bẹ̀ nyin, ẹ fi ẹ̀ṣẹ mi jì lẹ̃kanṣoṣo yi, ki ẹ si bẹ̀ OLUWA Ọlọrun nyin, ki o le mú ikú yi kuro lọdọ mi.
18On si jade kuro niwaju Farao, o si bẹ̀ OLUWA.
19OLUWA si yi afẹfẹ ìwọ-õrùn lile-lile ti o si fẹ́ awọn eṣú na kuro, o si gbá wọn lọ sinu Okun Pupa; kò si kù eṣú kanṣoṣo ni gbogbo ẹkùn Egipti.
20Ṣugbọn OLUWA mu àiya Farao le, bẹ̃ni kò si jẹ ki awọn ọmọ Israeli ki o lọ.
21OLUWA si wi fun Mose pe, Nà ọwọ́ rẹ si ọrun, ki òkunkun ki o ṣú yiká ilẹ Egipti, ani òkunkun ti a le fọwọbà.
22Mose si nà ọwọ́ rẹ̀ si ọrun; òkunkun biribiri si ṣú ni gbogbo ilẹ Egipti ni ijọ́ mẹta:
23Nwọn kò ri ara wọn, bẹ̃li ẹnikan kò si dide ni ipò tirẹ̀ ni ijọ́ mẹta: ṣugbọn gbogbo awọn ọmọ Israeli li o ni imọle ni ibugbé wọn.
24Farao si pè Mose, o si wipe, Ẹ ma lọ, ẹ sìn OLUWA; kìki agbo ati ọwọ́-ẹran nyin ni ki o kù lẹhin; ki awọn ewe nyin ki o bá nyin lọ pẹlu.
25Mose si wipe, Iwọ kò le ṣaima fun wa li ohun ẹbọ pẹlu ati ẹbọ sisun, ti awa o fi rubọ si OLUWA Ọlọrun wa.
26Ẹran-ọ̀sin wa yio si bá wa lọ pẹlu; a ki yio fi ibósẹ-ẹran kan silẹ lẹhin; nitori ninu rẹ̀ li awa o mú sìn OLUWA Ọlọrun wa; awa kò si mọ̀ ohun na ti a o fi sìn OLUWA, titi awa o fi dé ibẹ̀.
27Ṣugbọn OLUWA mu àiya Farao le, kò si fẹ́ jẹ ki nwọn lọ.
28Farao si wi fun u pe, Kuro lọdọ mi, ma ṣọ́ ara rẹ, máṣe tun ri oju mi mọ́; nitori ni ijọ́ na ti iwọ ba ri oju mi iwọ o kú.
29Mose si wipe, Iwọ fọ̀ rere; emi ki yio tun ri oju rẹ mọ́.
Currently Selected:
Eks 10: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.