Eks 9
9
1NIGBANA li OLUWA wi fun Mose pe, Wọle tọ̀ Farao lọ ki o si wi fun u pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun awọn Heberu wi, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn le sìn mi.
2Nitoripe, bi iwọ ba kọ̀ lati jẹ ki nwọn lọ, ti iwọ si da wọn duro sibẹ̀,
3Kiyesi i, ọwọ́ OLUWA mbẹ lara ẹran-ọ̀sin rẹ ti mbẹ li oko, lara ẹṣin, lara kẹtẹkẹtẹ, lara ibakasiẹ, lara ọwọ́-malu, ati lara agbo-agutan wọnni: ajakalẹ-àrun buburu mbọ̀.
4OLUWA yio si pàla si agbedemeji ẹran-ọ̀sin Israeli ati ẹran-ọ̀sin Egipti: kò si ohun kan ti yio kú ninu gbogbo eyiti iṣe ti awọn ọmọ Israeli.
5OLUWA si dá akokò kan wipe, Li ọla li OLUWA yio ṣe nkan yi ni ilẹ yi.
6OLUWA si ṣe nkan na ni ijọ́ keji, gbogbo ẹran-ọ̀sin Egipti si kú: ṣugbọn ninu ẹran-ọ̀sin awọn ọmọ Israeli ọkanṣoṣọ kò si kú.
7Farao si ranṣẹ, si kiyesi i, ọkanṣoṣo kò kú ninu ẹran-ọ̀sin awọn ọmọ Israeli. Àiya Farao si le, kò si jẹ ki awọn enia na ki o lọ.
8OLUWA si wi fun Mose ati fun Aaroni pe, Bù ikunwọ ẽru ninu ileru, ki Mose ki o kù u si oju-ọrun li oju Farao.
9Yio si di ekuru lẹbulẹbu ni gbogbo ilẹ Egipti, yio si di õwo ti yio ma tú pẹlu ileròro lara enia, ati lara ẹran, ká gbogbo ilẹ Egipti.
10Nwọn si bù ẽru ninu ileru, nwọn duro niwaju Farao; Mose si kù u si oke ọrun; o si di õwo ti o ntú jade pẹlu ileròro lara enia ati lara ẹran.
11Awọn alalupayida kò si le duro niwaju Mose nitori õwo wọnni; nitoriti õwo na wà lara awọn alalupayida, ati lara gbogbo awọn ara Egipti.
12OLUWA si mu àiya Farao le, kò si gbọ́ ti wọn; bi OLUWA ti sọ fun Mose.
13OLUWA si wi fun Mose pe, Dide ni kutukutu owurọ̀, ki o si duro niwaju Farao, ki o si wi fun u pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun awọn Heberu wi, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ ki nwọn le sìn mi.
14Nitori ìgba yi li emi o rán gbogbo iyọnu mi si àiya rẹ, ati sara awọn iranṣẹ rẹ, ati sara awọn enia rẹ; ki iwọ ki o le mọ̀ pe kò si ẹlomiran bi emi ni gbogbo aiye.
15Nitori nisisiyi, emi iba nà ọwọ́ mi, ki emi ki o le fi ajakalẹ-àrun lù ọ, ati awọn enia rẹ; a ba si ti ke ọ kuro lori ilẹ.
16Ṣugbọn nitori eyi pãpa li emi ṣe mu ọ duro, lati fi agbara mi hàn lara rẹ; ati ki a le ròhin orukọ mi ká gbogbo aiye.
17Titi di isisiyi iwọ ngbé ara rẹ ga si awọn enia mi pe, iwọ ki yio jẹ ki nwọn ki o lọ?
18Kiyesi i, li ọla li akokò yi, li emi o mu ọ̀pọ yinyin rọ̀ si ilẹ, irú eyiti kò ti si ni Egipti lati ipilẹṣẹ rẹ̀ titi o fi di isisiyi.
19Njẹ nisisiyi ranṣẹ, ki o si kó ẹran rẹ bọ̀, ati ohun gbogbo ti o ni ninu oko; nitori olukuluku enia ati ẹran ti a ba ri li oko, ti a kò si múbọ̀ wá ile, yinyin yio bọ lù wọn, nwọn o si kú.
20Ẹniti o bẹ̀ru ọ̀rọ OLUWA ninu awọn iranṣẹ Farao, mu ki awọn iranṣẹ rẹ̀ ati awọn ẹran-ọ̀sin rẹ̀ sá padà wá ile:
21Ẹniti kò si kà ọ̀rọ OLUWA si, jọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀ ati awọn ẹran-ọ̀sin rẹ̀ si oko.
22OLUWA si sọ fun Mose pe, Nà ọwọ́ rẹ si oke ọrun, ki yinyin ki o le bọ́ si gbogbo ilẹ Egipti, sara enia, ati sara ẹranko, ati sara eweko igbẹ́ gbogbo, já gbogbo ilẹ Egipti.
23Mose si nà ọpá rẹ̀ si ọrun: OLUWA si rán ãra ati yinyin, iná na si njó lori ilẹ; OLUWA si rọ̀ yinyin sori ilẹ Egipti.
24Yinyin si bọ́, iná si dàpọ mọ́ yinyin na, o papọ̀ju, irú rẹ̀ kò si ri ni gbogbo ilẹ Egipti lati ìgba ti o ti di orilẹ-ède.
25Yinyin na si lù ohun gbogbo ti o wà ninu oko bolẹ, ati enia ati ẹranko, já gbogbo ilẹ Egipti; yinyin na si lù gbogbo eweko bolẹ, o si fà gbogbo igi igbẹ́ ya.
26Ni kìki ilẹ Goṣeni, nibiti awọn ọmọ Israeli gbé wà, ni yinyin kò si.
27Farao si ranṣẹ, o si pè Mose ati Aaroni, o si wi fun wọn pe, Emi ṣẹ̀ nigbayi: OLUWA li olododo, ẹni buburu si li emi ati awọn enia mi.
28Ẹ bẹ̀ OLUWA (o sa to) ki ãra nla ati yinyin wọnyi ki o máṣe si mọ́; emi o si jẹ ki ẹ ma lọ; ẹ ki yio si duro mọ́.
29Mose si wi fun u pe, Bi mo ba ti jade ni ilu, emi o tẹ́ ọwọ́ mi si OLUWA; ãra yio si dá, bẹ̃ni yinyin ki yio si mọ́; ki iwọ ki o le mọ̀ pe ti OLUWA li aiye.
30Ṣugbọn bi o ṣe tirẹ ni ati ti awọn iranṣẹ rẹ, emi mọ̀ pe sibẹ, ẹnyin kò ti ibẹ̀ru OLUWA Ọlọrun.
31A si lù ọgbọ́ ati ọkà barle bolẹ; nitori ọkà barle wà ni ipẹ́, ọgbọ́ si rudi.
32Ṣugbọn alikama ati ọkà (rie) li a kò lù bolẹ: nitoriti nwọn kò ti idàgba.
33Mose si jade kuro lọdọ Farao sẹhin ilu, o si tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ si OLUWA; ãra ati yinyin si dá, bẹ̃li òjo kò si rọ̀ si ilẹ̀ mọ́.
34Nigbati Farao ri pe, òjo ati yinyin ati ãra dá, o ṣẹ̀ si i, o si sé àiya rẹ̀ le, on ati awọn iranṣẹ rẹ̀.
35Àiya Farao si le, bẹ̃ni kò si jẹ ki awọn ọmọ Israeli ki o lọ; bi OLUWA ti wi lati ọwọ́ Mose.
Currently Selected:
Eks 9: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.