YouVersion Logo
Search Icon

Isa 8

8
Ọmọ Aisaya jẹ́ Àmì fún Àwọn Eniyan
1PẸLUPẸLU Oluwa wi fun mi pe, Iwọ mu iwe nla kan, ki o si fi kalamu enia kọwe si inu rẹ̀ niti Maher-ṣalal-haṣ-basi.
2Emi si mu awọn ẹlẹri otitọ sọdọ mi lati ṣe ẹlẹri. Uriah alufa, ati Sekariah ọmọ Jeberekiah.
3Mo si wọle tọ wolĩ obinrin ni lọ; o si loyun o si bi ọmọkunrin kan. Nigbana ni Oluwa wi fun mi pe, sọ orukọ rẹ̀ ni Maher-ṣalal-haṣ-basi.
4Nitoripe ki ọmọ na to ni oye ati ke pe, Baba mi, ati iya mi, ọrọ̀ Damasku ati ikogun Samaria ni a o mu kuro niwaju ọba Assiria.
Ọba Asiria ń Bọ̀ Wá
5Oluwa si tun wi fun mi pe,
6Niwọn bi enia yi ti kọ̀ omi Ṣiloa ti nṣàn jẹjẹ silẹ, ti nwọn si nyọ̀ ninu Resini ati ọmọ Remaliah.
7Njẹ nitorina kiyesi i, Oluwa nfà omi odò ti o le, ti o si pọ̀, wá sori wọn, ani ọba Assiria ati gbogbo ogo rẹ̀; yio si wá sori gbogbo ọ̀na odò rẹ̀, yio si gun ori gbogbo bèbe rẹ̀.
8Yio si kọja li arin Juda; yio si ṣàn bò o mọlẹ yio si mù u de ọrùn, ninà iyẹ rẹ̀ yio si kún ibú ilẹ rẹ, iwọ Immanueli.
9Ẹ ko ara nyin jọ, ẹnyin enia, a o si fọ nyin tũtu: ẹ si fi eti silẹ, gbogbo ẹnyin ará ilẹ jijìna: ẹ di ara nyin li àmure, a o si fọ nyin tũtu; ẹ di ara nyin li àmure, a o si fọ nyin tũtu.
10Ẹ gbìmọ pọ̀ yio si di asan; ẹ sọ̀rọ na, ki yio si duro: nitoripe Ọlọrun wà pẹlu wa.
OLUWA Kìlọ̀ fún Wolii
11Nitoriti Oluwa wi bayi fun mi, nipa ọwọ agbara, o si kọ mi ki nmá ba rìn ni ọ̀na enia yi, pe,
12Ẹ máṣe pè gbogbo eyi ni imulẹ ti awọn enia yi pè ni imulẹ: bẹ̃ni ẹ máṣe bẹ̀ru ibẹ̀ru wọn, ẹ má si ṣe foya.
13Yà Oluwa awọn ọmọ-ogun tikalarẹ̀ si mimọ́; si jẹ ki o ṣe ẹ̀ru nyin, si jẹ ki o ṣe ifòya nyin.
14On o si wà fun ibi mimọ́, ṣugbọn fun okuta idùgbolu, ati fun apata ẹ̀ṣẹ, si ile Israeli mejeji, fun ẹgẹ, ati fun okùn didẹ si awọn ara Jerusalemu.
15Ọ̀pọlọpọ ninu wọn yio si kọsẹ, nwọn o si ṣubu, a o si fọ wọn, a o si mu wọn.
Ìkìlọ̀ nípa Bíbá Òkú Sọ̀rọ̀
16Di ẹri na, fi edídi di ofin na lãrin awọn ọmọ-ẹhin mi.
17Emi o si duro de Oluwa, ti o pa oju rẹ̀ mọ kuro lara ile Jakobu, emi o si ma wo ọ̀na rẹ̀.
18Kiyesi i, emi ati awọn ọmọ ti Oluwa ti fi fun mi wà fun àmi ati fun iyanu ni Israeli, lati ọdọ Oluwa awọn ọmọ-ogun wá, ti ngbe òke Sioni.
19Nigbati nwọn ba si wi fun nyin pe, Ẹ wá awọn ti mba okú lò, ati awọn oṣó ti nke, ti nsi nkùn, kò ha yẹ ki orilẹ-ède ki o wá Ọlọrun wọn jù ki awọn alãye ma wá awọn okú?
20Si ofin ati si ẹri: bi nwọn kò ba sọ gẹgẹ bi ọ̀rọ yi, nitoriti kò si imọlẹ ninu wọn ni.
Àkókò Ìṣòro
21Nwọn o si kọja lọ lãrin rẹ̀, ninu inilara ati ebi: yio si ṣe pe nigbati ebi yio pa wọn, nwọn o ma kanra, nwọn o si fi ọba ati Ọlọrun wọn re, nwọn o si ma wò òke.
22Nwọn o si wò ilẹ, si kiyesi i, iyọnu ati okùnkun, iṣuju irora: a o si le wọn lọ sinu okùnkun.

Currently Selected:

Isa 8: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in