Isa 9
9
Ọba Lọ́la
1ṢUGBỌN iṣuju na kì yio wà nibiti wahalà mbẹ nisisiyi, gẹgẹ bi ìgba iṣãju ti mu itìju wá si ilẹ Sebuloni ati ilẹ Naftali, bẹ̃ni ìgba ikẹhin yio mu ọla wá si ọ̀na okun, niha ẹkùn Jordani, Galili awọn orilẹ-ède.
2Awọn enia ti nrin li okùnkun ri imọlẹ nla: awọn ti ngbe ilẹ ojiji ikú, lara wọn ni imọlẹ mọ́ si.
3Iwọ ti mu orilẹ-ède nì bi si i pupọ̀pupọ̀, iwọ si sọ ayọ̀ di pupọ̀ fun u: nwọn nyọ̀ niwaju rẹ gẹgẹ bi ayọ̀ ikore, ati gẹgẹ bi enia iti yọ̀ nigbati nwọn npin ikogun.
4Nitori iwọ ṣẹ́ ajàga-irú rẹ̀, ati ọpá ejika rẹ̀, ọgọ aninilara rẹ̀, gẹgẹ bi li ọjọ Midiani.
5Nitori gbogbo ihamọra awọn ologun ninu irọkẹ̀kẹ, ati aṣọ ti a yi ninu ẹ̀jẹ, yio jẹ fun ijoná ati igi iná.
6Nitori a bi ọmọ kan fun wa, a fi ọmọkunrin kan fun wa: ijọba yio si wà li ejika rẹ̀: a o si ma pe orukọ rẹ̀ ni Iyanu, Oludamọ̀ran, Ọlọrun Alagbara, Baba Aiyeraiye, Ọmọ-Alade Alafia.
7Ijọba yio bi si i, alafia ki yio ni ipẹkun: lori itẹ Dafidi, ati lori ijọba rẹ̀, lati ma tọ́ ọ, ati lati fi idi rẹ̀ mulẹ, nipa idajọ, ati ododo lati isisiyi lọ, ani titi lai. Itara Oluwa awọn ọmọ-ogun yio ṣe eyi.
OLUWA yóo Jẹ Israẹli Níyà
8Oluwa rán ọ̀rọ si Jakobu, o si ti bà lé Israeli.
9Gbogbo enia yio si mọ̀ ọ, Efraimu ati awọn ti ngbe Samaria, ti nwi ninu igberaga, ati lile aiya pe,
10Briki wọnni ṣubu lu ilẹ, ṣugbọn awa o fi okuta gbigbẹ́ mọ ọ: a ke igi sikamore lu ilẹ, ṣugbọn a o fi igi kedari pãrọ wọn.
11Nitorina li Oluwa yio gbe awọn aninilara Resini dide si i, yio si dá awọn ọtá rẹ̀ pọ̀.
12Awọn ara Siria niwaju, ati awọn Filistini lẹhin: nwọn o si fi gbogbo ẹnu jẹ Israeli run. Ni gbogbo eyi ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ.
13Awọn enia na kọ yipada si ẹniti o lù wọn, bẹ̃ni nwọn kò wá Oluwa awọn ọmọ-ogun.
14Nitorina ni Oluwa yio ke ori ati irù, imọ̀-ọpẹ ati koriko-odo kuro ni Israeli, li ọjọ kan.
15Agbà ati ọlọla, on li ori, ati wolĩ ti nkọni li eké, on ni irù.
16Nitori awọn olori enia yi mu wọn ṣìna: awọn ti a si tọ́ li ọ̀na ninu wọn li a parun.
17Nitorina ni Oluwa kì yio ṣe ni ayọ̀ ninu ọdọ-ọmọkunrin wọn, bẹ̃ni ki yio ṣãnu fun awọn alainibaba ati opo wọn: nitori olukuluku wọn jẹ agabagebe ati oluṣe-buburu, olukuluku ẹnu nsọ wère. Ni gbogbo eyi ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ.
18Nitori ìwa-buburu njo bi iná: yio jo ẹwọn ati ẹgún run, yio si ràn ninu pàntiri igbó, nwọn o si goke lọ bi ẹ̃fin iti goke.
19Nipa ibinu Oluwa awọn ọmọ-ogun ni ilẹ fi ṣõkùn, awọn enia yio dabi igi iná, ẹnikan kì yio dá arakunrin rẹ̀ si.
20On o si jajẹ li ọwọ́ ọ̀tun, ebi o si pa a; on o si jẹ li ọwọ́ osì; nwọn kì yio si yo: olukuluku enia yio si jẹ ẹran-ara apa rẹ̀.
21Manasse o jẹ Efraimu; Efraimu o si jẹ Manasse: awọn mejeji o dojukọ Juda. Ni gbogbo eyi, ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ.
Currently Selected:
Isa 9: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.