Joh 3
3
Jesu ati Nikodemu
1ỌKUNRIN kan si wà ninu awọn Farisi, ti a npè ni Nikodemu, ijoye kan ninu awọn Ju:
2On na li o tọ̀ Jesu wá li oru, o si wi fun u pe, Rabbi, awa mọ̀ pe olukọni lati ọdọ Ọlọrun wá ni iwọ iṣe: nitoripe kò si ẹniti o le ṣe iṣẹ àmi wọnyi ti iwọ nṣe, bikoṣepe Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀.
3Jesu dahùn o si wi fun u pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun ọ, Bikoṣepe a tún enia bí, on kò le ri ijọba Ọlọrun.
4Nikodemu wi fun u pe, A o ti ṣe le tún enia bí, nigbati o di agbalagba tan? o ha le wọ̀ inu iya rẹ̀ lọ nigba keji, ki a si bí i?
5Jesu dahùn wipe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun ọ, Bikoṣepe a fi omi ati Ẹmi bi enia, on kò le wọ̀ ijọba Ọlọrun.
6 Eyiti a bí nipa ti ara, ara ni; eyiti a si bí nipa ti Ẹmí, ẹmí ni.
7 Ki ẹnu ki o máṣe yà ọ, nitori mo wi fun ọ pe, A kò le ṣe alaitún nyin bí.
8 Afẹfẹ nfẹ si ibi ti o gbé wù u, iwọ si ngbọ́ iró rẹ̀, ṣugbọn iwọ kò mọ̀ ibi ti o ti wá, ati ibi ti o gbé nlọ: gẹgẹ bẹ̃ni olukuluku ẹniti a bí nipa ti Ẹmí.
9Nikodemu dahùn, o si wi fun u pe, Nkan wọnyi yio ti ṣe le ri bẹ̃?
10Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Ṣe olukọni ni Israeli ni iwọ iṣe, o kò si mọ̀ nkan wọnyi?
11 Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun ọ, Awa nsọ eyiti awa mọ̀, a si njẹri eyiti awa ti ri; ẹnyin kò si gbà ẹri wa.
12 Bi mo ba sọ̀ ohun ti aiye yi fun nyin, ti ẹnyin kò si gbagbọ́, ẹnyin o ti ṣe gbagbọ́ bi mo ba sọ ohun ti ọrun fun nyin?
13 Ko si si ẹniti o gòke re ọrun, bikoṣe ẹniti o ti ọrun sọkalẹ wá, ani Ọmọ-enia ti mbẹ li ọrun.
14 Bi Mose si ti gbé ejò soke li aginjù, gẹgẹ bẹ̃li a kò le ṣe alaigbé Ọmọ-enia soke pẹlu:
15 Ki ẹnikẹni ti o ba gba a gbọ, ki o má ba ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni ìye ainipẹkun.
16 Nitori Ọlọrun fẹ araiye tobẹ̃ gẹ, ti o fi Ọmọ bíbi rẹ̀ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ́ má bà ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni ìye ainipẹkun.
17 Nitori Ọlọrun kò rán Ọmọ rẹ̀ si aiye lati da araiye lẹjọ; ṣugbọn ki a le ti ipasẹ rẹ̀ gbà araiye là.
18 Ẹniti o ba gbà a gbọ́, a ko ni da a lẹjọ; ṣugbọn a ti da ẹniti kò gbà a gbọ́ lẹjọ na, nitoriti kò gbà orukọ Ọmọ bíbi kanṣoṣo ti Ọlọrun gbọ́.
19 Eyi ni idajọ na pe, imọlẹ wá si aiye, awọn enia si fẹ òkunkun jù imọlẹ lọ, nitoriti iṣẹ wọn buru.
20 Nitori olukuluku ẹniti o ba hùwa buburu ni ikorira imọlẹ, ki isi wá si imọlẹ, ki a máṣe ba iṣẹ rẹ̀ wí.
21 Ṣugbọn ẹniti o ba nṣe otitọ ni iwá si imọlẹ, ki iṣẹ rẹ̀ ki o le fi ara hàn pe, a ṣe wọn nipa ti Ọlọrun.
Johanu Tún Sọ̀rọ̀ nípa Jesu
22Lẹhin nkan wọnyi Jesu pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá si ilẹ Judea; o si duro pẹlu wọn nibẹ o si baptisi.
23Johanu pẹlu si mbaptisi ni Ainoni, li àgbegbe Salimu, nitoriti omi pipọ wà nibẹ̀: nwọn si nwá, a si baptisi wọn.
24Nitoriti a kò ti isọ Johanu sinu tubu.
25Nigbana ni iyàn kan wà larin awọn ọmọ-ẹhin Johanu, pẹlu Ju kan niti ìwẹnu.
26Nwọn si tọ̀ Johanu wá, nwọn si wi fun u pe, Rabbi, ẹniti o ti wà pẹlu rẹ loke odò Jordani, ti iwọ ti jẹrí rẹ̀, wo o, on mbaptisi, gbogbo enia si ntọ̀ ọ̀ wá.
27Johanu dahùn o si wipe, Enia ko le ri nkankan gbà, bikoṣepe a ba ti fifun u lati ọrun wá.
28Ẹnyin tikaranyin jẹri mi, pe mo wipe, Emi kì iṣe Kristi na, ṣugbọn pe a rán mi ṣiwaju rẹ̀.
29Ẹniti o ba ni iyawo ni ọkọ iyawo; ṣugbọn ọrẹ́ ọkọ iyawo ti o duro ti o si ngbohùn rẹ̀, o nyọ̀ gidigidi nitori ohùn ọkọ iyawo; nitorina ayọ̀ mi yi di kíkun.
30On kò le ṣaima pọsi i, ṣugbọn emi kò le ṣaima rẹ̀hin.
Ipò Ẹni Tí Ó Wá láti Ọ̀run
31Ẹniti o ti oke wá ju gbogbo enia lọ: ẹniti o ti aiye wá ti aiye ni, a si ma sọ̀ ohun ti aiye: ẹniti o ti ọrun wá ju gbogbo enia lọ.
32Ohun ti o ti ri ti o si ti gbọ́ eyina si li on njẹri rẹ̀; ko si si ẹniti o gbà ẹrí rẹ̀.
33Ẹniti o gbà ẹrí rẹ̀ fi edidi di i pe, otitọ li Ọlọrun.
34Nitori ẹniti Ọlọrun ti rán nsọ ọ̀rọ Ọlọrun: nitoriti Ọlọrun kò fi Ẹmí fun u nipa oṣuwọn.
35Baba fẹ Ọmọ, o si ti fi ohun gbogbo le e lọwọ.
36Ẹniti o ba gbà Ọmọ gbọ́, o ni iye ainipẹkun: ẹniti kò ba si gbà Ọmọ gbọ, kì yio ri ìye; ṣugbọn ibinu Ọlọrun mbẹ lori rẹ̀.
S'ha seleccionat:
Joh 3: YBCV
Subratllat
Comparteix
Copia
Vols que els teus subratllats es desin a tots els teus dispositius? Registra't o inicia sessió
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.