ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 5:3-5
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 5:3-5 YCE
Peteru bá bi í pé, “Anania, kí ló dé tí Satani fi gbà ọ́ lọ́kàn tí o fi ṣe èké sí Ẹ̀mí Mímọ́, tí o fi yọ sílẹ̀ ninu owó tí o rí lórí ilẹ̀ náà? Kí o tó ta ilẹ̀ náà, mo ṣebí tìrẹ ni? Nígbà tí o tà á tán, mo ṣebí o ní àṣẹ lórí owó tí o tà á? Kí ló dé tí o gbèrò irú nǹkan yìí? Kì í ṣe eniyan ni o ṣèké sí, Ọlọrun ni.” Nígbà tí Anania gbọ́ gbolohun yìí, ó ṣubú lulẹ̀, ó kú. Ẹ̀rù ńlá sì ba gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́.