Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú I. Joh 1:8

Ṣé Mo Lè B'orí Ẹ̀ṣẹ̀ àtí Ìdánwò Nítòótọ́?
Ọjọ marun
Ǹjẹ́ o ti bi ara rẹ léèrè rí pé, "Kílódé tí mo ṣì ńbá ẹ̀ṣẹ̀ yẹn já ìjàkadì?" Àpóstélì Pọ́ọ́lù pàápàá sọ bẹ́ẹ̀ ní Róòmù 7:15: "Kìí ṣe ohun tí mo fẹ́ ni èmi ńṣe, ṣùgbọ́n ohun tí mo kórìra ni èmi ńṣe." Báwo ni a ṣe lè dá ẹ̀ṣẹ̀ l'ọ́wọ́ kọ́ kí ó má baà p'agi dínà ìgbé-ayé ẹ̀mí wa? Ṣé èyí tilẹ̀ ṣeéṣe? Jẹ́ kí á jíròrò lórí ẹ̀ṣẹ̀, ìdanwò, Èṣù, àti, ìfẹ́ Ọlọ́run.

Ìyípadà Ọmọ Onínàkúnàá pẹ̀lú Kyle Idleman
Ọjọ́ Méje
A fa ètò yí jáde látinú ìwé Kyle Idleman "AHA," máa fọkàn báalọ bí ó ti ń ṣàwarí àwọn ǹkan mẹ́ta tó lè túbọ̀ mú wa sún mọ́ Ọlọ́run àti láti yí ayé wa padà fún rere. Ṣé o ṣetán fún àkókò pẹ̀lú Ọlọ́run tí yóò yí ohun gbogbo padà?

Ara Èké
7 Awọn ọjọ
Ǹjẹ́ àwọn ìbẹ̀rùbojo ati àìláàbò ayéè rẹ ti tì ọ́ sínú ìdánimọ̀ tó ṣe àjèjì? Kíni ìwọ̀n ìyàtọ̀ tó wà ní àárín ẹni tí ìwọ jẹ́ ní òtítọ́ àti àwòrán rẹ tí o fi ń han àwọn míràn? Ní ìbásepọ̀ pẹ̀lú LUMO àti OneHope, àti tó dá lórí ìwàásù Àlùfáà Tyler Staton, ètò ọlọ́jọ́ méje yí yóò mú ẹ ṣe àyẹ̀wò òtítọ́ kodoro tó wà lẹ́yìn “ara èké.