Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Owe 14:30
Ìbínú
Ọjọ́ Mẹ́ta
Gbogbo wa la máa n bínú! Ìdáhùn rẹ sí ìbínú dá lórí gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run àti ṣíṣàrò lórí Ọ̀rọ Rẹ̀. Wo ètò kíkà Ìgbẹ́kẹ̀lé lẹ́gbẹ̀ẹ́ àkọ́lé Ìbínú. Àwọn ẹsẹ̀ tí ó tẹ̀lé e, tí a bá fi wọ́n ṣe àkọ́sórí, lè ràn ọ́ l'ọ́wọ́ láti dáhùn sí ìbínú l'ọ́na tó tọ́. Jẹ́ kí ìgbésí ayé rẹ yípadà nípasẹ fífi Ìwé Mímọ́ se àkọ́sórí! Fún ètò kíkún fún fífi Ìwé Mímọ́ se àkọ́sórí, lọ sí www.MemLoK.com
Já Ara Rẹ Gbà Kúrò Lọ́wọ́ Owú Ètò Kíkà Ọlọ́jọ́-Mẹ́fà Látọwọ́ Anna Light
Ọjọ́ mẹ́fà
Ní àkókò yí, ǹkan tó dára nípa ìgbésí ayé àwọn ènìyàn ní wọ́n fihàn fún wa láti rí, àti wípé àfiwé tí a bá ṣe pẹ̀lú ayé tiwa a máa mú owú jẹyọ. O kò fẹ́ kí irú ẹ̀mí yìí máa jọba nínú ayé rẹ, àmọ́ kí ló máa ṣe sí àwọn ìjàmbá tó lè wá nípasẹ̀ owú látọ̀dọ̀ ẹlòmíràn sí ọ? Nínú ètò kíkà yí, o máa rí àwọn ọ̀nà tí o lè gbà borí owú, pa ọkàn rẹ mọ́, pẹ̀lú òmìnira.