Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Rom 8:38

Mo Yọ̀ǹda: Ìwé-Ìfọkànsìn Asínilórì Láti Ọwọ́ Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n
Ọjọ́ Mẹ́rin
Bíbelì jẹ́ ìwé ìràpadà, òmìnira, àti ìrètí. Nínú àwọn ojú-ìwé rẹ̀ ni orírúirú ẹ̀dá ènìyàn, akínkanjú—àwọn oníròbìnùjẹ́-ọkàn l'ọ́kùnrin l'óbìnrin tí wọn ń wá ọ̀nà àbáyọ. Ní ọ̀nà kan tàbí òmínràn, wọ́n dàbìi àwọn àbọ̀dé elẹ́wọ̀n àná tàbí àwọn tí wọ́n ń ṣe ẹ̀wọ̀n lọ́wọ́lọ́wọ́ tí wọ́n kọ àwọn ìwé-ìfọkànsìn tí o fẹ́ kà báyìí. A ní èrò pé àwọn ohùn ìjọ làti inú àhámọ́ yìí yíó jẹ́ ìgbaniníyànjú àti ìwúrí fún ọ. Kí ọ̀rọ̀ ẹ̀rí wọn dá àwa náà s'ílẹ̀.

Ara Èké
7 Awọn ọjọ
Ǹjẹ́ àwọn ìbẹ̀rùbojo ati àìláàbò ayéè rẹ ti tì ọ́ sínú ìdánimọ̀ tó ṣe àjèjì? Kíni ìwọ̀n ìyàtọ̀ tó wà ní àárín ẹni tí ìwọ jẹ́ ní òtítọ́ àti àwòrán rẹ tí o fi ń han àwọn míràn? Ní ìbásepọ̀ pẹ̀lú LUMO àti OneHope, àti tó dá lórí ìwàásù Àlùfáà Tyler Staton, ètò ọlọ́jọ́ méje yí yóò mú ẹ ṣe àyẹ̀wò òtítọ́ kodoro tó wà lẹ́yìn “ara èké.
